Nọ́ńbà 6:1-27

  • Ẹ̀jẹ́ láti di Násírì (1-21)

  • Bí àwọn àlùfáà á ṣe máa súre (22-27)

6  Jèhófà wá sọ fún Mósè pé:  “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Tí ọkùnrin tàbí obìnrin kan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ pàtàkì pé òun fẹ́ di Násírì*+ fún Jèhófà,  kó yẹra fún wáìnì àti àwọn ohun mímu míì tó ní ọtí. Kó má mu ọtí kíkan tí wọ́n fi wáìnì ṣe tàbí ọtí kíkan tí wọ́n fi ohunkóhun tó ní ọtí+ ṣe. Kó má mu ohunkóhun tí wọ́n fi èso àjàrà ṣe, kó má sì jẹ èso àjàrà, ì báà jẹ́ tútù tàbí gbígbẹ.  Ní gbogbo ọjọ́ tó bá fi jẹ́ Násírì, kó má jẹ ohunkóhun tí wọ́n fi àjàrà ṣe, látorí èso àjàrà tí kò tíì pọ́n títí dórí èèpo rẹ̀.  “‘Ní gbogbo ọjọ́ tó bá fi jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun máa jẹ́ Násírì, kò gbọ́dọ̀ fi abẹ kan orí rẹ̀.+ Kó jẹ́ kí irun orí rẹ̀ gùn títí ọjọ́ tó fi ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún Jèhófà yóò fi pé, kó lè máa jẹ́ mímọ́.  Kò gbọ́dọ̀ sún mọ́* òkú èèyàn* ní gbogbo ọjọ́ tó bá fi ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún Jèhófà.  Ì báà jẹ́ bàbá rẹ̀, ìyá rẹ̀, arákùnrin rẹ̀ tàbí arábìnrin rẹ̀ ló kú, kò gbọ́dọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́,+ torí àmì wà ní orí rẹ̀ pé ó jẹ́ Násírì fún Ọlọ́run rẹ̀.  “‘Ní gbogbo ọjọ́ tó bá fi jẹ́ Násírì, ó jẹ́ mímọ́ sí Jèhófà.  Àmọ́ tí ẹnì kan bá dédé kú lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀,+ tó sì sọ irun rẹ̀ di aláìmọ́, irun tó fi hàn pé ó ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún Ọlọ́run,* ó gbọ́dọ̀ fá orí rẹ̀+ ní ọjọ́ tí wọ́n bá kéde pé ó ti di mímọ́. Kó fá a ní ọjọ́ keje. 10  Tó bá wá di ọjọ́ kẹjọ, kó mú ẹyẹ oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì wá fún àlùfáà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 11  Kí àlùfáà fi ọ̀kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kó fi èkejì rú ẹbọ sísun, kó sì ṣe ètùtù fún un torí ẹ̀ṣẹ̀+ tó dá tó jẹ mọ́ òkú* náà. Kó wá ya orí rẹ̀ sí mímọ́ ní ọjọ́ yẹn. 12  Kó tún ara rẹ̀ yà sọ́tọ̀ fún Jèhófà ní àwọn ọjọ́ tó fi jẹ́ Násírì, kó sì mú ọmọ àgbò ọlọ́dún kan wá láti fi rú ẹbọ ẹ̀bi. Àmọ́ kò ní ka àwọn ọjọ́ tó ti kọjá torí ó ti ba Násírì rẹ̀ jẹ́. 13  “‘Èyí ni òfin nípa Násírì: Tí ọjọ́ tó fi jẹ́ Násírì+ bá pé, kí ẹ mú un wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 14  Ibẹ̀ ni kó mú ọrẹ rẹ̀ tó fẹ́ fún Jèhófà wá: ọmọ àgbò ọlọ́dún kan tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá láti fi rú ẹbọ sísun,+ abo ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀,+ àgbò kan tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá láti fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀,+ 15  apẹ̀rẹ̀ búrẹ́dì aláìwú tó rí bí òrùka tí wọ́n fi ìyẹ̀fun tó kúnná ṣe, tí wọ́n pò mọ́ òróró, búrẹ́dì aláìwú pẹlẹbẹ tí wọ́n fi òróró pa àti ọrẹ ọkà+ wọn àti àwọn ọrẹ ohun mímu+ wọn. 16  Kí àlùfáà gbé e wá síwájú Jèhófà, kó fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ sísun. 17  Kó fi àgbò náà rúbọ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrẹ́pọ̀ sí Jèhófà pẹ̀lú apẹ̀rẹ̀ búrẹ́dì aláìwú náà, kí àlùfáà sì mú ọrẹ ọkà+ àgbò náà àti ọrẹ ohun mímu rẹ̀ wá. 18  “‘Kí Násírì náà wá gé irun orí+ rẹ̀ tí kò gé rí* ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, kó kó irun náà jọ, èyí tó hù lórí rẹ̀ nígbà tó jẹ́ Násírì, kó kó o sínú iná tó wà lábẹ́ ẹbọ ìrẹ́pọ̀. 19  Kí àlùfáà sì mú apá àgbò náà tí wọ́n bọ̀,+ kó mú búrẹ́dì aláìwú kan tó rí bí òrùka látinú apẹ̀rẹ̀ náà àti búrẹ́dì aláìwú pẹlẹbẹ kan, kó sì kó o lé àtẹ́lẹwọ́ Násírì náà lẹ́yìn tó ti gé àmì Násírì rẹ̀ kúrò. 20  Kí àlùfáà sì fì wọ́n síwá-sẹ́yìn bí ọrẹ fífì níwájú Jèhófà.+ Ohun mímọ́ ló jẹ́ fún àlùfáà, pẹ̀lú igẹ̀ ọrẹ fífì àti ẹsẹ̀ ọrẹ+ náà. Lẹ́yìn náà, Násírì náà lè mu wáìnì. 21  “‘Èyí ni òfin nípa Násírì+ tó jẹ́jẹ̀ẹ́: Tó bá jẹ́jẹ̀ẹ́, tí agbára rẹ̀ sì gbé e láti ṣe ọrẹ fún Jèhófà, ọrẹ tó pọ̀ jù ohun tí a béèrè lọ́wọ́ Násírì, kó san ẹ̀jẹ́ rẹ̀ kó lè tẹ̀ lé òfin Násírì.’” 22  Jèhófà sọ fún Mósè pé: 23  “Sọ fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, ‘Bí ẹ ó ṣe máa súre+ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìyí. Kí ẹ sọ fún wọn pé: 24  “Kí Jèhófà bù kún ọ,+ kó sì pa ọ́ mọ́. 25  Kí Jèhófà mú kí ojú rẹ̀ tàn sí ọ+ lára, kó sì ṣojúure sí ọ. 26  Kí Jèhófà bojú wò ọ́, kó sì fún ọ ní àlàáfíà.”’+ 27  Kí wọ́n sì fi orúkọ mi sára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ kí n lè bù kún wọn.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Lédè Hébérù, na·zirʹ, ó túmọ̀ sí “Ẹni Tí A Yàn; Ẹni Tí A Yà Sí Mímọ́; Ẹni Tí A Yà Sọ́tọ̀.”
Tàbí “wá sí tòsí.”
Tàbí “ọkàn.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “sọ orí Násírì rẹ̀ di aláìmọ́.”
Tàbí “ọkàn.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “orí Násírì rẹ̀.”