Nọ́ńbà 7:1-89
-
Àwọn ọrẹ tí wọ́n mú wá síbi ìyàsímímọ́ àgọ́ ìjọsìn (1-89)
7 Ní ọjọ́ tí Mósè to àgọ́ ìjọsìn+ náà tán, ó fòróró yàn án,+ ó sì yà á sí mímọ́ pẹ̀lú gbogbo ohun tó wà níbẹ̀, pẹpẹ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀.+ Lẹ́yìn tó fòróró yan nǹkan wọ̀nyí, tó sì sọ wọ́n di mímọ́,+
2 àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì,+ àwọn olórí agbo ilé bàbá wọn mú ọrẹ wá. Àwọn ìjòyè yìí látinú àwọn ẹ̀yà, tí wọ́n darí ìforúkọsílẹ̀ náà
3 mú ọrẹ wọn wá síwájú Jèhófà, kẹ̀kẹ́ ẹrù mẹ́fà tí wọ́n bò àti màlúù méjìlá (12), kẹ̀kẹ́ ẹrù kan fún ìjòyè méjì àti akọ màlúù* kan fún ẹnì kọ̀ọ̀kan; wọ́n sì kó o wá síwájú àgọ́ ìjọsìn.
4 Jèhófà sọ fún Mósè pé:
5 “Gba nǹkan wọ̀nyí lọ́wọ́ wọn, torí wọ́n máa fi ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé, kí o sì fún àwọn ọmọ Léfì, kí o fún kálukú ní ohun tó máa nílò láti fi ṣiṣẹ́ rẹ̀.”
6 Mósè wá gba àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù àti màlúù náà, ó sì kó o fún àwọn ọmọ Léfì.
7 Ó fún àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì ní kẹ̀kẹ́ ẹrù méjì àti màlúù mẹ́rin, bí wọ́n ṣe nílò rẹ̀ fún iṣẹ́+ wọn;
8 ó sì fún àwọn ọmọ Mérárì ní kẹ̀kẹ́ ẹrù mẹ́rin àti màlúù mẹ́jọ, bí wọ́n ṣe nílò rẹ̀ fún iṣẹ́ wọn, Ítámárì ọmọ àlùfáà Áárónì+ ló ń darí wọn.
9 Àmọ́ kò fún àwọn ọmọ Kóhátì ní ìkankan, torí ojúṣe wọn jẹ mọ́ iṣẹ́ ibi mímọ́,+ èjìká+ ni wọ́n sì máa ń fi ru àwọn ohun mímọ́.
10 Àwọn ìjòyè náà wá mú ọrẹ wọn wá síbi ìyàsímímọ́*+ pẹpẹ lọ́jọ́ tí wọ́n fòróró yàn án. Nígbà tí àwọn ìjòyè náà mú ọrẹ wọn wá síwájú pẹpẹ,
11 Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, kí ìjòyè kọ̀ọ̀kan mú ọrẹ rẹ̀ wá fún ìyàsímímọ́ pẹpẹ náà, ní ọjọ́ kan tẹ̀ lé òmíràn.”
12 Ní ọjọ́ kìíní, Náṣónì+ ọmọ Ámínádábù láti ẹ̀yà Júdà mú ọrẹ rẹ̀ wá.
13 Ọrẹ tó mú wá ni abọ́ ìjẹun fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì* àti abọ́ fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, ó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́,*+ ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró kún inú méjèèjì, láti fi ṣe ọrẹ ọkà;+
14 ife wúrà* kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí tùràrí kún inú rẹ̀;
15 akọ ọmọ màlúù kan, àgbò kan, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan tó jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ sísun;+
16 ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+
17 àti màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀.+ Èyí ni ọrẹ tí Náṣónì ọmọ Ámínádábù+ mú wá.
18 Ní ọjọ́ kejì, Nétánélì+ ọmọ Súárì, ìjòyè Ísákà mú ọrẹ wá.
19 Ọrẹ tó mú wá ni abọ́ ìjẹun fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti abọ́ fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, ó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́,+ ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró kún inú méjèèjì, láti fi ṣe ọrẹ ọkà;+
20 ife wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí tùràrí kún inú rẹ̀;
21 akọ ọmọ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan tó jẹ́ ọlọ́dún kan, láti fi rú ẹbọ sísun;+
22 ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+
23 àti màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀.+ Èyí ni ọrẹ tí Nétánélì ọmọ Súárì mú wá.
24 Ní ọjọ́ kẹta, Élíábù+ ọmọ Hélónì, ìjòyè àwọn ọmọ Sébúlúnì,
25 mú ọrẹ wá, ọrẹ tó mú wá ni abọ́ ìjẹun fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti abọ́ fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, ó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́,+ ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró kún inú méjèèjì, láti fi ṣe ọrẹ ọkà;+
26 ife wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí tùràrí kún inú rẹ̀;
27 akọ ọmọ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan tó jẹ́ ọlọ́dún kan, láti fi rú ẹbọ sísun;+
28 ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+
29 àti màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀.+ Èyí ni ọrẹ tí Élíábù+ ọmọ Hélónì mú wá.
30 Ní ọjọ́ kẹrin, Élísúrì+ ọmọ Ṣédéúrì, ìjòyè àwọn ọmọ Rúbẹ́nì
31 mú ọrẹ wá, ọrẹ tó mú wá ni abọ́ ìjẹun fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti abọ́ fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, ó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́,+ ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró kún inú méjèèjì, láti fi ṣe ọrẹ ọkà;+
32 ife wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí tùràrí kún inú rẹ̀;
33 akọ ọmọ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan tó jẹ́ ọlọ́dún kan, láti fi rú ẹbọ sísun;+
34 ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+
35 àti màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀.+ Èyí ni ọrẹ tí Élísúrì+ ọmọ Ṣédéúrì mú wá.
36 Ní ọjọ́ karùn-ún, Ṣẹ́lúmíẹ́lì+ ọmọ Súríṣádáì, ìjòyè àwọn ọmọ Síméónì,
37 mú ọrẹ wá, ọrẹ tó mú wá ni abọ́ ìjẹun fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti abọ́ fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, ó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́,+ ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró kún inú méjèèjì, láti fi ṣe ọrẹ ọkà;+
38 ife wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí tùràrí kún inú rẹ̀;
39 akọ ọmọ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan tó jẹ́ ọlọ́dún kan, láti fi rú ẹbọ sísun;+
40 ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+
41 àti màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀.+ Èyí ni ọrẹ tí Ṣẹ́lúmíẹ́lì+ ọmọ Súríṣádáì mú wá.
42 Ní ọjọ́ kẹfà, Élíásáfù+ ọmọ Déúélì, ìjòyè àwọn ọmọ Gádì
43 mú ọrẹ wá, ọrẹ tó mú wá ni abọ́ ìjẹun fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti abọ́ fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, ó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́,+ ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró kún inú méjèèjì, láti fi ṣe ọrẹ ọkà;+
44 ife wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí tùràrí kún inú rẹ̀;
45 akọ ọmọ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan tó jẹ́ ọlọ́dún kan, láti fi rú ẹbọ sísun;+
46 ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+
47 àti màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀.+ Èyí ni ọrẹ tí Élíásáfù+ ọmọ Déúélì mú wá.
48 Ní ọjọ́ keje, Élíṣámà+ ọmọ Ámíhúdù, ìjòyè àwọn ọmọ Éfúrémù
49 mú ọrẹ wá, ọrẹ tó mú wá ni abọ́ ìjẹun fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti abọ́ fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, ó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́,+ ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró kún inú méjèèjì, láti fi ṣe ọrẹ ọkà;+
50 ife wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí tùràrí kún inú rẹ̀;
51 akọ ọmọ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan tó jẹ́ ọlọ́dún kan, láti fi rú ẹbọ sísun;+
52 ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+
53 àti màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀.+ Èyí ni ọrẹ tí Élíṣámà+ ọmọ Ámíhúdù mú wá.
54 Ní ọjọ́ kẹjọ, Gàmálíẹ́lì+ ọmọ Pédásúrì, ìjòyè àwọn ọmọ Mánásè
55 mú ọrẹ wá, ọrẹ tó mú wá ni abọ́ ìjẹun fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti abọ́ fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, ó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́,+ ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró kún inú méjèèjì, láti fi ṣe ọrẹ ọkà;+
56 ife wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí tùràrí kún inú rẹ̀;
57 akọ ọmọ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan tó jẹ́ ọlọ́dún kan, láti fi rú ẹbọ sísun;+
58 ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+
59 àti màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀.+ Èyí ni ọrẹ tí Gàmálíẹ́lì+ ọmọ Pédásúrì mú wá.
60 Ní ọjọ́ kẹsàn-án, Ábídánì+ ọmọ Gídéónì, ìjòyè+ àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì
61 mú ọrẹ wá, ọrẹ tó mú wá ni abọ́ ìjẹun fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti abọ́ fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, ó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́,+ ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró kún inú méjèèjì, láti fi ṣe ọrẹ ọkà;+
62 ife wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí tùràrí kún inú rẹ̀;
63 akọ ọmọ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan tó jẹ́ ọlọ́dún kan, láti fi rú ẹbọ sísun;+
64 ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+
65 àti màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀.+ Èyí ni ọrẹ tí Ábídánì+ ọmọ Gídéónì mú wá.
66 Ní ọjọ́ kẹwàá, Áhíésérì+ ọmọ Ámíṣádáì, ìjòyè àwọn ọmọ Dánì
67 mú ọrẹ wá, ọrẹ tó mú wá ni abọ́ ìjẹun fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti abọ́ fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, ó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́,+ ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró kún inú méjèèjì, láti fi ṣe ọrẹ ọkà;+
68 ife wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí tùràrí kún inú rẹ̀;
69 akọ ọmọ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan tó jẹ́ ọlọ́dún kan, láti fi rú ẹbọ sísun;+
70 ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+
71 àti màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀.+ Èyí ni ọrẹ tí Áhíésérì+ ọmọ Ámíṣádáì mú wá.
72 Ní ọjọ́ kọkànlá, Págíẹ́lì+ ọmọ Ókíránì, ìjòyè àwọn ọmọ Áṣérì
73 mú ọrẹ wá, ọrẹ tó mú wá ni abọ́ ìjẹun fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti abọ́ fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, ó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́,+ ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró kún inú méjèèjì, láti fi ṣe ọrẹ ọkà;+
74 ife wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí tùràrí kún inú rẹ̀;
75 akọ ọmọ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan tó jẹ́ ọlọ́dún kan, láti fi rú ẹbọ sísun;+
76 ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+
77 àti màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀.+ Èyí ni ọrẹ tí Págíẹ́lì+ ọmọ Ókíránì mú wá.
78 Ní ọjọ́ kejìlá, Áhírà+ ọmọ Énánì, ìjòyè àwọn ọmọ Náfútálì
79 mú ọrẹ wá, ọrẹ tó mú wá ni abọ́ ìjẹun fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti abọ́ fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, ó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́,+ ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró kún inú méjèèjì, láti fi ṣe ọrẹ ọkà;+
80 ife wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí tùràrí kún inú rẹ̀;
81 akọ ọmọ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan tó jẹ́ ọlọ́dún kan, láti fi rú ẹbọ sísun;+
82 ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+
83 àti màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀.+ Èyí ni ọrẹ tí Áhírà+ ọmọ Énánì mú wá.
84 Èyí ni ọrẹ+ tí àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì mú wá síbi ìyàsímímọ́ pẹpẹ nígbà tí wọ́n fòróró yàn án: abọ́ ìjẹun méjìlá (12) tí wọ́n fi fàdákà ṣe, abọ́ fàdákà méjìlá (12), ife wúrà méjìlá (12);+
85 ìwọ̀n abọ́ ìjẹun kọ̀ọ̀kan tí wọ́n fi fàdákà ṣe jẹ́ àádóje (130) ṣékélì, ìwọ̀n abọ́ kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, gbogbo fàdákà tí wọ́n fi ṣe àwọn ohun èlò náà jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (2,400) ṣékélì, ó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́;+
86 ìwọ̀n ọ̀kọ̀ọ̀kan ife wúrà méjìlá (12) náà tí tùràrí kún inú rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, ó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́, gbogbo wúrà àwọn ife náà jẹ́ ọgọ́fà (120) ṣékélì.
87 Gbogbo ẹran tí wọ́n fi rú ẹbọ sísun jẹ́ akọ màlúù méjìlá (12), àgbò méjìlá (12), akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méjìlá (12) tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan àti àwọn ọrẹ ọkà wọn àti ọmọ ewúrẹ́ méjìlá (12) tí wọ́n fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;
88 gbogbo ẹran tí wọ́n fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀ jẹ́ akọ màlúù mẹ́rìnlélógún (24), ọgọ́ta (60) àgbò, ọgọ́ta (60) òbúkọ àti ọgọ́ta (60) akọ ọ̀dọ́ àgùntàn tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan. Èyí ni ọrẹ+ tí wọ́n mú wá síbi ìyàsímímọ́ pẹpẹ lẹ́yìn tí wọ́n fòróró yàn án.+
89 Nígbàkigbà tí Mósè bá lọ sínú àgọ́ ìpàdé láti bá Ọlọ́run*+ sọ̀rọ̀, ó máa ń gbọ́ ohùn tó ń bá a sọ̀rọ̀ láti òkè ìbòrí+ àpótí Ẹ̀rí, láàárín àwọn kérúbù+ méjèèjì; Ọlọ́run á sì bá a sọ̀rọ̀.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “màlúù.”
^ Tàbí “ayẹyẹ tí wọ́n fi máa ṣí.”
^ Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.
^ Tàbí “ṣékélì mímọ́.”
^ Tàbí “abọ́ kékeré.”
^ Ní Héb., “bá a.”