Nọ́ńbà 8:1-26
8 Jèhófà sọ fún Mósè pé:
2 “Sọ fún Áárónì pé, ‘Tí o bá tan àwọn fìtílà, kí fìtílà méje mọ́lẹ̀ síwájú ọ̀pá fìtílà+ náà.’”
3 Ohun tí Áárónì sì ṣe nìyí: Ó tan àwọn fìtílà rẹ̀ kó lè mọ́lẹ̀ síwájú ọ̀pá fìtílà+ náà, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.
4 Bí wọ́n ṣe ṣe ọ̀pá fìtílà náà nìyí: Wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ni wọ́n fi ṣe é; òòlù ni wọ́n fi lù ú+ láti ibi ọ̀pá rẹ̀ débi àwọn ìtànná rẹ̀. Wọ́n ṣe ọ̀pá fìtílà náà bó ṣe rí nínú ìran+ tí Jèhófà fi han Mósè.
5 Jèhófà tún sọ fún Mósè pé:
6 “Mú àwọn ọmọ Léfì láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí o sì wẹ̀ wọ́n mọ́.+
7 Bí o ṣe máa wẹ̀ wọ́n mọ́ nìyí: Wọ́n omi ìwẹ̀mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ sí wọn lára, kí wọ́n sì fi abẹ fá gbogbo irun ara wọn, kí wọ́n fọ aṣọ wọn, kí wọ́n sì wẹ ara wọn mọ́.+
8 Kí wọ́n wá mú akọ ọmọ màlúù+ kan àti ọrẹ ọkà+ rẹ̀ tó jẹ́ ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró, kí o sì mú akọ ọmọ màlúù míì láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.+
9 Kí o mú àwọn ọmọ Léfì wá síwájú àgọ́ ìpàdé, kí o sì kó gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ jọ.
10 Tí o bá mú àwọn ọmọ Léfì wá síwájú Jèhófà, kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbé ọwọ́ wọn lé àwọn ọmọ Léfì.+
11 Kí Áárónì mú àwọn ọmọ Léfì wá* síwájú Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì+ láti ọwọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí wọ́n sì máa ṣiṣẹ́ Jèhófà.+
12 “Kí àwọn ọmọ Léfì gbé ọwọ́ wọn lé orí àwọn akọ màlúù+ náà. Lẹ́yìn náà, kí wọ́n fi ọ̀kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí wọ́n sì fi ìkejì rú ẹbọ sísun sí Jèhófà láti ṣe ètùtù+ fún àwọn ọmọ Léfì.
13 Kí o mú kí àwọn ọmọ Léfì dúró níwájú Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí o sì mú wọn wá* fún Jèhófà bí ọrẹ fífì.
14 Kí o ya àwọn ọmọ Léfì sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn ọmọ Léfì yóò sì di tèmi.+
15 Lẹ́yìn náà, kí àwọn ọmọ Léfì wọlé, kí wọ́n sì máa ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé. Bí o ṣe máa wẹ̀ wọ́n mọ́ nìyí, tí wàá sì mú wọn wá* bí ọrẹ fífì.
16 Àwọn ni a fi fúnni, a fún mi látinú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Èmi yóò mú wọn fún ara mi dípò gbogbo àkọ́bí* àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+
17 Torí tèmi ni gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ì báà jẹ́ èèyàn tàbí ẹranko.+ Ọjọ́ tí mo pa gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Íjíbítì+ ni mo yà wọ́n sí mímọ́ fún ara mi.
18 Èmi yóò mú àwọn ọmọ Léfì dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
19 Èmi yóò fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ní àwọn ọmọ Léfì bí àwọn tí a fi fúnni láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí wọ́n lè máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé+ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí wọ́n sì máa ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ kí ìyọnu má bàa dé bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì torí wọ́n sún mọ́ ibi mímọ́.”
20 Ohun tí Mósè àti Áárónì àti gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe fún àwọn ọmọ Léfì nìyẹn. Gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè nípa àwọn ọmọ Léfì ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gẹ́lẹ́.
21 Àwọn ọmọ Léfì wẹ ara wọn mọ́, wọ́n sì fọ aṣọ+ wọn. Lẹ́yìn náà, Áárónì mú wọn wá* síwájú Jèhófà+ bí ọrẹ fífì. Áárónì wá ṣe ètùtù fún wọn kó lè wẹ̀ wọ́n mọ́.+
22 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Léfì wọlé kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ wọn nínú àgọ́ ìpàdé níwájú Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀. Ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè nípa àwọn ọmọ Léfì ni wọ́n ṣe fún wọn gẹ́lẹ́.
23 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé:
24 “Èyí kan àwọn ọmọ Léfì: Kí ẹni tó bá ti pé ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé.
25 Àmọ́ tó bá ti lé ní ẹni àádọ́ta (50) ọdún, kó fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ náà, kó sì ṣíwọ́ iṣẹ́.
26 Ó lè máa ṣèrànwọ́ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ tí wọ́n ń ṣe ojúṣe wọn nínú àgọ́ ìpàdé, àmọ́ kó má ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Ohun tí o máa ṣe nípa àwọn ọmọ Léfì àti ojúṣe+ wọn nìyí.”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “fi àwọn ọmọ Léfì,” ìyẹn ni pé, kó fì wọ́n síwá-sẹ́yìn.
^ Ní Héb., “fì wọ́n,” ìyẹn ni pé, kó fì wọ́n síwá-sẹ́yìn.
^ Ní Héb., “fì wọ́n,” ìyẹn ni pé, kó fì wọ́n síwá-sẹ́yìn.
^ Tàbí “gbogbo àkọ́bí tó ṣí ilé ọmọ.”
^ Ní Héb., “fì wọ́n,” ìyẹn ni pé, kó fì wọ́n síwá-sẹ́yìn.