Nọ́ńbà 9:1-23
9 Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀ ní aginjù Sínáì ní oṣù kìíní,+ ọdún kejì tí wọ́n kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, ó sọ pé:
2 “Kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣètò ẹbọ+ Ìrékọjá ní àkókò rẹ̀.+
3 Ìrọ̀lẹ́* ọjọ́ kẹrìnlá oṣù yìí ni kí ẹ ṣètò rẹ̀ ní àkókò rẹ̀. Kí ẹ tẹ̀ lé gbogbo àṣẹ rẹ̀ àti ìlànà tó wà fún un tí ẹ bá ń ṣètò rẹ̀.”+
4 Mósè wá sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n ṣètò ẹbọ Ìrékọjá.
5 Ní ìrọ̀lẹ́* ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìíní, wọ́n ṣètò ẹbọ Ìrékọjá náà ní aginjù Sínáì. Gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe.
6 Ó ṣẹlẹ̀ pé àwọn ọkùnrin kan di aláìmọ́ torí wọ́n fara kan òkú èèyàn,*+ wọn ò wá lè ṣètò ẹbọ Ìrékọjá ní ọjọ́ yẹn. Torí náà, àwọn ọkùnrin náà wá sọ́dọ̀ Mósè àti Áárónì ní ọjọ́ yẹn,+
7 wọ́n sì sọ fún un pé: “A ti di aláìmọ́ torí a fara kan òkú èèyàn.* Kí ló dé tí a kò fi lè mú ọrẹ náà wá fún Jèhófà láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ ní àkókò rẹ̀?”
8 Ni Mósè bá dá wọn lóhùn pé: “Ẹ dúró ná, ẹ jẹ́ kí n gbọ́ ohun tí Jèhófà máa sọ nípa yín.”+
9 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé:
10 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Tí ẹnikẹ́ni nínú yín tàbí nínú àwọn ìran yín tó ń bọ̀ bá di aláìmọ́ torí pé ó fara kan òkú èèyàn*+ tàbí tí ó rin ìrìn àjò ọ̀nà jíjìn, ẹni náà ṣì gbọ́dọ̀ ṣètò ẹbọ Ìrékọjá fún Jèhófà.
11 Kí wọ́n ṣètò rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́* ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kejì.+ Kí wọ́n jẹ ẹ́ pẹ̀lú búrẹ́dì aláìwú àti ewébẹ̀ kíkorò.+
12 Wọn ò gbọ́dọ̀ ṣẹ́ ìkankan lára rẹ̀ kù di àárọ̀,+ wọn ò sì gbọ́dọ̀ fọ́ ìkankan nínú egungun rẹ̀.+ Kí wọ́n tẹ̀ lé gbogbo àṣẹ tó wà fún Ìrékọjá láti ṣètò rẹ̀.
13 Àmọ́ tí ẹnì kan bá wà ní mímọ́ tàbí tí kò rìnrìn àjò, tó sì kọ̀ láti ṣètò ẹbọ Ìrékọjá, ṣe ni kí ẹ pa ẹni* náà, kí ẹ lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀,+ torí kò mú ọrẹ Jèhófà wá ní àkókò rẹ̀. Ẹni náà yóò jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
14 “‘Tí àjèjì kan bá ń gbé lọ́dọ̀ yín, kí òun náà ṣètò ẹbọ Ìrékọjá fún Jèhófà.+ Kó tẹ̀ lé àṣẹ àti ìlànà tó wà fún Ìrékọjá láti ṣètò rẹ̀.+ Àṣẹ kan náà ni kí ẹ máa tẹ̀ lé, ì báà jẹ́ àjèjì tàbí ọmọ ìbílẹ̀.’”+
15 Ní ọjọ́ tí wọ́n to+ àgọ́ ìjọsìn, ìkùukùu* bo àgọ́ ìjọsìn náà, ìyẹn àgọ́ Ẹ̀rí, àmọ́ láti ìrọ̀lẹ́ títí di àárọ̀,+ ohun tó rí bí iná wà lórí àgọ́ ìjọsìn náà.
16 Bó ṣe máa ń ṣẹlẹ̀ nìyẹn: Ìkùukùu máa ń bò ó ní ọ̀sán, ohun tó rí bí iná sì máa ń bò ó ní òru.+
17 Ìgbàkígbà tí ìkùukùu náà bá kúrò lórí àgọ́ náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì á gbéra+ kíákíá, ibi tí ìkùukùu náà bá sì dúró sí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa pàgọ́+ sí.
18 Tí Jèhófà bá pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n gbéra, wọ́n á gbéra, tí Jèhófà bá sì pàṣẹ pé kí wọ́n pàgọ́, wọ́n á pàgọ́.+ Wọn kì í tú àgọ́ wọn ká ní gbogbo ìgbà tí ìkùukùu náà bá fi wà lórí àgọ́ ìjọsìn.
19 Tí ìkùukùu náà bá wà lórí àgọ́ ìjọsìn fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ṣègbọràn sí Jèhófà, wọn ò sì ní tú àgọ́ wọn ká.+
20 Nígbà míì, ìkùukùu máa ń wà lórí àgọ́ ìjọsìn fún ọjọ́ mélòó kan. Tí Jèhófà bá pàṣẹ pé kí wọ́n ṣì wà níbi tí wọ́n pàgọ́ sí, wọ́n á ṣe bẹ́ẹ̀, tí Jèhófà bá sì pàṣẹ pé kí wọ́n gbéra, wọ́n á gbéra.
21 Nígbà míì, ó lè má ju ìrọ̀lẹ́ sí àárọ̀ tí ìkùukùu náà á fi dúró, tí ìkùukùu náà bá sì gbéra ní àárọ̀, àwọn èèyàn náà máa gbéra. Ì báà jẹ́ ọ̀sán tàbí òru ni ìkùukùu náà gbéra, àwọn èèyàn náà máa gbéra.+
22 Ì báà jẹ́ ọjọ́ méjì, oṣù kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni ìkùukùu náà fi wà lórí àgọ́ ìjọsìn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò ní tú àgọ́ wọn ká, wọn ò sì ní gbéra. Àmọ́ tó bá ti gbéra, àwọn náà á gbéra.
23 Tí Jèhófà bá pàṣẹ pé kí wọ́n pàgọ́, wọ́n á pàgọ́. Tí Jèhófà bá sì pàṣẹ pé kí wọ́n gbéra, wọ́n á gbéra. Wọ́n ń ṣe ojúṣe wọn sí Jèhófà bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ nípasẹ̀ Mósè.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “Láàárín ìrọ̀lẹ́ méjèèjì.”
^ Ní Héb., “Láàárín ìrọ̀lẹ́ méjèèjì.”
^ Tàbí “ọkàn kan.”
^ Tàbí “torí ọkàn kan.”
^ Tàbí “ọkàn kan.”
^ Ní Héb., “láàárín ìrọ̀lẹ́ méjèèjì.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “àwọsánmà.”