Nehemáyà 12:1-47
12 Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì tó tẹ̀ lé Serubábélì+ ọmọ Ṣéálítíẹ́lì+ àti Jéṣúà+ nìyí: Seráyà, Jeremáyà, Ẹ́sírà,
2 Amaráyà, Málúkù, Hátúṣì,
3 Ṣẹkanáyà, Réhúmù, Mérémótì,
4 Ídò, Gínétóì, Ábíjà,
5 Míjámínì, Maadáyà, Bílígà,
6 Ṣemáyà, Jóyáríbù, Jedáyà,
7 Sáálù, Ámókì, Hilikáyà àti Jedáyà. Àwọn ni olórí àwọn àlùfáà àti àwọn arákùnrin wọn nígbà ayé Jéṣúà.
8 Àwọn ọmọ Léfì ni Jéṣúà, Bínúì, Kádímíélì,+ Ṣerebáyà, Júdà àti Matanáyà + tó ń gbé orin ọpẹ́ pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀.
9 Bakibúkáyà àti Únì tí wọ́n jẹ́ arákùnrin wọn sì dúró ní òdìkejì wọn láti máa ṣe iṣẹ́ ẹ̀ṣọ́.*
10 Jéṣúà bí Jóyákímù, Jóyákímù bí Élíáṣíbù,+ Élíáṣíbù sì bí Jóyádà.+
11 Jóyádà bí Jónátánì, Jónátánì sì bí Jádúà.
12 Nígbà ayé Jóyákímù, àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ olórí agbo ilé nìyí: fún Seráyà,+ Meráyà; fún Jeremáyà, Hananáyà;
13 fún Ẹ́sírà,+ Méṣúlámù; fún Amaráyà, Jèhóhánánì;
14 fún Málúkì, Jónátánì; fún Ṣebanáyà, Jósẹ́fù;
15 fún Hárímù,+ Ádúnà; fún Méráótì, Hélíkáì;
16 fún Ídò, Sekaráyà; fún Gínétónì, Méṣúlámù;
17 fún Ábíjà,+ Síkírì; fún Míníámínì, . . . ;* fún Moadáyà, Pílítáì;
18 fún Bílígà,+ Ṣámúà; fún Ṣemáyà, Jèhónátánì;
19 fún Jóyáríbù, Máténáì; fún Jedáyà,+ Úsáì;
20 fún Sáláì, Káláì; fún Ámókì, Ébérì;
21 fún Hilikáyà, Haṣabáyà; fún Jedáyà, Nétánélì.
22 Àwọn olórí agbo ilé àwọn ọmọ Léfì àti ti àwọn àlùfáà wà lákọsílẹ̀ nígbà ayé Élíáṣíbù, Jóyádà, Jóhánánì àti Jádúà,+ títí di ìgbà ìjọba Dáríúsì ará Páṣíà.
23 Àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ olórí agbo ilé wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn àkókò náà, títí di ìgbà ayé Jóhánánì ọmọ Élíáṣíbù.
24 Àwọn olórí àwọn ọmọ Léfì ni Haṣabáyà, Ṣerebáyà àti Jéṣúà+ ọmọ Kádímíélì,+ àwọn arákùnrin wọn dúró ní òdìkejì wọn láti máa yin Ọlọ́run, kí wọ́n sì máa dúpẹ́, gẹ́gẹ́ bí Dáfídì èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ ṣe pa á láṣẹ,+ àwùjọ ẹ̀ṣọ́ kan dojú kọ àwùjọ ẹ̀ṣọ́ kejì.
25 Matanáyà,+ Bakibúkáyà, Ọbadáyà, Méṣúlámù, Tálímónì àti Ákúbù+ jẹ́ aṣọ́bodè+ tó ń ṣọ́ àwọn yàrá tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnubodè.
26 Àwọn yìí ṣiṣẹ́ nígbà ayé Jóyákímù ọmọ Jéṣúà + ọmọ Jósádákì àti nígbà ayé Nehemáyà gómìnà àti Ẹ́sírà+ tó jẹ́ àlùfáà àti adàwékọ.*
27 Nígbà ayẹyẹ ṣíṣí ògiri Jerúsálẹ́mù, wọ́n wá àwọn ọmọ Léfì, wọ́n sì mú wọn wá sí Jerúsálẹ́mù láti gbogbo ibi tí wọ́n ń gbé kí wọ́n lè ṣe ayẹyẹ náà tayọ̀tayọ̀, pẹ̀lú orin ọpẹ́,+ pẹ̀lú síńbálì* àti àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti háàpù.
28 Àwọn ọmọ àwọn akọrin* kóra jọ láti agbègbè* náà, láti gbogbo àyíká Jerúsálẹ́mù, láti àwọn ibi tí àwọn ará Nétófà+ tẹ̀ dó sí,
29 láti Bẹti-gílígálì+ àti láti àwọn pápá Gébà+ àti Ásímáfẹ́tì,+ nítorí àwọn akọrin ti kọ́ àwọn ibi tí wọ́n á máa gbé ní gbogbo àyíká Jerúsálẹ́mù.
30 Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì sọ ara wọn di mímọ́, wọ́n sì sọ àwọn èèyàn náà di mímọ́+ àti àwọn ẹnubodè+ pẹ̀lú ògiri náà.+
31 Lẹ́yìn náà, mo mú àwọn olórí Júdà wá sórí ògiri náà. Yàtọ̀ síyẹn, mo yan ẹgbẹ́ ńlá méjì tó ń kọrin ọpẹ́ àti àwọn àwùjọ tí á máa tẹ̀ lé wọn, ọ̀kan lára àwọn ẹgbẹ́ akọrin náà sì lọ sápá ọ̀tún lórí ògiri tó lọ sí Ẹnubodè Àwọn Òkìtì Eérú.+
32 Hóṣáyà àti ìdajì àwọn olórí Júdà ń tẹ̀ lé wọn
33 pẹ̀lú Asaráyà, Ẹ́sírà, Méṣúlámù,
34 Júdà, Bẹ́ńjámínì, Ṣemáyà àti Jeremáyà.
35 Lára àwọn ọmọ àlùfáà tó wà pẹ̀lú wọn, tí wọ́n mú kàkàkí+ lọ́wọ́ ni: Sekaráyà ọmọ Jónátánì ọmọ Ṣemáyà ọmọ Matanáyà ọmọ Mikáyà ọmọ Sákúrì ọmọ Ásáfù +
36 àti àwọn arákùnrin rẹ̀, Ṣemáyà àti Ásárẹ́lì, Míláláì, Gíláláì, Máì, Nétánélì, Júdà àti Hánáánì, wọ́n mú ohun ìkọrin Dáfídì+ èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ lọ́wọ́; Ẹ́sírà+ adàwékọ* sì ń lọ níwájú wọn.
37 Wọ́n dé Ẹnubodè Ojúsun,+ wọ́n sì lọ tààrà sórí Àtẹ̀gùn+ Ìlú Dáfídì+ níbi ìgòkè ògiri lórí Ilé Dáfídì títí lọ dé Ẹnubodè Omi+ ní ìlà oòrùn.
38 Ẹgbẹ́ akọrin ọpẹ́ kejì gba òdìkejì* lọ, èmi àti ìdajì àwọn èèyàn náà sì tẹ̀ lé wọn, lórí ògiri lókè Ilé Gogoro Ààrò+ títí dé orí Ògiri Fífẹ̀+
39 àti lókè Ẹnubodè Éfúrémù+ títí dé Ẹnubodè Ìlú Àtijọ́+ àti títí dé Ẹnubodè Ẹja,+ Ilé Gogoro Hánánélì,+ Ilé Gogoro Méà àti títí dé Ẹnubodè Àgùntàn;+ wọ́n sì dúró ní Ẹnubodè Ẹ̀ṣọ́.
40 Nígbà tó yá, ẹgbẹ́ akọrin ọpẹ́ méjèèjì dúró níwájú ilé Ọlọ́run tòótọ́; bẹ́ẹ̀ ni èmi àti ìdajì àwọn alábòójútó tó wà pẹ̀lú mi ṣe
41 àti àwọn àlùfáà, ìyẹn Élíákímù, Maaseáyà, Míníámínì, Mikáyà, Élíóénáì, Sekaráyà àti Hananáyà pẹ̀lú àwọn kàkàkí lọ́wọ́
42 àti Maaseáyà, Ṣemáyà, Élíásárì, Úsáì, Jèhóhánánì, Málíkíjà, Élámù àti Ésérì. Àwọn akọrin náà kọrin sókè lábẹ́ àbójútó Isiráháyà.
43 Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n rú àwọn ẹbọ ńlá, wọ́n sì ń yọ̀,+ nítorí Ọlọ́run tòótọ́ ti mú kí wọ́n yọ ayọ̀ ńlá. Bákan náà, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé ń yọ̀,+ tó fi jẹ́ pé àwọn tó wà níbi tó jìnnà réré ń gbọ́ ìró ayọ̀ Jerúsálẹ́mù.+
44 Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n yan àwọn tí á máa bójú tó àwọn ilé ìkẹ́rùsí,+ èyí tó wà fún àwọn ọrẹ,+ àwọn àkọ́so èso+ àti àwọn ìdá mẹ́wàá.+ Inú àwọn ilé náà ni wọ́n á máa kó àwọn nǹkan tí wọ́n kórè látinú àwọn oko tó wà ní àwọn ìlú sí, gẹ́gẹ́ bí Òfin ṣe sọ+ pé kí wọ́n máa fún àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì.+ Àwọn èèyàn sì ń yọ̀ ní Júdà torí pé àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn.
45 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún wọn àti iṣẹ́ ìwẹ̀mọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́bodè ń ṣe iṣẹ́ tiwọn, gẹ́gẹ́ bí Dáfídì àti Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ ṣe pa á láṣẹ.
46 Nítorí ó ti pẹ́ gan-an láti ìgbà ayé Dáfídì àti Ásáfù tí àwọn olùdarí* ti wà fún àwọn akọrin àti fún àwọn orin ìyìn àti orin ọpẹ́ sí Ọlọ́run.+
47 Nígbà ayé Serubábélì+ àti nígbà ayé Nehemáyà, gbogbo Ísírẹ́lì ń mú oúnjẹ wá fún àwọn akọrin+ àti àwọn aṣọ́bodè+ bí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan bá ṣe gbà. Wọ́n tún ya oúnjẹ sọ́tọ̀ tí wọ́n ń fún àwọn ọmọ Léfì,+ àwọn ọmọ Léfì sì ń ya apá kan sọ́tọ̀ fún àwọn àtọmọdọ́mọ Áárónì.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí kó jẹ́, “nígbà iṣẹ́ ìsìn.”
^ Ó ṣe kedere pé àkọsílẹ̀ Hébérù fo orúkọ kan níbí yìí.
^ Tàbí “akọ̀wé òfin.”
^ Tàbí “aro.”
^ Tàbí “àwọn akọrin tó kọ́ṣẹ́ orin.”
^ Ìyẹn, agbègbè tó yí Jọ́dánì ká.
^ Tàbí “akọ̀wé òfin.”
^ Tàbí “iwájú.”
^ Ní Héb., “àwọn olórí.”