Nehemáyà 13:1-31
13 Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n ka ìwé Mósè sétí àwọn èèyàn,+ wọ́n sì rí i pé ó wà lákọsílẹ̀ pé àwọn ọmọ Ámónì àti àwọn ọmọ Móábù+ kò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Ọlọ́run tòótọ́ láé,+
2 nítorí wọn kò fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní oúnjẹ àti omi, dípò bẹ́ẹ̀ ṣe ni wọ́n háyà Báláámù láti gégùn-ún fún wọn.+ Àmọ́, Ọlọ́run wa yí ègún náà pa dà sí ìbùkún.+
3 Nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ inú Òfin náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ya onírúurú àjèjì* tó wà láàárín Ísírẹ́lì sọ́tọ̀.+
4 Ṣáájú àkókò yìí, Élíáṣíbù + tó jẹ́ ìbátan Tòbáyà+ ni àlùfáà tó ń bójú tó àwọn yàrá tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí* ní ilé* Ọlọ́run wa.+
5 Ó ti ṣètò yàrá ńlá kan tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí* fún un, ibẹ̀ ni wọ́n máa ń kó ọrẹ ọkà sí tẹ́lẹ̀ pẹ̀lú oje igi tùràrí àti àwọn nǹkan èlò, ibẹ̀ tún ni wọ́n ń kó ìdá mẹ́wàá ọkà, ti wáìnì tuntun àti ti òróró+ sí, èyí tó wà fún àwọn ọmọ Léfì,+ àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́bodè, ibẹ̀ náà ni wọ́n sì ń kó ọrẹ tó wà fún àwọn àlùfáà sí.+
6 Ní gbogbo àkókò yìí, mi ò sí ní Jerúsálẹ́mù, nítorí mo lọ sọ́dọ̀ ọba ní ọdún kejìlélọ́gbọ̀n+ Atasásítà+ ọba Bábílónì; lẹ́yìn ìgbà yẹn, mo gba àyè kúrò lẹ́nu iṣẹ́ lọ́dọ̀ ọba.
7 Lẹ́yìn náà, mo wá sí Jerúsálẹ́mù, mo sì rí nǹkan burúkú tí Élíáṣíbù+ ṣe nítorí Tòbáyà,+ ó ti ṣètò yàrá kan tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí fún un ní àgbàlá ilé Ọlọ́run tòótọ́.
8 Nǹkan yìí múnú bí mi gan-an, torí náà, mo da gbogbo ẹrù ilé Tòbáyà sóde yàrá* náà.
9 Lẹ́yìn ìyẹn, mo pàṣẹ, wọ́n sì fọ àwọn yàrá* náà mọ́; mo wá dá àwọn nǹkan èlò ilé Ọlọ́run tòótọ́+ pa dà síbẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ ọkà àti oje igi tùràrí.+
10 Mo tún rí i pé wọn ò fún àwọn ọmọ Léfì+ ní ìpín wọn,+ tó fi di pé àwọn ọmọ Léfì àti àwọn akọrin tó ń ṣe iṣẹ́ náà lọ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan sí pápá wọn.+
11 Torí náà, mo bá àwọn alábòójútó wí,+ mo sì sọ pé: “Kí ló dé tí ẹ jẹ́ kí wọ́n pa ilé Ọlọ́run tòótọ́ tì?”+ Ni mo bá kó wọn jọ, mo sì yàn wọ́n pa dà sí ipò wọn.
12 Gbogbo Júdà sì kó ìdá mẹ́wàá+ ọkà àti ti wáìnì tuntun àti ti òróró wá sí àwọn yàrá tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí.+
13 Lẹ́yìn náà, mo fi àlùfáà Ṣelemáyà, Sádókù adàwékọ* àti Pedáyà lára àwọn ọmọ Léfì sídìí àbójútó àwọn yàrá tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí, Hánánì ọmọ Sákúrì ọmọ Matanáyà sì ni olùrànlọ́wọ́ wọn, nítorí wọ́n ṣeé fọkàn tán. Iṣẹ́ wọn ni láti pín nǹkan fún àwọn arákùnrin wọn.
14 Ọlọ́run mi, rántí mi+ nítorí èyí, má sì gbàgbé ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí mo ti fi hàn sí ilé Ọlọ́run mi àti iṣẹ́ ìsìn* rẹ̀.+
15 Ní àkókò yẹn, mo rí àwọn èèyàn ní Júdà tí wọ́n ń fún wáìnì ní Sábáàtì,+ tí wọ́n ń kó òkìtì ọkà wá, tí wọ́n sì ń dì wọ́n lé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, wọ́n ń kó wáìnì, èso àjàrà àti ọ̀pọ̀tọ́ pẹ̀lú oríṣiríṣi ẹrù wá sí Jerúsálẹ́mù ní ọjọ́ Sábáàtì.+ Torí náà, mo kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n má ta nǹkan kan lọ́jọ́ náà.*
16 Àwọn ará Tírè tó ń gbé ní ìlú náà ń kó ẹja àti oríṣiríṣi ọjà wá, wọ́n sì ń tà wọ́n fún àwọn èèyàn Júdà àti ní Jerúsálẹ́mù ní ọjọ́ Sábáàtì.+
17 Torí náà, mo bá àwọn èèyàn pàtàkì ní Júdà wí, mo sì sọ fún wọn pé: “Nǹkan burúkú wo lẹ̀ ń ṣe yìí, tí ẹ̀ ń tẹ òfin Sábáàtì lójú?
18 Ṣé kì í ṣe ohun tí àwọn baba ńlá yín ṣe nìyí tí Ọlọ́run wa fi mú gbogbo àjálù yìí bá àwá àti ìlú yìí? Báyìí, ńṣe lẹ̀ ń dá kún ìbínú tó ń jó fòfò lórí Ísírẹ́lì bí ẹ ò ṣe pa Sábáàtì mọ́.”+
19 Mo pàṣẹ pé kí wọ́n ti àwọn ẹnubodè Jerúsálẹ́mù pa kí ilẹ̀ tó ṣú, ìyẹn kí Sábáàtì tó bẹ̀rẹ̀. Mo tún sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ ṣí wọn títí di ẹ̀yìn Sábáàtì, mo fi lára àwọn ìránṣẹ́ mi sí àwọn ẹnubodè náà kí wọ́n má bàa kó ẹrù kankan wọlé ní ọjọ́ Sábáàtì.
20 Torí náà, ẹ̀yìn òde Jerúsálẹ́mù ni àwọn oníṣòwò àti àwọn tó ń ta oríṣiríṣi ọjà sùn mọ́jú, wọ́n sùn síbẹ̀ lẹ́ẹ̀kan tàbí lẹ́ẹ̀mejì.
21 Lẹ́yìn náà, mo kìlọ̀ fún wọn, mo sì sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ fi ń sùn níwájú ògiri? Tí ẹ bá tún ṣe bẹ́ẹ̀, màá lé yín kúrò níbẹ̀ tipátipá.” Láti ìgbà yẹn lọ, wọn ò wá lọ́jọ́ Sábáàtì mọ́.
22 Mo wá sọ fún àwọn ọmọ Léfì pé kí wọ́n máa sọ ara wọn di mímọ́, kí wọ́n sì wá máa ṣọ́ àwọn ẹnubodè láti mú kí ọjọ́ Sábáàtì wà ní mímọ́.+ Ọlọ́run mi, jọ̀wọ́ rántí ṣojú rere sí mi nítorí èyí pẹ̀lú, kí o sì ṣàánú mi nínú ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tí ó pọ̀ gidigidi.+
23 Ní àkókò yẹn, mo rí àwọn Júù tí wọ́n fẹ́ àwọn obìnrin tó jẹ́ ará Áṣídódì,+ ọmọ Ámónì àti ọmọ Móábù.*+
24 Ìdajì lára àwọn ọmọ wọn ń sọ èdè àwọn ará Áṣídódì àti àwọn èdè míì, kò sí ìkankan nínú wọn tó lè sọ èdè àwọn Júù.
25 Torí náà, mo bá wọn wí, mo sì gégùn-ún fún wọn, mo lu àwọn ọkùnrin kan lára wọn,+ mo fa irun wọn tu, mo sì mú kí wọ́n fi Ọlọ́run búra pé: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ fi àwọn ọmọbìnrin yín fún àwọn ọmọkùnrin wọn, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín tàbí fún ara yín.+
26 Ṣé kì í ṣe tìtorí èyí ni Sólómọ́nì ọba Ísírẹ́lì fi dẹ́ṣẹ̀? Kò sí ọba tó dà bíi rẹ̀ láàárín ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè;+ Ọlọ́run rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀+ débi pé ó fi í jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì. Síbẹ̀ àwọn àjèjì obìnrin tó fẹ́ mú òun pàápàá dẹ́ṣẹ̀.+
27 Ṣé ó ṣeé gbọ́ sétí pé ẹ dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá yìí, tí ẹ hùwà àìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wa bí ẹ ṣe lọ ń fẹ́ àwọn àjèjì obìnrin?”+
28 Ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin Jóyádà+ ọmọ Élíáṣíbù + àlùfáà àgbà ti di àna Sáńbálátì+ tó jẹ́ ará Hórónì. Torí náà, mo lé e kúrò lọ́dọ̀ mi.
29 Ọlọ́run mi, jọ̀wọ́ rántí wọn, nítorí wọ́n ti kó àbààwọ́n bá iṣẹ́ àlùfáà àti májẹ̀mú iṣẹ́ àlùfáà+ àti ti àwọn ọmọ Léfì.+
30 Mo wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò nínú gbogbo ohun àìmọ́ tó jẹ́ ti àwọn àjèjì, mo sì yan iṣẹ́ fún àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì, kálukú sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀,+
31 mo ṣètò bí wọ́n á ṣe máa kó igi wá+ ní àkókò tí a dá, mo sì tún ṣètò bí wọ́n á ṣe máa kó àkọ́so èso wá.
Ọlọ́run mi, jọ̀wọ́ rántí mi sí rere.*+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “onírúurú èèyàn.”
^ Tàbí “àwọn gbọ̀ngàn ìjẹun.”
^ Tàbí “tẹ́ńpìlì.”
^ Tàbí “gbọ̀ngàn ìjẹun.”
^ Tàbí “gbọ̀ngàn ìjẹun.”
^ Tàbí “àwọn gbọ̀ngàn ìjẹun.”
^ Tàbí “akọ̀wé òfin.”
^ Tàbí “àbójútó.”
^ Tàbí kó jẹ́, “lọ́jọ́ náà, mo kìlọ̀ fún wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ ta nǹkan kan.”
^ Tàbí “tí wọ́n gbé . . . sílé.”
^ Tàbí “fún ire.”