Sí Àwọn Ará Róòmù 13:1-14
13 Kí gbogbo èèyàn* máa tẹrí ba fún àwọn aláṣẹ onípò gíga,+ nítorí kò sí àṣẹ kankan àfi èyí tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run;+ àwọn aláṣẹ tó wà ni a gbé sí àwọn ipò wọn tó ní ààlà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.+
2 Nítorí náà, ẹni tó bá ta ko aláṣẹ ta ko ètò tí Ọlọ́run ṣe; àwọn tó bá ta kò ó máa gba ìdájọ́ sórí ara wọn.
3 Torí àwọn tó ń ṣàkóso jẹ́ ohun ẹ̀rù, kì í ṣe sí àwọn tó ń ṣe rere, àmọ́ sí àwọn tó ń ṣe búburú.+ Ṣé o kò fẹ́ kí ẹ̀rù aláṣẹ máa bà ọ́? Máa ṣe rere,+ wàá sì gba ìyìn nítorí rẹ̀;
4 torí òjíṣẹ́ Ọlọ́run ló jẹ́ sí ọ fún ire rẹ. Àmọ́ tí o bá ń ṣe ohun búburú, máa bẹ̀rù, nítorí kì í ṣàdédé gbé idà. Òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni, ó ń gbẹ̀san láti fi ìrunú hàn sí* ẹni tó ń ṣe ohun búburú.
5 Torí náà, ìdí pàtàkì wà tó fi yẹ kí ẹ máa tẹrí ba, kì í ṣe nítorí ìrunú yẹn nìkan, àmọ́ ó jẹ́ nítorí ẹ̀rí ọkàn+ yín pẹ̀lú.
6 Ìdí nìyẹn tí ẹ tún fi ń san owó orí; nítorí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run fún gbogbo èèyàn, wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ yìí nígbà gbogbo.
7 Ẹ fún gbogbo èèyàn ní ohun tí ó tọ́ sí wọn: ẹni tó béèrè owó orí, ẹ fún un ní owó orí;+ ẹni tó béèrè ìṣákọ́lẹ̀,* ẹ fún un ní ìṣákọ́lẹ̀; ẹni tí ìbẹ̀rù yẹ, ẹ bẹ̀rù rẹ̀ bó ṣe yẹ;+ ẹni tí ọlá yẹ, ẹ bọlá fún un bó ṣe yẹ.+
8 Ẹ má jẹ ẹnikẹ́ni ní gbèsè ohunkóhun, àmọ́ kí ẹ máa nífẹ̀ẹ́ ara yín;+ nítorí ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ̀ ti mú òfin ṣẹ.+
9 Nítorí àkójọ òfin tó sọ pé, “O ò gbọ́dọ̀ ṣe àgbèrè,+ o ò gbọ́dọ̀ pààyàn,+ o ò gbọ́dọ̀ jalè,+ o ò gbọ́dọ̀ ṣojúkòkòrò”+ àti àṣẹ míì tó bá wà, ni a kó pọ̀ sínú ọ̀rọ̀ yìí, pé: “Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.”+
10 Ìfẹ́ kì í ṣiṣẹ́ ibi sí ọmọnìkejì ẹni;+ torí náà, ìfẹ́ ni àkójá òfin.+
11 Kí ẹ ṣe èyí nítorí ẹ mọ àsìkò tí a wà, pé wákàtí ti tó fún yín láti jí lójú oorun,+ torí ní báyìí, ìgbàlà wa ti sún mọ́lé ju ti ìgbà tí a di onígbàgbọ́.
12 Òru ti lọ jìnnà; ilẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ mọ́. Torí náà, ẹ jẹ́ ká ju àwọn iṣẹ́ tó jẹ́ ti òkùnkùn nù,+ ká sì gbé àwọn ohun ìjà ìmọ́lẹ̀ wọ̀.+
13 Ẹ jẹ́ ká máa rìn lọ́nà tó bójú mu+ bí ìgbà téèyàn ń rìn ní ọ̀sán, kì í ṣe nínú àwọn àríyá aláriwo àti ìmutípara, kì í ṣe nínú ìṣekúṣe àti ìwà àìnítìjú,*+ kì í ṣe nínú wàhálà àti owú.+
14 Àmọ́, ẹ gbé Olúwa Jésù Kristi wọ̀,+ ẹ má sì máa gbèrò àwọn ìfẹ́ ti ara.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “láti fìyà jẹ.”
^ Tàbí “owó òde.”
^ Tàbí “ìwà ọ̀dájú.” Ó ń tọ́ka sí ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, a·selʹgei·a tí wọ́n bá lò ó fún ohun tó ju ẹyọ kan lọ. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.