Sáàmù 102:1-28

  • Àdúrà ẹni tí a ni lára nígbà tí nǹkan tojú sú u

    • “Mo dà bí ẹyẹ tó dá wà lórí òrùlé” (7)

    • ‘Àwọn ọjọ́ mi jẹ́ òjìji tó ń pa rẹ́ lọ’ (11)

    • “Jèhófà máa tún Síónì kọ́” (16)

    • Jèhófà wà títí láé (26, 27)

Àdúrà ẹni tí ìnilára bá nígbà tí nǹkan tojú sú u,* tó sì ń sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ níwájú Jèhófà.+ 102  Jèhófà, gbọ́ àdúrà mi;+Jẹ́ kí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́ dé ọ̀dọ̀ rẹ.+   Má fi ojú rẹ pa mọ́ fún mi nígbà tí mo wà nínú wàhálà.+ Tẹ́tí sí mi;*Tètè dá mi lóhùn nígbà tí mo bá pè ọ́.+   Nítorí àwọn ọjọ́ mi ń pa rẹ́ lọ bí èéfín,Àwọn egungun mi sì ti di dúdú bí ibi ìdáná.+   Ọkàn mi dà bíi koríko tí a gé, tó sì ti rọ,+Nítorí mi ò rántí jẹ oúnjẹ mi.   Nítorí bí mo ṣe ń kérora gidigidi,+Egungun mi ti lẹ̀ mọ́ ẹran ara mi.+   Mo dà bí ẹyẹ òfú tó wà ní aginjù;Mo dà bí òwìwí kékeré tó wà láàárín àwókù.   Mi ò rí oorun sùn;*Mo dà bí ẹyẹ tó dá wà lórí òrùlé.+   Àwọn ọ̀tá mi ń pẹ̀gàn mi láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.+ Àwọn tó ń fi mí ṣẹ̀sín* ń lo orúkọ mi tí wọ́n bá fẹ́ gégùn-ún.   Eérú ni mo fi ń ṣe oúnjẹ jẹ,+Omijé sì ti dà pọ̀ mọ́ ohun tí mò ń mu,+ 10  Nítorí ìbínú rẹ àti ìrunú rẹ,O gbé mi sókè kí o lè jù mí sí ẹ̀gbẹ́ kan. 11  Àwọn ọjọ́ mi dà bí òjìji tó ń pa rẹ́ lọ,*+Mo sì ń rọ bíi koríko.+ 12  Àmọ́, Jèhófà, o wà títí láé,+Òkìkí rẹ yóò sì máa kàn* láti ìran dé ìran.+ 13  Ó dájú pé wàá dìde, wàá sì ṣàánú Síónì,+Torí àkókò ti tó láti ṣe ojú rere sí i;+Àkókò tí a dá ti pé.+ 14  Nítorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ fẹ́ràn àwọn òkúta rẹ̀,+Kódà, wọ́n nífẹ̀ẹ́ erùpẹ̀ rẹ̀.+ 15  Àwọn orílẹ̀-èdè yóò máa bẹ̀rù orúkọ Jèhófà,Gbogbo ọba ayé yóò sì máa bẹ̀rù ògo rẹ.+ 16  Jèhófà máa tún Síónì kọ́;+Á fara hàn nínú ògo rẹ̀.+ 17  Á fetí sí àdúrà àwọn òtòṣì,+Kò sì ní kó àdúrà wọn dà nù.+ 18  A kọ èyí sílẹ̀ torí ìran tó ń bọ̀,+Kí àwọn èèyàn tí a ó bí* lè yin Jáà. 19  Ó ń bojú wolẹ̀ láti ibi gíga rẹ̀ mímọ́,+Láti ọ̀run, Jèhófà ń wo ayé, 20  Kí ó lè gbọ́ bí ẹlẹ́wọ̀n ṣe ń kérora,+Kí ó lè dá àwọn tí wọ́n ti dájọ́ ikú fún sílẹ̀,+ 21  Ká lè kéde orúkọ Jèhófà ní Síónì+Àti ìyìn rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù, 22  Nígbà tí àwọn èèyàn àti àwọn ìjọbaBá kóra jọ láti sin Jèhófà.+ 23  Ó gba agbára mi láìtọ́jọ́;Ó gé ọjọ́ ayé mi kúrú. 24  Mo sọ pé: “Ìwọ Ọlọ́run mi,Má ṣe dá ẹ̀mí mi légbodò,*Ìwọ tí àwọn ọdún rẹ lọ láti ìran dé ìran.+ 25  Tipẹ́tipẹ́ lo ti fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,Ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.+ 26  Wọ́n á ṣègbé, àmọ́ ìwọ á máa wà nìṣó;Gbogbo wọn á gbó bí aṣọ. Wàá pààrọ̀ wọn bí aṣọ, wọn ò sì ní sí mọ́. 27  Àmọ́ ìwọ kò yí pa dà, àwọn ọdún rẹ kò sì ní dópin láé.+ 28  Ọmọ àwọn ìránṣẹ́ rẹ yóò máa wà láìséwu,A ó sì fìdí àtọmọdọ́mọ wọn múlẹ̀ gbọn-in níwájú rẹ.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “tí àárẹ̀ mú un.”
Tàbí “Bẹ̀rẹ̀ kí o sì fetí sí mi.”
Tàbí kó jẹ́, “Mo ti rù kan eegun.”
Tàbí “tó ń dá yẹ̀yẹ́ mi sílẹ̀.”
Tàbí “òjìji àṣálẹ́.”
Tàbí “Orúkọ rẹ yóò sì wà.” Ní Héb., “Ìrántí.”
Ní Héb., “dá.”
Ní Héb., “Má ṣe mú mi kúrò ní ààbọ̀ àwọn ọjọ́ mi.”