Sáàmù 146:1-10
146 Ẹ yin Jáà!*+
Kí gbogbo ara* mi yin Jèhófà.+
2 Màá yin Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé mi.
Màá kọ orin ìyìn* sí Ọlọ́run mi nígbà tí mo bá wà láàyè.
3 Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé àwọn olórí*Tàbí lé ọmọ èèyàn, tí kò lè gbani là.+
4 Ẹ̀mí* rẹ̀ jáde lọ, ó pa dà sínú ilẹ̀;+Ọjọ́ yẹn gan-an ni èrò inú rẹ̀ ṣègbé.+
5 Aláyọ̀ ni ẹni tí Ọlọ́run Jékọ́bù jẹ́ olùrànlọ́wọ́ rẹ̀,+Tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀,+
6 Aṣẹ̀dá ọ̀run àti ayé,Òkun àti gbogbo ohun tó wà nínú wọn,+Ẹni tó jẹ́ olóòótọ́ nígbà gbogbo,+
7 Ẹni tó ń ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn tí wọ́n lù ní jìbìtì,Ẹni tó ń fún àwọn tí ebi ń pa lóúnjẹ.+
Jèhófà ń dá àwọn ẹlẹ́wọ̀n* sílẹ̀.+
8 Jèhófà ń la ojú àwọn afọ́jú;+Jèhófà ń gbé àwọn tó sorí kọ́ dìde;+Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn olódodo.
9 Jèhófà ń dáàbò bo àwọn àjèjì;Ó ń fún ọmọ aláìníbaba àti opó lókun,+Àmọ́, ó ń sọ èrò àwọn ẹni burúkú dòfo.*+
10 Jèhófà yóò jẹ Ọba títí láé,+Àní Ọlọ́run rẹ, ìwọ Síónì, láti ìran dé ìran.
Ẹ yin Jáà!*
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “kọrin.”
^ Tàbí “èèyàn pàtàkì.”
^ Tàbí “Èémí.”
^ Ní Héb., “àwọn tí a dè.”
^ Tàbí “sọ ọ̀nà àwọn ẹni burúkú di wíwọ́.”
^ Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.