Sáàmù 66:1-20
Sí olùdarí. Orin. Orin atunilára.
66 Gbogbo ayé, ẹ kígbe ìṣẹ́gun sí Ọlọ́run.+
2 Ẹ fi orin yin* orúkọ rẹ̀ ológo.
Ẹ mú kí ìyìn rẹ̀ ní ògo.+
3 Ẹ sọ fún Ọlọ́run pé: “Àwọn iṣẹ́ rẹ mà bani lẹ́rù o!+
Nítorí agbára ńlá rẹ,Àwọn ọ̀tá rẹ yóò ba búrúbúrú níwájú rẹ.+
4 Gbogbo ayé yóò forí balẹ̀ fún ọ;+Wọ́n á kọ orin ìyìn sí ọ,Wọ́n á sì kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ.”+ (Sélà)
5 Ẹ wá wo àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run.
Àwọn ohun tó ṣe fún àwọn ọmọ èèyàn jẹ́ àgbàyanu.+
6 Ó sọ òkun di ilẹ̀ gbígbẹ;+Wọ́n fi ẹsẹ̀ la odò kọjá.+
Níbẹ̀, à ń yọ̀ nítorí ohun tó ṣe.+
7 Ó ń fi agbára ńlá rẹ̀ ṣàkóso títí láé.+
Ojú rẹ̀ ń wo àwọn orílẹ̀-èdè.+
Kí àwọn alágídí má ṣe gbé ara wọn ga.+ (Sélà)
8 Ẹ yin Ọlọ́run wa,+Ẹ sì jẹ́ kí a gbọ́ ohùn ìyìn rẹ̀.
9 Ó dá ẹ̀mí wa sí;*+Kò jẹ́ kí a kọsẹ̀.*+
10 Ìwọ Ọlọ́run, o ti yẹ̀ wá wò;+O ti yọ́ wa mọ́ bí ẹni yọ́ fàdákà mọ́.
11 O fi àwọ̀n rẹ mú wa;O gbé ẹrù tó ń wọni lọ́rùn lé wa lórí.*
12 O jẹ́ kí ẹni kíkú máa gùn wá;*A la iná àti omi kọjá;Lẹ́yìn náà, o mú wa wá sí ibi tó tura.
13 Màá mú odindi ẹbọ sísun wá sí ilé rẹ;+Màá san àwọn ẹ̀jẹ́ mi fún ọ+
14 Èyí tí ètè mi ṣèlérí,+Tí ẹnu mi sì sọ nígbà tí mo wà nínú ìdààmú.
15 Màá fi àwọn ẹran àbọ́sanra rú ẹbọ sísun sí ọPẹ̀lú èéfín àwọn àgbò tí a fi rúbọ.
Màá fi àwọn akọ màlúù pẹ̀lú àwọn òbúkọ rúbọ. (Sélà)
16 Ẹ wá gbọ́, gbogbo ẹ̀yin tó bẹ̀rù Ọlọ́run,Màá sọ ohun tó ṣe fún mi.*+
17 Mo fi ẹnu mi ké pè é,Mo sì fi ahọ́n mi yìn ín lógo.
18 Ká ní mo ti gbèrò ohun búburú lọ́kàn mi,Jèhófà kò ní gbọ́ mi.+
19 Àmọ́, Ọlọ́run gbọ́;+Ó fetí sí àdúrà mi.+
20 Ìyìn ni fún Ọlọ́run, ẹni tí kò kọ àdúrà mi,Tí kò sì fawọ́ ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sẹ́yìn lórí mi.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “kọrin sí.”
^ Tàbí “Ó pa ọkàn wa mọ́ láàyè.”
^ Tàbí “ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́; ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.”
^ Ní Héb., “lé ìbàdí wa.”
^ Ní Héb., “gun orí wa.”
^ Tàbí “ọkàn mi.”