Sáàmù 86:1-17
Àdúrà Dáfídì.
86 Fetí sílẹ̀,* Jèhófà, kí o sì dá mi lóhùn,Nítorí pé ìyà ń jẹ mí, mo sì jẹ́ aláìní.+
2 Ṣọ́ ẹ̀mí* mi, torí pé adúróṣinṣin+ ni mí.
Gba ìránṣẹ́ rẹ tó gbẹ́kẹ̀ lé ọ là,Nítorí ìwọ ni Ọlọ́run mi.+
3 Ṣojú rere sí mi, Jèhófà,+Nítorí ìwọ ni mò ń ké pè láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.+
4 Mú kí ìránṣẹ́ rẹ* máa yọ̀,Nítorí ọ̀dọ̀ rẹ ni mo yíjú* sí, Jèhófà.
5 Nítorí pé ẹni rere ni ọ́,+ Jèhófà, o sì ṣe tán láti dárí jini;+Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí o ní sí gbogbo àwọn tó ń ké pè ọ́ pọ̀ gidigidi.+
6 Jèhófà, gbọ́ àdúrà mi;Sì fetí sí ẹ̀bẹ̀ mi fún ìrànlọ́wọ́.+
7 Mo ké pè ọ́ ní ọjọ́ wàhálà mi,+Torí mo mọ̀ pé wàá dá mi lóhùn.+
8 Jèhófà, kò sí èyí tó dà bí rẹ nínú àwọn ọlọ́run,+Kò sí iṣẹ́ kankan tó dà bíi tìrẹ.+
9 Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí o dáYóò wá forí balẹ̀ níwájú rẹ, Jèhófà,+Wọn yóò sì fi ògo fún orúkọ rẹ.+
10 Nítorí ẹni ńlá ni ọ́, o sì ń ṣe àwọn ohun àgbàyanu;+Ìwọ ni Ọlọ́run, ìwọ nìkan ṣoṣo.+
11 Jèhófà, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ.+
Èmi yóò máa rìn nínú òtítọ́ rẹ.+
Fún mi ní ọkàn tó pa pọ̀* kí n lè máa bẹ̀rù orúkọ rẹ.+
12 Mo fi gbogbo ọkàn mi yìn ọ́, Jèhófà Ọlọ́run mi,+Màá sì máa yin orúkọ rẹ lógo títí láé,
13 Nítorí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí o ní sí mi pọ̀,O sì ti gba ẹ̀mí* mi lọ́wọ́ Isà Òkú.*+
14 Ọlọ́run, àwọn agbéraga dìde sí mi;+Àwùjọ ìkà ẹ̀dá ń wá ọ̀nà láti gba ẹ̀mí* mi,Wọn ò sì kà ọ́ sí.*+
15 Àmọ́ ní tìrẹ, Jèhófà, o jẹ́ Ọlọ́run aláàánú, tó ń gba tẹni rò,*Tí kì í tètè bínú, tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ àti òdodo* rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi.+
16 Yíjú sí mi, kí o sì ṣojú rere sí mi.+
Fún ìránṣẹ́ rẹ ní agbára,+Kí o sì gba ọmọ ẹrúbìnrin rẹ là.
17 Fún mi ní àmì* oore rẹ,Kí àwọn tó kórìíra mi lè rí i, kí ojú sì tì wọ́n.
Nítorí ìwọ Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi àti olùtùnú mi.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “Bẹ̀rẹ̀ kí o sì fetí sí mi.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “ọkàn ìránṣẹ́ rẹ.”
^ Tàbí “gbé ọkàn mi.”
^ Tàbí “Mú ọkàn mi ṣọ̀kan.”
^ Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “Wọn ò fi tìrẹ pè.”
^ Tàbí “olóore ọ̀fẹ́.”
^ Tàbí “òtítọ́.”
^ Tàbí “ẹ̀rí.”