MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ṣé Wàá Fẹ́ Lọ Sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere?
Ṣé aṣáájú-ọ̀nà ni ẹ́, ṣé ọjọ́ orí ẹ̀ ṣì wà láàárín ọdún mẹ́tàlélógún [23] sí márùndínláàádọ́rin [65]? Ṣé o ní ìlera tó dáa, ṣé wàá sì lè lọ sìn níbikíbi tá a bá ti nílò àwọn oníwàásù sí i? Tí ìdáhùn rẹ bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni sáwọn ìbéèrè yìí, ṣé wàá fẹ́ lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere? Látìgbà tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tọkọtaya, arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọn ò tíì ṣègbéyàwó ló ti lọ síbẹ̀. Àmọ́ ní báyìí, a túbọ̀ nílò àwọn arákùnrin tí ò tíì ṣègbéyàwó nílé ẹ̀kọ́ yìí. Bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó wù ẹ́ láti túbọ̀ máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀, kó o sì máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ọmọ rẹ̀. (Sm 40:8; Mt 20:28; Heb 10:7) Lẹ́yìn náà, ronú nípa bó o ṣe lè dín ojúṣe rẹ tàbí iṣẹ́ tó ò ń ṣe kù kó o lè tóótun láti lọ sílé ẹ̀kọ́ yìí.
Àǹfààní iṣẹ́ ìsìn wo làwọn tó lọ sílé ẹ̀kọ́ yìí máa ń ní? Àwọn kan lára wọn ti lọ sìn níbi tí wọ́n ti ń sọ èdè tó yàtọ̀ sí tiwọn, àwọn míì sì tí kópa níbi àkànṣe ìwàásù láwọn ìlú térò pọ̀ sí. Àwọn kan ti di alábòójútó àyíká, adelé alábòójútó àyíká tàbí míṣọ́nnárì. Bó o ṣe ń ronú láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ṣe lò ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wòlíì Àìsáyà tó sọ pé: “Èmi nìyí! Rán mi!”—Ais 6:8.
WO FÍDÍÒ NÁÀ ÀWỌN MÍṢỌ́NNÁRÌ Ń ṢÍṢẸ KÁRA LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Báwo ni wọ́n ṣe ń yan àwọn míṣọ́nnárì?
-
Iṣẹ́ wo làwọn míṣọ́nnárì ń ṣe?
-
Ìbùkún wo làwọn míṣọ́nnárì máa ń rí?