December 7-13
LÉFÍTÍKÙ 10-11
Orin 32 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“A Gbọ́dọ̀ Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ju Ìdílé Wa Lọ”: (10 min.)
Le 10:1, 2—Jèhófà pa Nádábù àti Ábíhù torí pé wọ́n rú ẹbọ tí kò yẹ (it-1 1174)
Le 10:4, 5—Wọ́n gbé òkú wọn lọ sẹ́yìn ibùdó
Le 10:6, 7—Jèhófà pàṣẹ fún Áárónì àtàwọn ọmọ rẹ̀ yòókù pé wọn ò gbọ́dọ̀ ṣọ̀fọ̀ wọn (w11 7/15 31 ¶16)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (10 min.)
Le 10:8-11—Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú àwọn ẹsẹ yìí? (w14 11/15 17 ¶18)
Le 11:8—Ṣé àwa Kristẹni náà ò gbọ́dọ̀ jẹ àwọn ẹran tí Òfin Mósè ká léèwọ̀? (it-1 111 ¶5)
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Le 10:1-15 (th ẹ̀kọ́ 10)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Fídíò Nígbà Àkọ́kọ́: (4 min.) Ìjíròrò. Ẹ wo fídíò náà, lẹ́yìn náà béèrè pé: Báwo ni Tóyìn ṣe dọ́gbọ́n ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, lẹ́yìn tí onílé ṣe bíi pé ohun ò fẹ́ gbọ́? Báwo lo ṣe lè ṣàlàyé Sáàmù 1:1, 2 fún ẹnì kan?
Nígbà Àkọ́kọ́: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Pe onílé wá sípàdé, kẹ́ ẹ sì ṣe bí ẹni wo fídíò Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba? (àmọ́ ẹ má ṣe wò ó) (th ẹ̀kọ́ 20)
Àsọyé: (5 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) w11 2/15 12—Àkòrí: Kí ló mú kí ìbínú Mósè sí Élíásárì àti Ítámárì rọlẹ̀? (th ẹ̀kọ́ 12)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Ìfẹ́ Ló Ń Mú Ká Fara Mọ́ Ìbáwí Jèhófà”: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Jẹ́ Adúróṣinṣin Bó O Ṣe Ń Fi Ọkàn Kan Sin Jèhófà.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) rr orí 1 ¶15-19 àti àpótí 1B
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
Orin 15 àti Àdúrà