February 15 sí 21
NEHEMÁYÀ 9-11
Orin 84 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Àwọn Ìránṣẹ́ Jèhófà Máa Ń Kọ́wọ́ Ti Gbogbo Ètò Tó Jẹ Mọ́ Ìjọsìn Ọlọ́run”: (10 min.)
Ne 10:28-30
—Wọ́n fẹnu kò pé àwọn kò ní wọnú àdéhùn ìgbéyàwó pẹ̀lú “àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà” mọ́ (w98 10/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 11) Ne 10:32-39
—Wọ́n pinnu pé àwọn á ṣètìlẹyìn fún ìsìn tòótọ́ ní onírúurú ọ̀nà (w98 10/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 11 àti 12) Ne 11:1, 2
—Wọ́n fi tinútinú ṣètìlẹyìn fún àkànṣe ètò tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run (w06 2/1 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 6; w98 10/15 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 13)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Ne 9:19-21
—Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ kó dá wa lójú pé òun á pèsè ohun táwọn èèyàn rẹ̀ nílò? (w13 9/15 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 9 àti 10) Ne 9:6-38
—Àpẹẹrẹ rere wo làwọn ọmọ Léfì fi lélẹ̀ fún wa nípa bó ṣe yẹ ká máa gbàdúrà? (w13 10/15 ojú ìwé 22 sí 23 ìpínrọ̀ 6 àti 7) Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?
Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?
Bíbélì Kíkà: Ne 11:15-36 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Fi àpilẹ̀kọ náà, “Bí Ẹ Ṣe Lè Mú Kí Àlàáfíà Wà Nínú Ilé” tó wà nínú ìwé ìròyìn Jí! ti lọ́ọ́lọ́ọ́ ṣe àṣefihàn kan. Sọ ohun tí wàá bá ẹni náà jíròrò nígbà tó o bá pa dà wá.
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè ṣe ìpadàbẹ̀wò ẹni tó nífẹ̀ẹ́ sí àpilẹ̀kọ náà, “Bí Ẹ Ṣe Lè Mú Kí Àlàáfíà Wà Nínú Ilé” tó wà nínú ìwé ìròyìn Jí! ti lọ́ọ́lọ́ọ́ tí wọ́n fi lọ̀ ọ́. Sọ ohun tí wàá bá ẹni náà jíròrò nígbà tó o bá tún pa dà wá.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ṣe àṣefihàn bí a ṣe máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (bh ojú ìwé32 sí 33 ìpínrọ̀ 13 àti 14)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Orin 19
“Ìgbésí Ayé Tó Dára Jù Lọ”: (15 min.) Ìjíròrò. Kọ́kọ́ jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò yìí. Lẹ́yìn náà, jíròrò àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí. Ní ṣókí, fi ọ̀rọ̀ wá akéde kan lẹ́nu wò. Ó lè jẹ́ ẹni tó ti ṣègbéyàwó tàbí ẹni tí kò tíì ṣègbéyàwó. Akéde náà ti lo àǹfààní ọ̀pọ̀ ọdún tó fi wà láì lọ́kọ tàbí láì láya láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. (1Kọ 7:35) Àwọn ìbùkún wo ló ti rí gbà?
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: ia orí 9 ìpínrọ̀ 1 sí 13 (30 min.)
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 76 àti Àdúrà