February 15-21
NỌ́ŃBÀ 3-4
Orin 99 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Iṣẹ́ Ìsìn Àwọn Ọmọ Léfì”: (10 min.)
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí: (10 min.)
Nọ 4:15—Báwo la ṣe lè fi hàn pé a bẹ̀rù Ọlọ́run? (w06 8/1 23 ¶13)
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min.) Nọ 4:34-49 (th ẹ̀kọ́ 5)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min.) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Onílé sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ tí wọn ò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. (th ẹ̀kọ́ 2)
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min.) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Fún onílé ní ọ̀kan lára àwọn ìtẹ̀jáde tó wà nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́. (th ẹ̀kọ́ 15)
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (5 min.) fg ẹ̀kọ́ 12 ¶8 (th ẹ̀kọ́ 13)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn Ọdọọdún: (15 min.) Alàgbà ni kó sọ àsọyé yìí. Kọ́kọ́ ka lẹ́tà látọ̀dọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì nípa ìròyìn iṣẹ́ ìsìn ọdọọdún, lẹ́yìn náà fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn akéde kan tó o ti yàn, kí wọ́n sọ àwọn ìrírí tó ń gbéni ró tí wọ́n ní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ní ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) rr apá 2, orí 5 ¶1-8 àti fídíò ohun tó wà ní orí 5
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.)
Orin 63 àti Àdúrà