January 17-23
ÀWỌN ONÍDÀÁJỌ́ 20-21
Orin 47 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Máa Wádìí Lọ́dọ̀ Jèhófà”: (10 min.)
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì: (10 min.)
Ond 20:16—Báwo ni wọ́n ṣe máa ń fi kànnàkànnà jagun láyé àtijọ́? (w14 5/1 11 ¶4-6)
Àwọn ìṣúra wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min.) Ond 20:1-13 (th ẹ̀kọ́ 10)
TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min.) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Onílé sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ tí wọn ò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. (th ẹ̀kọ́ 5)
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min.) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Ṣe bíi pé ẹ wo fídíò Ta Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà? (àmọ́ ẹ má ṣe wò ó) (th ẹ̀kọ́ 17)
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (5 min.) lffi ẹ̀kọ́ 03 ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀ àti kókó 1-3 (th ẹ̀kọ́ 4)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Àwọn Ohun Tí Jèhófà Dá Jẹ́ Kó Túbọ̀ Dá Wa Lójú Pé Ọlọ́gbọ́n Ni”: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo àwọn fídíò náà, Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí? Báwo Ni Àwọn Èèrà Ṣe Ń Rìn Láìsí Sún Kẹẹrẹ Fà Kẹẹrẹ? àti Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí? Bí Oyin Ṣe Ń Fò Láìka Atẹ́gùn Tó Le Sí. Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n wo àwọn fídíò “Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?” tó wà lórí ìkànnì jw.org nígbà ìjọsìn ìdílé wọn.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) rr apá 5, orí 19 ¶1-6, fídíò ohun tó wà ní orí 19 àti àpótí 19A
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.)
Orin 87 àti Àdúrà