January 3-9
ÀWỌN ONÍDÀÁJỌ́ 15-16
Orin 124 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Jèhófà Kórìíra Àwọn Ọ̀dàlẹ̀”: (10 min.)
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì: (10 min.)
Ond 16:1-3—Kí ni àwọn ẹsẹ yìí túmọ̀ sí? (w05 3/15 27 ¶6)
Àwọn ìṣúra wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min.) Ond 16:18-31 (th ẹ̀kọ́ 10)
TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Fídíò Nígbà Àkọ́kọ́: (5 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Nígbà Àkọ́kọ́: Ọlọ́run Ń Bójú Tó Wa—Mt 10:29-31. Ẹ dá fídíò náà dúró láwọn ibi tẹ́ ẹ bá ti rí ìbéèrè, kẹ́ ẹ sì jíròrò ìbéèrè náà kẹ́ ẹ tó máa wò ó lọ.
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min.) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. (th ẹ̀kọ́ 3)
Nígbà Àkọ́kọ́: (5 min.) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Lẹ́yìn náà fún ẹni náà ni ìwé pẹlẹbẹ̀ Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! Kó o sì ṣe bíi pé ẹ wo fídíò Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? (àmọ́ ẹ má ṣe wò ó) (th ẹ̀kọ́ 9)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Bíbélì Ló Mú Ká Ṣì Wà Pa Pọ̀: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà. Lẹ́yìn náà, béèrè àwọn ìbéèrè yìí: Ìlànà Bíbélì wo ló ran àwọn tọkọtaya yìí lọ́wọ́ tí ìgbéyàwó wọn ò fi tú ká? Báwo ni fífọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Jèhófà ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́? Kí nìdí tó fi yẹ káwọn tọkọtaya sapá láti máa yanjú ìṣòro wọn? Àwọn wo ni tọkọtaya tó níṣòro lè lọ bá fún ìrànlọ́wọ́?—Jem 5:14, 15.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) rr orí 18 ¶9-15 àti àpótí 18A
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.)
Orin 149 àti Àdúrà