Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ | JẸ́ KÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀

Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́wọ́ Láti Máa Wá Sípàdé

Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́wọ́ Láti Máa Wá Sípàdé

Apá pàtàkì lára ìjọsìn mímọ́ ni àwọn ìpàdé wa jẹ́. (Sm 22:22) Gbogbo àwọn tó bá kóra jọ láti jọ́sìn Jèhófà máa láyọ̀, wọ́n á sì rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà. (Sm 65:4) Àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa túbọ̀ tẹ̀ síwájú tí wọ́n bá ń wá sípàdé déédéé.

Kí lo lè ṣe kí ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lè máa wá sípàdé? Máa pè é wá sípàdé látìgbàdégbà. Jẹ́ kó wo fídíò náà Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba? Jẹ́ kó mọ àwọn nǹkan tó máa gbádùn tó bá wá sípàdé. (lff ẹ̀kọ́ 10) O lè sọ ẹ̀kọ́ pàtàkì kan tó o kọ́ ní ìpàdé tẹ́ ẹ ṣe kọjá tàbí kẹ́ ẹ jọ ṣàyẹ̀wò ohun tẹ́ ẹ máa kọ́ nípàdé tó ń bọ̀. Fún akẹ́kọ̀ọ́ rẹ ní ìwé tẹ́ ẹ máa lò nípàdé. Yàtọ̀ síyẹn, o lè ràn án lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà míì. Bí àpẹẹrẹ, o lè ṣètò láti gbé e wá sípàdé. Tí akẹ́kọ̀ọ́ ẹ bá wá sípàdé fún ìgbà àkọ́kọ́, wàá rí i pé ìsapá ẹ ò já sásán.​—1Kọ 14:24, 25.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ RAN ÀWỌN TÓ Ò Ń KỌ́ LẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ LỌ́WỌ́ LÁTI MÁA WÁ SÍPÀDÉ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Àǹfààní wo ni Neeta lò láti pe Jade wá sípàdé?

  • Kí nìdí tí inú wa fi máa ń dùn tí akẹ́kọ̀ọ́ wa bá wá sípàdé?

  • “Ọlọ́run wà láàárín yín lóòótọ́”

    Kí ni Jade rí nígbà tó kọ́kọ́ wá sípàdé?