MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣàṣeyọrí
Ó máa ń wu àwọn òbí tó níbẹ̀rù Ọlọ́run láti rí bí àwọn ọmọ wọn ṣe ń fi tọkàntọkàn sin Jèhófà. Àwọn òbí lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti sin Jèhófà tí wọ́n bá gbin ẹ̀kọ́ Bíbélì sínú ọkàn wọn láti kékeré. (Di 6:7; Owe 22:6) Ǹjẹ́ ó gba pé kí àwọn òbí yááfì àwọn nǹkan kan? Bẹ́ẹ̀ ni! Àmọ́ èrè tí wọ́n máa rí tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.—3Jo 4. Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ làwọn òbí lè kọ́ lára Jósẹ́fù àti Màríà. Ó ‘jẹ́ àṣà wọn láti máa lọ sí Jerúsálẹ́mù láti ọdún dé ọdún fún àjọyọ̀ ìrékọjá,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó gba ọ̀pọ̀ ìsapá àti ìnáwó. (Lk 2:41) Ó ṣe kedere pé ipò kìíní ni Jósẹ́fù àti Màríà fi àjọṣe ìdílé wọn pẹ̀lú Jèhófà sí. Bákan náà, ó yẹ kí àwọn òbí lóde òní máa lo gbogbo àǹfààní tí wọ́n bá ní láti darí àwọn ọmọ wọn sí ojú ọ̀nà tó yẹ nípa ọ̀rọ̀ ẹnu àti àpẹẹrẹ wọn.—Sm 127:3-5.
WO FÍDÍÒ NÁÀ WỌ́N GBÁ ÀǸFÀÀNÍ TÓ ṢÍ SÍLẸ̀ MÚ, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Báwo ni Jon àti Sharon Schiller ṣe fi Ìjọba Ọlọ́run sí ipò kìíní bí wọ́n ṣe ń tọ́ àwọn ọmọ wọn?
-
Kí nìdí tó fi yẹ kí àwọn òbí bá àwọn ọmọ wọn wí ní ìbámu pẹ̀lú ipò àti ohun tí ọmọ kọ̀ọ̀kan nílò?
-
Báwo làwọn òbí ṣe lè múra ọkàn àwọn ọmọ wọn sílẹ̀ láti kojú ìdánwò ìgbàgbọ́?
-
Èwo lára àwọn ohun tí ètò Jèhófà ṣe lẹ ti lò láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ kí wọ́n lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà?