MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ṣọ́ra fún Àwọn Ewu Tó Wà Nínú Ìkànnì Àjọlò
ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ: Bí ọ̀pọ̀ ohun èlò, ìkànnì àjọlò wúlò lápá kan, ó sì léwu lápá kan. Àwọn Kristẹni kan ti pinnu pé àwọn ò ní lo ìkànnì àjọlò rárá. Àwọn Kristẹni míì sì ń lò ó láti máa bá àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ sọ̀rọ̀. Àmọ́, Èṣù fẹ́ ká máa lo ìkànnì àjọlò ní ìlòkulò, ìyẹn sì lè ba orúkọ rere wa àti àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Bíi ti Jésù, àwọn ìlànà Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti rí àwọn ewu tó wà níbẹ̀, ká sì yẹra fún wọn.—Lk 4:4, 8, 12.
ÀWỌN EWU TÓ YẸ KÁ ṢỌ́RA FÚN:
-
Ṣíṣe àṣejù nídìí ìkànnì àjọlò. Tá a bá ń lo ọ̀pọ̀ wákàtí lórí ìkànnì àjọlò, èyí ò ní jẹ́ ká fi bẹ́ẹ̀ ráyè fún àwọn nǹkan tẹ̀mí.
Àwọn ìlànà Bíbélì: Ef 5:15, 16; Flp 1:10
-
Wíwo àwọn nǹkan tí kò bójú mu. Téèyàn bá ń wo àwòrán àwọn tó ṣí ara sílẹ̀, tó bá yá, onítọ̀hún lè bẹ̀rẹ̀ sí í wo àwọn ohun tó ń mú ọkàn ẹni fà sí ìṣekúṣe tàbí kó tiẹ̀ ṣe ìṣekúṣe. Tá a bá ń ka ìsọfúnni táwọn apẹ̀yìndà gbé sórí ìkànnì àjọlò, ó lè ba ìgbàgbọ́ wa jẹ́.
-
Gbígbé ọ̀rọ̀ tàbí àwòrán tí kò dáa sórí ìkànnì. Torí pé ọkàn máa ń tanni jẹ, ó lè máa ṣe wá bíi pé ká gbé àwọn ọ̀rọ̀ tàbí àwòrán tí kò dáa sórí ìkànnì àjọlò. Àmọ́, èyí lè ba àwọn ẹlòmíì lórúkọ jẹ́ tàbí kó jin ìgbàgbọ́ wọn lẹ́sẹ̀.
WO FÍDÍÒ NÁÀ MÁA FỌGBỌ́N LO ÌKÀNNÌ ÀJỌLÒ, KÓ O SÌ RONÚ LÓRÍ BÍ WÀÁ ṢE YẸRA FÚN ÀWỌN EWU YÌÍ: