March 21 sí 27
JÓÒBÙ 6-10
Orin 68 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Jóòbù Ọkùnrin Olóòótọ́ Sọ Ẹ̀dùn Ọkàn Rẹ̀”: (10 min.)
Job 6:1-3, 9, 10, 26; 7:11, 16
—Tí ìdààmú bá bá àwọn èèyàn, kì í ṣe ohun tí wọ́n ní lọ́kàn gan-an ni wọ́n sábà máa ń sọ (w13 8/15 19 ¶7; w13 5/15 22 ¶13) Job 9:20-22
—Àwọn ìṣòro tí Jóòbù ní mú kó ní èrò tí kò tọ́, ó rò pé ojú kan náà ni Ọlọ́run fi ń wo ẹni burúkú àti ẹni rere (w15 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 2) Job 10:12
—Kódà nígbà tí Jóòbù kojú àdánwò tó lè koko, ó sọ àwọn ohun tó dára nípa Jèhófà (w09 4/15 7 ¶18; w09 4/15 10 ¶13)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Job 6:14
—Báwo ni Jóòbù ṣe fi hàn pé ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ṣe pàtàkì? (w10 11/15 ojú ìwé 32 ìpínrọ̀ 20) Job 7:9, 10; 10:21
—Tí Jóòbù bá gbà pé àjíǹde wà, kí nìdí tó fi sọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹsẹ yìí? (w06 3/15 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 11) Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?
Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?
Bíbélì Kíkà: Job 9:1-21 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: wp16.2 ojú ìwé 16
—Sọ bí a ṣe ń fi ọrẹ ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ wa. (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ìpadàbẹ̀wò: wp16.2 ojú ìwé 16
—Sọ ohun tí wàá bá ẹni náà jíròrò nígbà tó o bá tún pa dà wá. (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: fg ẹ̀kọ́ 2 ìpínrọ̀ 6 sí 8 (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Orin 114
Máa Lo Ìjìnlẹ̀ Òye Tó O Bá Ń Tu Àwọn Èèyàn Nínú: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò tí àwọn alàgbà wò láìpẹ́ yìí ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Lẹ́yìn náà, ní kí àwọn ará sọ bí àwọn arákùnrin méjì tá a rí nínú fídíò náà ṣe fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún wa nípa bí a ṣe lè tu ẹni tó sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún wa nínú lẹ́yìn tí èèyàn rẹ̀ kan kú.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: ia orí 11 ìpínrọ̀ 12 sí 20, àtúnyẹ̀wò tó wà lójú ìwé 98 (30 min.)
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 27 àti Àdúrà