Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́SÍTÉRÌ 6-10

Ẹ́sítérì Fi Àìmọtara-Ẹni-Nìkan Gbèjà Jèhófà Àtàwọn Èèyàn Rẹ̀

Ẹ́sítérì Fi Àìmọtara-Ẹni-Nìkan Gbèjà Jèhófà Àtàwọn Èèyàn Rẹ̀

Ẹ́sítérì lo ìgboyà, ó gbèjà Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀ torí pé kò ní ìmọtara-ẹni-nìkan

8:3-5, 9

  • Kò séwu fún Ẹ́sítérì àti Módékáì. Àmọ́ òfin tí Hámánì ṣe pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn Júù run ti dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn ní gbogbo ilẹ̀ ọba Páṣíà

  • Ẹ́sítérì tún fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu, ó lọ bá ọba láì jẹ́ pé ọba ló pè é. Ó sunkún níwájú ọba torí àwọn èèyàn rẹ̀, ó sì bẹ ọba pé kó yí òfin burúkú tí Hámánì ṣe pa dà

  • Òfin tí wọ́n bá ṣe lórúkọ ọba Páṣíà kò ṣeé yí pa dà. Ọba wá fún Ẹ́sítérì àti Módékáì láṣẹ pé kí wọ́n ṣe òfin tuntun míì

Jèhófà mú kí àwọn èèyàn rẹ̀ ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn pátápátá

8:10-14, 17

  • Wọ́n ṣe ìkéde kejì, èyí tó fún àwọn Júù láṣẹ láti gbèjà ara wọn

  • Àwọn tó ń gun ẹṣin sáré tete lọ sí gbogbo ilẹ̀ ọba Páṣíà, àwọn Júù sì gbára dì fún ogun

  • Ọ̀pọ̀ àwọn ará Páṣíà tó rí i pé Ọlọ́run ti ṣojú rere sí àwọn èèyàn rẹ̀ wá di aláwọ̀ṣe Júù