Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
ILÉ ÌṢỌ́
Béèrè ìbéèrè: Kí lẹ rò pé ó jẹ́ ẹ̀bùn tó dára jù lọ tí Ọlọ́run tíì fún wa?
Ka Bíbélì: Jo 3:16
Fi ìwé lọni: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí sọ ìdí tí Ọlọ́run fi rán Jésù wá sáyé àti bá a ṣe lè fi hàn pé a mọ rírì ẹ̀bùn náà.
KÍ NI ÌJỌBA ỌLỌ́RUN?
ÌWÉ ÌKÉSÍNI SÍBI ÌRÀNTÍ IKÚ KRISTI
Fi ìwé lọni: À ń pe àwọn èèyàn wá síbi ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan. [Fún un ní ìwé ìkésíni.] Ní April 11, ọ̀pọ̀ èèyàn jákèjádò ayé máa pé jọ láti ṣe ìrántí ikú Jésù, wọ́n á sì gbọ́ àsọyé kan tó dá lórí Bíbélì nípa bí ikú Jésù ṣe lè ṣe wá láǹfààní, ọ̀fẹ́ sì ni. Wàá rí àkókò àti ibi tá a ti máa ṣe ìpàdé náà nínú ìwé yìí. A ó máa retí yín o.
KỌ Ọ̀NÀ ÌGBỌ́RỌ̀KALẸ̀ RẸ
Wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a fi ṣe àpẹẹrẹ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ.