Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Pa Jèhófà Tì
Jèhófà gbé iṣẹ́ ńlá kan fún Jeremáyà tó máa ṣàpẹẹrẹ ìpinnu tí Jèhófà ṣe láti pa Júdà àti Jerúsálẹ́mù run, torí wọ́n jẹ́ alágídí àti onígbèéraga.
Jeremáyà wá ìgbànú aṣọ ọ̀gbọ
-
Ìgbànú tí Jeremáyà so mọ́ ìgbáròkó rẹ̀ ṣàpẹẹrẹ àjọṣe tímọ́tímọ́ tíì bá wà láàárín Jèhófà àti orílẹ̀-èdè náà
Jeremáyà mú ìgbànú náà lọ sí Odò Yúfírétì
-
Ó fi í pamọ́ sínú pàlàpálá àpáta gàǹgà, ó sì pa dà sí Jerúsálẹ́mù
Jeremáyà pa dà sí Odò Yúfírétì láti mú ìgbànú náà
-
Ìgbànú náà ti bà jẹ́
Jèhófà wá ṣàlàyé fún Jeremáyà ohun tí èyí túmọ̀ sí lẹ́yìn tó ti ṣe ohun tó rán-an
-
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún Jeremáyà dá bí ohun tí kò tó nǹkan, síbẹ̀ ìgbọ̀ràn rẹ̀ jẹ́ ọkàn lára ọ̀nà tí Jèhófà gbà mú kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ wọ àwọn èèyàn náà lọ́kàn