March 12-18
MÁTÍÙ 22-23
Orin 30 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Máa Tẹ̀ Lé Àwọn Àṣẹ Méjì Tó Tóbi Jù Lọ”: (10 min.)
Mt 22:36-38—Báwo ni àwọn ẹsẹ yìí ṣe ṣàlàyé ohun tó ní nínú láti tẹ̀ lé àṣẹ títóbi jù lọ àti èkíní nínú Òfin? (“ọkàn-àyà,” “ọkàn,” “èrò inú” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 22:37, nwtsty)
Mt 22:39—Kí ni àṣẹ títóbi jù lọ kejì nínú Òfin? (“Èkejì,” “aládùúgbò” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 22:39, nwtsty)
Mt 22:40—Orí ìfẹ́ ni gbogbo Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù dá lé (“Òfin . . . àwọn Wòlíì,” “so kọ́” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 22:40, nwtsty)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Mt 22:21—Kí ni “àwọn ohun ti Késárì,” kí sì ni “àwọn ohun ti Ọlọ́run”? (“àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì,” “àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 22:21, nwtsty)
Mt 23:24—Kí ni ọ̀rọ̀ Jésù yìí túmọ̀ sí? (“tí ń sẹ́ kòkòrò kantíkantí ṣùgbọ́n tí ń gbé ràkúnmí mì káló” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 23:24, nwtsty)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Mt 22:1-22
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Wo Ohun Tá A Lè Bá Àwọn Èèyàn Sọ.
Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́—Fídíò: (5 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) bh 186-187 ¶7-8—Kí olùkọ́ gba akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ níyànjú pé kó pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ wá sí Ìrántí Ikú Kristi.
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Bí A Ṣe Lè Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run Àtàwọn Aládùúgbò Wa”: (15 min.) Ìjíròrò. Ká lè rí àǹfààní tó wà nínú kéèyàn máa fọkàn yàwòrán àwọn ìtàn inú Bíbélì, jẹ́ kí àwọn ará gbọ́ díẹ̀ nínú Bíbélì kíkà bí ẹni ṣe eré ìtàn tá a pe àkọlé rẹ̀ ní Jèhófà Nìkan Ṣoṣo Ni Ọlọ́run Tòótọ́, kí wọ́n máa fojú bá ìtàn tó wà ní 1 Àwọn Ọba 18:17-46 lọ nínú Bíbélì wọn.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lv orí 5 ¶1-6 àti àpótí ojú ìwé 52 àti 55
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 52 àti Àdúrà