“Ẹnì Yòówù Tí Ó Bá Fẹ́ Di Ẹni Ńlá Láàárín Yín Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Òjíṣẹ́ Yín”
Àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí onígbèéraga máa ń pe àfiyèsí síra wọn, wọ́n sì máa ń fẹ́ wà ní ipò ọlá. (Mt 23:5-7) Jésù yàtọ̀ sí wọn. “Ọmọ ènìyàn ti wá, kì í ṣe kí a lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, bí kò ṣe kí ó lè ṣe ìránṣẹ́.” (Mt 20:28) Ṣé apá táwọn èèyàn á ti mọ̀ wá, tí wọ́n á sì ti máa yìn wá la máa ń fẹ́ láti ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run? Tá a bá fẹ́ jẹ́ ẹni ńlá lójú Jèhófà, àfi ká máa sapá láti dà bíi Jésù, ká máa ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti ran àwọn míì lọ́wọ́. Àwọn èèyàn lè má kíyè sí ohun tá a ṣe, àmọ́ Jèhófà rí i. (Mt 6:1-4) Òjíṣẹ́ tó nírẹ̀lẹ̀ á máa . . .
-
kópa nínú iṣẹ́ ìmọ́tótó àti àtúnṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba
-
lo ìdánúṣe láti ran àwọn àgbàlagbà àtàwọn míì lọ́wọ́
-
fowó ṣe ìtìlẹ́yìn fún àwọn iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run