March 14-20
1 SÁMÚẸ́LÌ 14-15
Orin 89 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ìgbọràn Sàn Ju Ẹbọ Lọ”: (10 min.)
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì: (10 min.)
1Sa 15:24—Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú bí Sọ́ọ̀lù ṣe fi ojú àánú hàn lọ́nà tí kò tọ́? (it-1 493)
Àwọn ìṣúra wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min.) 1Sa 15:1-16 (th ẹ̀kọ́ 2)
TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Fídíò Ìpadàbẹ̀wò: (5 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Ìpadàbẹ̀wò: Jésù—Mt 20:28. Ẹ dá fídíò náà dúró láwọn ibi tẹ́ ẹ bá ti rí ìbéèrè, kẹ́ ẹ sì jíròrò ìbéèrè náà kẹ́ ẹ tó máa wò ó lọ.
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min.) Ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ ni kó o fi bẹ̀rẹ̀. Fún onílé ní ọ̀kan lára àwọn ìtẹ̀jáde tó wà nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́. (th ẹ̀kọ́ 3)
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min.) Ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ ni kó o fi bẹ̀rẹ̀. Fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ ẹni náà, kó o sì ṣe bíi pé ẹ wo fídíò Báwo La Ṣe Máa Ń Ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? (àmọ́ ẹ má ṣe wò ó) (th ẹ̀kọ́ 11)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
A Máa Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Pe Àwọn Èèyàn sí Ìrántí Ikú Kristi ní Saturday, March 19: (10 min.) Ìjíròrò. Ṣàlàyé ohun tó wà nínú ìwé ìkésíni náà. Sọ ètò tí ìjọ ṣe nípa àkànṣe àsọyé àti Ìrántí Ikú Kristi, kẹ́ ẹ sì sọ ètò tí ìjọ ti ṣe láti kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a máa lò.
Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà—Máa Ṣègbọràn sí Jèhófà: (5 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) rr orí 22 ¶1-9 àti fídíò ohun tó wà ní orí 22
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.)
Orin 10 àti Àdúrà