Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Jèhófà Ń Gba Àwọn Tí Àárẹ̀ Bá Ẹ̀mí Wọn Là

Jèhófà Ń Gba Àwọn Tí Àárẹ̀ Bá Ẹ̀mí Wọn Là

Gbogbo wa la máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ti pé inú ẹnì kan ò dùn kò túmọ̀ sí pé kò nígbàgbọ́ nínú Jèhófà. Ó ṣe tán, àwọn ìgbà kan wà tí inú Jèhófà náà ò dùn. (Jẹ 6:​5, 6) Àmọ́ tó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni inú wa kì í dùn ńkọ́?

Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Jèhófà fẹ́ kí inú wa máa dùn nígbà gbogbo. Ó mọ ìgbà tí inú wa ń dùn àtìgbà tínú wa ò dùn. Ó mọ ohun tó ń kó wa lọ́kàn sókè, àti bí nǹkan ṣe rí lára wa. (Sm 7:9b) Ju gbogbo ẹ̀ lọ, Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó sì ṣe tán láti ràn wá lọ́wọ́ tí inú wa ò bá dùn tàbí tá a bá rẹ̀wẹ̀sì.—Sm 34:18.

Má ṣe jẹ́ kí èrò òdì gbà ẹ́ lọ́kàn. Tá a bá jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì gbà wá lọ́kàn, kì í ṣe pé a ò ní láyọ̀ nìkan, á tún ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Torí náà, a gbọ́dọ̀ dáàbò bo ọkàn wa, lédè míì, ká má gba èrò òdì láyè.—Owe 4:23.

Ẹ WO FÍDÍÒ ỌKÀN ÀWỌN ARÁ WA BALẸ̀ LÁÌKA Ẹ̀DÙN ỌKÀN SÍ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Àwọn nǹkan wo ni Nikki ṣe kí ẹ̀dùn ọkàn má bàa gbà á lọ́kàn?

  • Kí ló mú kí Nikki gbà pé á dáa kóun lọ rí dókítà?—Mt 9:12

  • Àwọn nǹkan wo ni Nikki ṣe tó fi hàn pé ó gbára lé Jèhófà?