September 23-29
SÁÀMÙ 88-89
Orin 22 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Ìṣàkóso Jèhófà Ló Dáa Jù
(10 min.)
Ìṣàkóso Jèhófà máa mú ìdájọ́ òdodo wá (Sm 89:14; w17.06 28 ¶5)
Ìṣàkóso Jèhófà máa mú káwọn èèyàn láyọ̀ (Sm 89:15, 16; w17.06 29 ¶10-11)
Ìṣàkóso Jèhófà máa wà títí láé (Sm 89: 34-37; w14 10/15 10 ¶14)
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
-
Sm 89:37 —Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín bí òṣùpá ṣe jẹ́ adúróṣinṣin àti bí àwa èèyàn ṣe lè jẹ́ adúróṣinṣin? (cl 281 ¶4-5)
-
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Sm 89:1-24 (th ẹ̀kọ́ 11)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. Fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ ẹni tí kì í ṣe Kristẹni. (lmd ẹ̀kọ́ 5 kókó 5)
5. Pa Dà Lọ
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Fi bá a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn án. (th ẹ̀kọ́ 9)
6. Ṣàlàyé Ohun Tó O Gbà Gbọ́
(5 min.) Àsọyé. ijwbq 181—Àkòrí: Kí Ni Bíbélì Dá Lé? (th ẹ̀kọ́ 2)
Orin 94
7. Àwọn Ìlànà Jèhófà Ló Dáa Jù
(10 min.) Ìjíròrò.
Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń wo ìlànà Bíbélì nípa ìbálòpọ̀ àti ìgbéyàwó bí ohun tó ti le koko jù tí kò sì bágbà mu mọ́. Ṣé ó dá ẹ lójú pé tó o bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà, ó máa ṣe ẹ́ láǹfààní?—Ais 48:17, 18; Ro 12:2.
-
Kí nìdí tí kò fi yẹ ká fara mọ́ àwọn ìwà tí ayé ń gbé lárugẹ? (Jer 10:23; 17:9; 2Kọ 11:13-15; Ef 4:18, 19)
-
Kí nìdí tó fi yẹ ká fara mọ́ àwọn ìlànà tí Jèhófà fún wa? (Jo 3:16; Ro 11:33; Tit 1:2)
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn tí kò tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run “kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run.” (1Kọ 6:9, 10) Àmọ́, ṣé torí àtijogún Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló fi yẹ ká máa tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run?
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Jẹ́ Kí Ohun Tó O Gbà Gbọ́ Dá Ẹ Lójú—Ṣé Ìlànà Ọlọ́run Ni Màá Tẹ̀ Lé àbí Èrò Ara Mi. Lẹ́yìn náà béèrè pé:
-
Báwo làwọn ìlànà Jèhófà ṣe ń dáàbò bò wá?
8. Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ
(5 min.)
9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 15 ¶15-20