Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kí N Sún Mọ́ Àwọn Òbí Mi Àgbà?
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kí N Sún Mọ́ Àwọn Òbí Mi Àgbà?
“Nígbà témi àti mọ́mì mi ò gbọ́ra wa yé, Màmá àgbà ló bá wa yanjú ẹ̀.”—Damaris.
DÓKÍTÀ Arthur Kornhaber sọ nínú ìwé rẹ̀ Grandparent Power! pé: “Látọjọ́ táláyé ti dáyé la ti mọ̀ pé a kò lè kóyán àwọn òbí àgbà kéré tọ́ràn bá kan ti pé ká mú ìdílé wà níṣọ̀kan ká sì tún kọ́ àwọn ògo wẹẹrẹ láwọn àṣà ìdílé.” Ó fi kún un pé: “Bí wọ́n ṣe jẹ́ olùkọ́ àti alátìlẹyìn àwọn òbí, asọ̀tàn ìdílé àti olùṣìkẹ́, olùgbaninímọ̀ràn àti adánilárayá, ipa tí wọ́n ń kó ní ti ìrònú òun ìhùwà, àjọṣe láàárín àwùjọ, àti ní ti ọ̀ràn tẹ̀mí ṣe pàtàkì gan an ni. Ó yà mí lẹ́nu bí àwùjọ wa ṣe wá bẹ̀rẹ̀ sí sọ ohun pàtàkì táwọn òbí àgbà ń ṣe yìí sígbó.”
Lọ́jọ́un àná, àwọn òbí àgbà ni ìpìlẹ̀ ìgbésí ayé ìdílé, pàápàá jù lọ láàárín àwọn olùjọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run. Bíbélì pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n bọ̀wọ̀ fáwọn àgbàlagbà kí wọ́n sì buyì fún wọn. (Léfítíkù 19:32) Wọ́n mọ̀ pé àwọn òbí àgbà kanlẹ̀ yẹ lẹ́ni táa ń bọlá fún.—1 Tímótì 5:4.
Ó bani nínú jẹ́ pé ìgbà ti yí padà. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn mẹ́ńbà ìdílé máa ń gbé níbi tó jìn síra, èyí kì í jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èwe rí àwọn òbí wọn àgbà. Ìwà náà ti yí padà. Níbi púpọ̀ lágbàáyé, wọn kì í fọ̀wọ̀ wọ̀ àwọn àgbàlagbà mọ́—títí kan àwọn ìbátan pàápàá. (2 Tímótì 3:1-3) Ẹ̀mí kóńkó jabele táwọn èwe máa ń ní sáwọn àgbàlagbà tẹ́lẹ̀ tún ti wá légbá kan. Ọ̀pọ̀ àwọn èwe ni wọ́n ka àwọn òbí wọn àgbà sí arúgbó lásánlàsàn tí ò mọ nǹkan tó bóde mu. Wọn ò ní i lọ́kàn pé àwọn àgbàlagbà wọ̀nyí lè lóye àwọn pákáǹleke àti ìṣòro táwọn èwe dojú kọ lónìí.
Bó bá jẹ́ èrò rẹ nìyẹn, múra tán láti tún ọ̀ràn náà gbé yẹ̀ wò! Nítorí pé àǹfààní ńláǹlà ń bẹ níbẹ̀ bóo bá sún mọ́ àwọn òbí rẹ àgbà—pàápàá bí wọ́n bá jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run. Bí o ò bá tíì sún mọ́ wọn, àǹfààní ńláǹlà lo ń sọnù yẹn o. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀?
Orísun Ọgbọ́n Òun Ìmọ̀ràn
Ọ̀pọ̀ àwọn èwe ló ti wá rí i pé àwọn òbí àgbà lè dáàbò boni láàárín àwọn ọdún onípákáǹleke ti ìgbà èwe. Ìwé ìròyìn Seventeen sọ pé: “Àwọn òbí àgbà sábà máa ń ṣèrànwọ́ láti kojú àwọn ìṣòro ju àwọn ọ̀gbà rẹ tẹ́ẹ jọ ń kojú àníyàn kan náà torí pé wọ́n ti ní ìrírí fún ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n ti wà láyé. Ìyípadà àkọ́kọ́ Òwe 16:31.
nínú ìgbésí ayé ni ìwọ àtàwọn ojúgbà rẹ ń bá yí; àwọn òbí rẹ àgbà sì ti la àìmọye irú ìyípadà bẹ́ẹ̀ já. Ọgbọ́n kún inú wọn bẹ́ẹ̀ sì ni ìmọ̀ ń bẹ lágbárí wọn.” Ìmọ̀ràn yìí wulẹ̀ jẹ́ àtúnsọ ohun tí Bíbélì sọ ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn ni, pé: “Orí ewú jẹ́ adé ẹwà nígbà tí a bá rí i ní ọ̀nà òdodo.”—Lóòótọ́, ipò àwọn nǹkan nígbà táwọn òbí rẹ àgbà wà léwe lè yàtọ̀ pátápátá sí bó ṣe rí lásìkò tìrẹ. Àmọ́ jẹ́ kó dá ọ lójú pé nígbà kan rí, àwọn náà ti ní irú ìmọ̀lára tóo ń bá fínra ní lọ́ọ́lọ́ọ́. Nígbà tó jẹ́ pé ìwọ kò tíì nírìírí tó pọ̀ tó láti kójú irú ìmọ̀lára wọ̀nyẹn, àwọn òbí rẹ àgbà ti kọ́ béèyàn ṣe lè kojú wọn nínú ìgbésí ayé. (Òwe 1:4) Ọkùnrin olódodo náà Jóòbù béèrè pé: “Ọgbọ́n kò ha wà láàárín àwọn àgbàlagbà àti òye nínú gígùn àwọn ọjọ́?” (Jóòbù 12:12) Bẹ́ẹ̀ ni, ìdí nìyẹn táwọn òbí àgbà fi wúlò gidi gan an nígbà tí èwe kan bá nílò ìmọ̀ràn tó ṣe déédéé, ìṣírí, tàbí ìtìlẹ́yìn.
Fún àpẹẹrẹ, ìyá tó bí ìyá ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Damaris, ń gbé ilé kan náà pẹ̀lú Damaris àti ìyá rẹ̀. Damaris sọ pé: “Nígbà témi àti mọ́mì mi ò gbọ́ra wa yé, Màmá àgbà ló bá wa yanjú ẹ̀. Ó máa ń fi béèyàn ṣe ń fojú tó yàtọ̀ wo ọ̀ràn hàn mí.”
Bọ́ràn Alexandria náà ṣe rí nìyẹn nígbà tí ìdílé rẹ̀ ṣí lọ, tó sì di pé ó ní láti kúrò nílé ẹ̀kọ́ tó ń lọ tẹ́lẹ̀. Alexandria sọ pé: “Olùkọ́ mi tuntun le gan an ó sì sábà máa ń gbaná jẹ. Ó ṣòro púpọ̀ fún Alexandria kí ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀ tuntun tó mọ́ ọn lára. Àmọ́ ṣá, ìyá rẹ̀ àgbà ṣèrànwọ́ fún un ó sì tì í lẹ́yìn. Ó ran Alexandria lọ́wọ́ tí ilé ẹ̀kọ́ fi wá gbádùn mọ́ ọn nípa fífún un níṣìírí láti fọkàn balẹ̀ pé nǹkan á ṣì dára. Alexandria sọ pé: “Mo ti wá fẹ́ràn ilé ẹ̀kọ́ àti tíṣà mi báyìí.”
Ọ̀dọ́mọkùnrin kan ní Brazil tó ń jẹ́ Rafael rántí ìrànlọ́wọ́ táwọn òbí rẹ̀ àgbà ṣe fún un nígbà tó lọ kàwé sí i lẹ́yìn tó jáde ilé ẹ̀kọ́ gíga, ó sọ pé: “Wọ́n fún mi nímọ̀ràn tó pọ̀ nípa ẹgbẹ́ kíkó àti bí mo ṣe lè yẹra fún ìṣòro oògùn líle.” Rafael ń sìn ní lọ́ọ́lọ́ọ́ gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún.
Ẹnì kan tí ń jẹ́ Eda LeShan, tó jẹ́ ìyá àgbà, sọ ìrírí òun fúnra rẹ̀ nínú ìwé rẹ̀, Grandparenting in a Changing World. Ó kọ ọ́ pé: “Ọmọ-ọmọ mi pè mí lọ́jọ́ kan ó sì sọ pé, ‘Màmá àgbà, ẹ ràn mí lọ́wọ́ nípa ohun tí mo lè ṣe sí ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe.’ Àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ kan ti ń sọ fún un pé kó máa bá àwọn ọmọkùnrin ròde, lára wọn sì ti ń pè é lórí tẹlifóònù.” Nítorí pé ọmọ-ọmọ rẹ̀ béèrè fún ìrànlọ́wọ́, ó ṣeé ṣe fún ìyá àgbà náà láti pèsè ìmọ̀ràn tó nílò fún un láti tì í lẹ́yìn. Ìwọ náà lè rí i pé fífọ̀rọ̀ jomitoro ọ̀rọ̀ pẹ̀lú òbí àgbà kan tóo nífẹ̀ẹ́ lè jẹ́ orísun ìtìlẹ́yìn ìwà rere ní ti gidi.
Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn òbí àgbà máa ń ṣèrànlọ́wọ́ dáadáa lákòókò tí ìdílé bá wà nínú ìṣòro, irú bí àìsàn tàbí ikú. Lẹ́yìn tí àìsàn líle kan pa bàbá ọmọdébìnrin kan tó ń jẹ́ Lacey, ìyá bàbá rẹ̀ ló ràn án lọ́wọ́ láti fara dà á. Lacey sọ pé: “A ti wá sún mọ́ra gan an kódà ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.”
Ìdè Ìfẹ́ Pàtàkì
Ó ṣeé ṣe káwọn pákáǹleke tó máa ń wáyé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láàárín àwọn èwe àtàwọn òbí wọn máà sí láàárín ìwọ àti òbí rẹ àgbà. Èé ṣe? Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn òbí àgbà máa ń gbádùn ìdè pàtàkì pẹ̀lú àwọn ọmọ-ọmọ wọn lọ́pọ̀ ìgbà. Bíbélì sọ pé: “Àwọn arúgbó a máa fi àwọn ọmọ-ọmọ wọn yangàn.”—Òwe 17:6, Today’s English Version.
Àmọ́ tún rántí pé, àwọn òbí rẹ gan an ni wọ́n ni ojúṣe wíwúwo náà láti tọ́ ọ dàgbà “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà” kì í ṣe àwọn òbí rẹ àgbà. (Éfésù 6:4) Àwọn òbí rẹ àgbà lè má rinkinkin nípa rẹ bíi tàwọn òbí rẹ, ó ṣe tán díẹ̀ ni ipa tiwọn nínú títọ́ ọ. Síwájú sí i, ẹrù iṣẹ́ àti wàhálà ojoojúmọ́ ti bíbójútó ìdílé kì í sábàá pá àwọn òbí àgbà lórí. Nítorí pé àwọn wàhálà yìí kì í fi bẹ́ẹ̀ sí lọ́rùn wọn, ó lè rọrùn fún wọn láti tètè ráyè gbọ́ tìẹ tàbí fún ọ láfiyèsí. Tom ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún rántí báwọn òbí rẹ̀ àgbà ṣe fún un láfiyèsí. Wọ́n máa ń fi “ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí i nítorí pé èsì ìdánwò rẹ̀ dára”; wọ́n tiẹ̀ tún sanwó ẹ̀kọ́ rẹ̀ tó kọ́ nípa bí wọ́n ṣe ń tẹ dùrù.
Òtítọ́ ni pé, kì í ṣe gbogbo àwọn òbí àgbà ló lágbára láti fún èèyàn nírú àwọn ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀, àmọ́ wọ́n ṣì lè fi hàn pé àwọn fẹ́ràn rẹ, bóyá nípa yíyìn ọ́ kí wọ́n sì fún ọ níṣìírí tàbí nípa títẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí ọ nígbà gbogbo. Èyí lè jẹ́ kẹ́ẹ bára yín rẹ́ gan an. Damaris sọ nípa ìyá rẹ̀ àgbà pé: “Kò fayé ni mí lára, mo lè lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ nígbàkigbà kí n sì bá a sọ̀rọ̀ nítorí ó ṣe tán láti gbọ́ tèmi nígbà yòówù ó jẹ́, kódà kó tiẹ̀ jẹ́ ìrégbè lásán ni mo ń wí.” Bákan náà ni ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Jônatas gbádùn òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ àti àǹfààní láti jíròrò àwọn kókó ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì pẹ̀lú àwọn òbí rẹ̀ àgbà.
Bù-fún-Mi-N-Bù-fún-Ọ Ni O
Bó ti jẹ́ pé o lè kọ́gbọ́n lọ́dọ̀ àwọn òbí àgbà kí wọ́n sì fi ìfẹ́ hàn sí ọ, àwọn náà lè jàǹfààní nínú agbára ọ̀dọ́ tóo ní àti ìbákẹ́gbẹ́ rẹ. Báwo? Tóò, àwọn ọ̀nà bíi mélòó kan wà tóo fi lè ran àwọn òbí rẹ àgbà lọ́wọ́ kóo sì tì wọ́n lẹ́yìn. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ lágbára mọ́. Tàbí kí àìlera máa bá wọn fínra. Ó dájú pé ara wọn á yá gágá bóo bá lọ bá wọn ra nǹkan tóo sì bá wọn ṣe àwọn iṣẹ́ inú ilé.
Ọ̀pọ̀ àwọn òbí àgbà ló jẹ́ pé ọkọ tàbí aya wọn ti kú tí wọ́n sì máa ń nímọ̀lára ìnìkanwà nígbà mìí. Nípa fífi ìfẹ́ hàn sí wọn, o lè ràn wọ́n lọ́wọ́ gan an láti kojú ìmọ̀lára ìnìkanwà kí wọ́n sì máa ri ògidì ayọ̀ nínú ìgbésí ayé. Ṣíṣe èyí jẹ́ ọ̀nà kan láti tẹ̀ lé àṣẹ Bíbélì pé “kí [o] sì máa san àsanfidípò yíyẹ fún àwọn òbí [rẹ] àgbà, nítorí tí èyí ṣe ìtẹ́wọ́gbà lójú Ọlọ́run.”—1 Tímótì 5:4.
Ó dájú pé sísún mọ́ àwọn òbí rẹ àgbà yóò mú kí ìgbésí ayé tìrẹ àti tiwọn túbọ̀ dùn sí i! Bóyá o ṣì ń sára fún wọn di báa ṣe ń wí yìí. Ó sì lè jẹ́ pé o fẹ́ ṣàtúnṣe àmọ́ o ò mọ ibi tóo ti máa bẹ̀rẹ̀. Ó lè jẹ́ pé ibi táwọn òbí rẹ àgbà ń gbé jìnnà tàbí pé àwọn òbí rẹ ti pínyà tí èyí sì ti mú kí ibi tóo wà jìnnà sáwọn òbí rẹ àgbà. Àpilẹ̀kọ kan lọ́jọ́ iwájú yóò fún ọ ní àwọn àbá tó gbéṣẹ́ lórí ohun tóo lè ṣe bọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Àwọn òbí àgbà máa ń tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ wọ́n sì lè jẹ orísun ìmọ̀ràn àti ìtìlẹ́yìn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Máa ran àwọn òbí rẹ àgbà lọ́wọ́