Kí Ló Ń dúró De Ìsìn Lọ́jọ́ Iwájú?
Kí Ló Ń dúró De Ìsìn Lọ́jọ́ Iwájú?
Ọ̀ NÀ tó jọni lójú gbáà ni ìsìn tún fi gbérí padà láwọn orílẹ̀-èdè Soviet Union àtijọ́. Nílẹ̀ Rọ́ṣíà nìkan ṣoṣo, ìpín àádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó ń gbébẹ̀ ló pe ara wọn ní ẹlẹ́sìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì báyìí, tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ sì ń ṣe àwọn ẹ̀sìn míì. Ẹ̀sìn Ìsìláàmù, ẹ̀sìn àwọn Júù àti ẹ̀sìn Búdà wà lára àwọn tọ́jọ́ wọ́n ti pẹ́, ó sì ti pẹ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà ti wà níbẹ̀.
Tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn ní ọdún 1891, àwọn aṣojú fún Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, gẹ́gẹ́ báa ṣe mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣáájú ọdún 1931, bẹ ìlú Kishinev ní ilẹ̀ Rọ́ṣíà, (táa wá mọ̀ báyìí sí Chisinau, Moldova) wò. Wọ́n ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn níbẹ̀. Ní 1928, George Young, tó jẹ́ aṣojú pàtàkì fún Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláṣẹ Soviet ní Moscow, ilẹ̀ Rọ́ṣíà, láti gba àṣẹ láti máa tẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Soviet Union. Ohun tó wá mú àwọn Ẹlẹ́rìí gbajúmọ̀ lẹ́yìn náà ni gbígbìyànjú tí ìjọba Soviet gbìyànjú láti tẹ̀ wọ́n rì.
Nígbà tí wọ́n tú ilẹ̀ Soviet Union ká lójijì ní ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe kàyéfì pé, ‘Ki lohun tó tiẹ̀ fà á tí ìjọba Soviet fi gbìyànjú láti mú ìsìn kúrò?’ Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ti fi ẹ̀kọ́ kòsọ́lọ́run kọ́ fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún wá bẹ̀rẹ̀ sí tọpinpin bóyá ìsìn láǹfààní kan tó tiẹ̀ lè ṣe fún wọn. Àbí ó ṣeé ṣe kí Bíbélì, ìwé tí wọ́n ti gbẹ́sẹ̀ lé pé ẹnì kankan ò gbọ́dọ̀ kà ní ìdáhùn sáwọn ìṣòro tó ń kojú aráyé ni? Bẹ́ẹ̀ làwọn ará Rọ́ṣíà bẹ̀rẹ̀ sí wádìí fúnra wọn.
Ìṣòro Mìíràn Lórí Ọ̀ràn Ẹ̀sìn
Ìfẹ́ tí ọ̀pọ̀ èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í ní nínú Bíbélì dá ìṣòro mìíràn nípa ìsìn sílẹ̀ ní ilẹ̀ Soviet Union àtijọ́. Lọ́dún tó kọjá, ìwé ìròyìn Guardian ti ìlú London, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “À bá sọ pé ‘ogun nípa Ọlọ́run’ ti parí, àmọ́ lóhun tí kò ju ẹ̀wádún kan péré lẹ́yìn ìṣubú adójútini tó ṣẹlẹ̀ sí orílẹ̀-èdè tó kọ́kọ́ sọ pé kò sí Ọlọ́run, ọ̀tẹ̀ abẹ́lẹ̀ lórí ọ̀ràn ẹ̀sìn ní Rọ́ṣíà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ lákọ̀tun ni.” Kí lohun tí wọ́n pè ní ọ̀tẹ̀ abẹ́lẹ̀ lórí ọ̀ràn ẹ̀sìn tí ìwé ìròyìn náà ń tọ́ka sí?
Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ nínú àpilẹ̀kọ wa ìṣáájú, wọléwọ̀de ni Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Rọ́ṣíà ń ṣe pẹ̀lú àwọn aṣáájú ilẹ̀ Soviet kí ó lè ráyè jàjàyè kó sì rí àwọn àǹfààní kan gbà. Ìwé ìròyìn The Guardian sọ nípa bí àjọṣe yẹn ṣe ń bá a lọ pé: “Láàárín ọdún mẹ́wàá tó kọjá, ṣọ́ọ̀ṣì tún ti dá àjọṣe tó kọni lóminú sílẹ̀ láàárín òun àti ìjọba kìígbọ́kìígbà, tó ti kọ́kọ́ tẹ̀ ẹ́ rì nígbà kan, ìgbà gbogbo sì ni ṣọ́ọ̀ṣì ń ti ìjọba Rọ́ṣíà lẹ́yìn (irú bí Bíṣọ́ọ̀bù ṣe fọwọ́ sí ogun tó wáyé ní Chechnya) tó sì ń kópa tó jọjú nínú ìṣèlú ní ìsanpadà.”
Nígbà tí ìwé ìròyìn Los Angeles Times ti February 10, 1999 ń sọ̀rọ̀ lórí Òfin Òmìnira Ẹ̀rí Ọkàn àti Àwọn Ẹgbẹ́ Ẹlẹ́sìn, ó pe àfiyèsí sí agbára òṣèlú tí ṣọ́ọ̀ṣì ń lò. Ìwé ìròyìn náà sọ pé òfin yìí, tí Ààrẹ ìgbà náà, Boris Yeltsin fọwọ́ sí ní September 1997, ni “Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Rọ́ṣíà ṣagbátẹrù rẹ̀.” Òfin náà fún ṣọ́ọ̀ṣì yẹn ní ipò tó ń wá, ìyẹn ni jíjẹ́ ìsìn “àdáyébá,” òun àti ìsìn Ìsìláàmù, ìsìn àwọn Júù, àti Ìsìn Búdà. Lára àwọn ohun mìíràn tí òfin náà béèrè ni pé kí àwọn ètò ẹ̀sìn tó wà ní Rọ́ṣíà tún orúkọ wọn fi sílẹ̀.
Ìwé ìròyìn The New York Times ti February 11, 1999, ròyìn pé lẹ́yìn tí wọ́n gbé òfin yìí jáde, “Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì bẹ̀rẹ̀ sí í fúngun mọ́ àwọn ẹ̀sìn mìíràn.” Ìwé ìròyìn Times fi
kún un pé: “Ní oṣù August ọdún tó kọjá, Aleksei Kejì tó jẹ́ Bíṣọ́ọ̀bù Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Rọ́ṣíà sọ pé kí wọ́n fòfin de àwọn ìsìn tó ń yí àwọn èèyàn lọ́kàn padà, pàápàá jù lọ àwọn tó máa ń gbìyànjú láti tan àwọn èèyàn kúrò nínú ‘àwọn ìsìn baba ńlá wọn.’” Àtìgbà yẹn ni akitiyan ti ń lọ láti fòfin de àwọn ìsìn tí wọ́n pè ní ìsìn ayínilọ́kànpadà, ìyẹn sì ti yọrí sí ohun tí wọ́n pè ní “ọ̀tẹ̀ abẹ́lẹ̀ lórí ọ̀ràn ẹ̀sìn.”Ọ̀kan Lára Àwọn Tí Wọ́n Dájú Sọ
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn tí wọ́n dojú àtakò tí Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Rọ́ṣíà dá sílẹ̀ kọ. Ní June 20, 1996, ilé ẹjọ́ Moscow kan bẹ̀rẹ̀ sí ṣàyẹ̀wò ẹjọ́ táwọn kan tó ń gbogun ti ẹgbẹ́ òkùnkùn pè, ìyẹn Ìgbìmọ̀ Tó Ń Dáàbò Bo Àwọn Ọ̀dọ́ Lọ́wọ́ Ìsìn Èké. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé dákú-dájí lọ̀ràn ẹjọ́ ọ̀hún nítorí àìsí ẹ̀rí pé àwọn Ẹlẹ́rìí hùwà ọ̀daràn kankan, kò sígbà tí wọn kì í gbé e dìde.
Láàárín àkókò náà, ìpolongo èké tó pọ̀ jaburata ni wọ́n ń ṣe nípa àwọn Ẹlẹ́rìí. Komsomolskaya Pravda, ìwé ìròyìn kan lédè Rọ́ṣíà tí ìpíndọ́gba rẹ̀ tó ọgọ́ta ọ̀kẹ́ [1,200,000], sọ nínú ìtẹ̀jáde rẹ̀ ti November 21, 1998 pé: “Láàárín ọdún méjì péré, Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Rọ́ṣíà ṣe ìwé tó lé ní mẹ́wàá, ìwé pẹlẹbẹ, àtàwọn ìwé ìléwọ́ ‘nítorí’ àwọn Oní-Jèhófà.” Kí ló dé tó jẹ́ títàbùkù àwọn Ẹlẹ́rìí ni ṣọ́ọ̀ṣì náà gbájú mọ́?
Ìwé ìròyìn Komsomolskaya Pravda ń bá a lọ pé: “Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ nítorí pé láàárín ọdún méje péré tó kọjá, iye mẹ́ńbà ètò àjọ yẹn ti ròkè ní ìlọ́po mẹ́wàá, Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Rọ́ṣíà sì rèé, kò fẹ́ káwọn kankan bá òun dupò gẹ́gẹ́ bó ti máa ń rí pẹ̀lú àjọ tó bá ń ṣàkóso ẹ̀sìn.”
Nígbà tí wọ́n tún ṣíṣọ lójú ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn Ẹlẹ́rìí níbẹ̀rẹ̀ ọdún 1999, gbogbo ayé ló gbọ́ nípa rẹ̀. Àkọlé kan nínú ìwé ìròyìn New York Times ti February 11 kà pé: “Ilé Ẹjọ́ Moscow Ń Gbé Ọ̀ràn Ìfòfinde Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Yẹ̀ Wò.” Àpilẹ̀kọ náà sọ pé: “Ẹjọ́ ọ̀hún tó ti dé iwájú ilé ẹjọ́ gbogbo gbòò báyìí ní Moscow, èyí tí wọ́n ti kọ́kọ́ gbọ́ ní yàrá ìgbẹ́jọ́ kékeré kan, tí wá di èyí tí àwọn ẹgbẹ́ onísìn àti ti ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ń pé wò gẹ́gẹ́ bí ìgbìyànjú pàtàkì àkọ́kọ́ láti lo [Òfin Òmìnira Ẹ̀rí Ọkàn àti Àwọn Ẹgbẹ́ Ẹlẹ́sìn] láti fi fòfin de ìjọsìn.”
Lyudmila Alekseyeva, tó jẹ́ ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìparapọ̀ ti Helsinki ṣàlàyé ìdí tí gbogbo ayé fi ń wo ibi tí ẹjọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí máa jálẹ̀ sí. Ó sọ pé, táwọn tó ń gbìyànjú láti tẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rì “bá fi kẹ́sẹ járí nínú ẹjọ́ yìí,” a jẹ́ “pé wọ́n á lómìnira nìyẹn láti tún gbógun ti àwọn àwùjọ mìíràn” tí wọ́n tún kà sí ìsìn tí kì í ṣe àdáyébá. Bó ti wù kó rí, ní March 12, 1999, wọ́n tún sún ẹjọ́ yẹn síwájú. Àmọ́ lóṣù tó tẹ̀ lé e, ní April 29, Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ Ilẹ̀ Rọ́ṣíà fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìwé ẹ̀rí ìforúkọsílẹ̀ fún “Ibùdó Ìdarí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà.”
Láìka bí ìjọba ti fọwọ́ sí wọn sí, gbígbógun tàwọn Ẹlẹ́rìí àtàwọn ẹ̀sìn mìíràn tí kò gbajúmọ̀ kò dópin ní Rọ́ṣíà àtàwọn orílẹ̀-èdè olómìnira ilẹ̀ Soviet àtijọ́ mìíràn. Lawrence Uzzell, olùdarí Ilé Ẹ̀kọ́ Keston nílùú Oxford, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé, “ó dára kéèyàn máa wo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà” nítorí pé “àmì kan tó ń ṣèkìlọ̀ ṣáájú” lohun tó bá ṣẹlẹ̀ sí wọn máa ń jẹ́. Ká sòótọ́, òmìnira ìsìn, èyí tó ṣe pàtàkì fún ọ̀pọ̀ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn wà nínú ewu!
Àtakò Wọn Kò Lẹ́sẹ̀ Ńlẹ̀
Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn olórí àlùfáà àtàwọn aṣáájú ìsìn ṣe inúnibíni sáwọn ọmọlẹ́yìn Jésù. (Jòhánù 19:15; Ìṣe 5:27-33) Èyí mú káwọn èèyàn sọ́ nípa ìsìn Kristẹni pé: “Lóòótọ́, ní ti ẹ̀ya ìsìn yìí, a mọ̀ pé níbi gbogbo ni wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ lòdì sí i.” (Ìṣe 28:22) Nítorí náà, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé wọ́n á ba àwọn Kristẹni tòótọ́ lórúkọ jẹ́ lónìí, bí wọ́n ti ṣe sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Síbẹ̀, lẹ́yìn tí Gàmálíẹ́lì tó jẹ́ Farisí olókìkí àti olùkọ́ Òfin ti yẹ ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn Kristẹni ìjímìjí wò, ó ṣe kìlọ̀kìlọ̀ pé: “Ẹ má tojú bọ ọ̀ràn àwọn ọkùnrin wọ̀nyí, ṣùgbọ́n ẹ jọ̀wọ́ wọn jẹ́ẹ́; (nítorí pé, bí ó bá jẹ́ pé láti Ìṣe 5:38, 39.
ọ̀dọ̀ ènìyàn ni ìpètepèrò tàbí iṣẹ́ yìí ti wá, a ó bì í ṣubú; ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni, ẹ kì yóò lè bì wọ́n ṣubú;) bí bẹ́ẹ̀ kọ́, a lè wá rí yín ní ẹni tí ń bá Ọlọ́run jà ní ti gidi.”—Lónìí náà, àwọn olùṣelámèyítọ́ ti fẹ̀sọ̀ ṣe àyẹ̀wò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Pẹ̀lú àbájáde wo? Sergey Blagodarov, tóun fúnra rẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́sìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì sọ nínú ìwé ìròyìn Komsomolskaya Pravda pé: “Fún ohun tó ju ọgọ́rùn-ún ọdún lọ, kò sí ẹyọ orílẹ̀-èdè kan lágbàáyé tó lè rí ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn fi kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí ìdí tí wíwà wọn fi jẹ́ aláìbófinmu.”
Báwo Lọ́jọ́ Iwájú Ìsìn Ṣe Máa Rí?
Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa “ìsìn mímọ́,” tàbí “ìjọsìn tí ó mọ́, tí ó sì jẹ́ aláìlẹ́gbin.” (Jákọ́bù 1:27a; tún wo Bibeli Mimọ.) Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, Bíbélì ṣàpèjúwe ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé gẹ́gẹ́ bí “aṣẹ́wó ńlá . . . ẹni tí àwọn ọba ilẹ̀ ayé bá ṣe àgbèrè.” Ìsìn táa pè ní aṣẹ́wó lọ́nà àpèjúwe yìí—ìyẹn “Bábílónì Ńlá”—ni a sọ pé ó “mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹni mímọ́ àti ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹlẹ́rìí Jésù ní àmupara.”—Ìṣípayá 17:1-6.
Ẹ ò ri pé wẹ́kú ni àpèjúwe yìí bá ìsìn mu nítorí ó ti ń ṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú àwọn aṣáájú òṣèlú ayé kí àǹfààní tó ń rí jẹ má bàa bọ́! Síbẹ̀, a ti fi èdìdì di ọjọ́ iwájú aṣẹ́wó ńlá tó dúró fún ìsìn yìí. Bíbélì sọ pé: “Ní ọjọ́ kan ṣoṣo, àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀, ikú àti ọ̀fọ̀ àti ìyàn yóò dé, a ó sì fi iná sun ún pátápátá, nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tí ó ṣèdájọ́ rẹ̀, jẹ́ alágbára.” Abájọ tí ìkìlọ̀ áńgẹ́lì náà fi jẹ́ kánjúkánjú pé: “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀ . . . bí ẹ kò bá . . . fẹ́ gbà lára àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀”!—Ìṣípayá 18:4, 7, 8.
Nígbà tí ọmọ ẹ̀yìn náà, Jákọ́bù ń sọ bí “ìsìn mímọ́” ṣe máa rí, ó ní yóò “pa ara [rẹ̀] mọ́ láìní èérí kúrò nínú ayé.” (Jákọ́bù 1:27b) Kò tán síbẹ̀ o, Jésù Kristi sọ nípa àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tòótọ́ pé: “Wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.” (Jòhánù 17:16) Ṣé o wá rí ìdí náà báyìí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń pa ara wọn mọ́ kúrò nínú ẹ̀gbin ọ̀ràn òṣèlú ayé tó lè kó èérí bá wọn? Ìgbọ́kànlé wọn tí kì í yẹ̀ nínú ìlérí Bíbélì ló ń mú kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, èyí tó sọ pé: “Ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”—1 Jòhánù 2:17.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ìgbẹ́jọ́ tí wọ́n ṣe ní Moscow ní February 1999. Àwọn olùjẹ́jọ́ (lọ́wọ́ òsì), onídàájọ́ (láàárín), àtàwọn olùpẹ̀jọ́ (lọ́wọ́ ọ̀tún)
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Bíbélì sọ bí ọjọ́ iwájú gbogbo ìsìn ṣe máa rí