Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Rìnrìn Àjò Lọ Sí Ọgbà Ẹranko Ní Gánà

A Rìnrìn Àjò Lọ Sí Ọgbà Ẹranko Ní Gánà

A Rìnrìn Àjò Lọ Sí Ọgbà Ẹranko Ní Gánà

LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ GÁNÀ

BÍ ÒKÙNKÙN àti kùrukùru ti ń paradà tí ojúmọ́ ń mọ́ bọ̀, a fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wa ọlọ́gọ́rin kìlómítà lórí títí tí kò lọ́dà lọ sí Ọgbà Ìtura Mole Níhà Àríwá Gánà. Koríko, igbó àtàwọn igi kúúkùùkú ló kún àyíká náà lọ salalu. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a ń kọjá ní àwọn abúlé kéékèèké tó láwọn ahéré tí wọ́n fi amọ̀ kọ́ tí wọ́n sì fi koríko ṣe òrùlé wọn.

Ohun táa rí yàtọ̀ pátápátá nígbà táa dé Damongo, ìlú kan tó wà ní àrọko tí àwọn èrò ń wọ́ lọ wọ́ bọ̀ nínú rẹ̀, ó ní àwọn ṣọ́ọ̀bù, títì ọlọ́dà, àtàwọn ọkọ̀ tó ń lọ tó ń bọ̀! Àwọn ọmọdé tí wọ́n wọṣọ iléèwé aláwọ̀ ìyeyè àti àwọ̀ ilẹ̀ ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́. Àwọn obìnrin tó wọṣọ oríṣiríṣi ru onírúurú ẹrù bí—igi ìdáná, oúnjẹ, àtàwọn nǹkan ìpọnmi tómi kúnnú wọn. Àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àtàwọn ẹ̀rọ katakata ń han gan-anran, bẹ́ẹ̀ làwọn oníkẹ̀kẹ́ náà ò láwọn ò sí níbẹ̀. Ogún kìlómítà ṣì nibi táa ń lọ.

Lọ́gbà Ẹranko Mole

Níkẹyìn, a dé ọgbà ẹranko náà. Níbàámu pẹ̀lú ohun tí Zechariah tó mú wa káàkiri sọ, ọdún 1971 ni wọ́n dá Ọgbà Ẹranko Mole sílẹ̀, ó sì fẹ̀ ní òjì lé lẹ́gbẹ̀rìnlélógún [4,840] kìlómítà níbùú àti lóròó. Àkọsílẹ̀ tí wọ́n ṣe nípa ọgbà náà fi hàn pé ó ní irú ọ̀wọ́ ẹranko afọ́mọlọ́mú mẹ́tàléláàádọ́rùn-ún, jomijòkè mẹ́sàn-án, àti afàyàfà mẹ́tàlélọ́gbọ̀n. Àwọn wọ̀nyí ní nínú, kìnnìún, àmọ̀tẹ́kùn, pẹnlẹpẹ̀, ológbò civet , erin, bongo, ẹfọ̀n, ìmàdò, òtòlò, gìdìgìdì, genet, ìrá kùnnùgbá, mongoose, ìrò, oríṣiríṣi ọ̀bọ, àgbáǹréré, òòrẹ̀, ọ̀nì, àti ejò, títí kan òjòlá. Yàtọ̀ sáwọn yẹn, ó lé ní ọ̀ọ́dúnrún irú ọ̀wọ́ ẹyẹ tí wọ́n ti rí níbẹ̀.

Báa ti ń fọwọ́ pa àwọn kòkòrò arebipa tó ń fò síwa lára nínú koríko tó gùn dórúnkún wa táa ń wọ́ lọ, kò pẹ́ táa fi dé tòsí àwọn ẹtu kan tó péjọ. A ò kọ́kọ́ rí wọn, nítorí pé àwọ̀ wọn ò yàtọ̀ sí àyíká wọn. Báa ṣe ń wò wọ́n làwọn náà tẹjú mọ́ wa roro, débi pé, a ò tiẹ̀ wá mọ ẹni tó ń wora wọn nínú àwa àtàwọn. Fọ́tò la ń yà lọ́wọ́ nígbà tí nǹkan kan fọnmú lọ́nà tí ń múni ta gìrì lápá ọ̀tún wa. Akọ òtòlò títóbi kan ló ń bínú pé a wá síbi ìkọ̀kọ̀ òun tó sì sá wọnú igbó tó wà níwájú wa.

Kò pẹ́ lẹ́yìn náà táa rí àwọn erin fàkìàfakia mẹ́rin kan lábẹ́ igi. Wọ́n ń fi ọwọ́ ìjà wọn ya ẹ̀ka igi lulẹ̀ tí wọ́n sì ń jẹ àwọn ọ̀mùnú wọn. A rìn sún mọ́ wọn, nígbà tó sì ku mítà mẹ́wàá péré ká dé ọ̀dọ̀ wọn, Zechariah ní a lè ya fọ́tò wọn. Ó fọwọ́ gbá ìdí ìbọn rẹ̀, ìyẹn sì pariwo bí ìgbà téèyàn bá fi nǹkan lu páànù, èyí lé àwọn erin náà kúrò lábẹ́ igi yẹn a sì ráyè ya fọ́tò wọn dáadáa. Ní tòsí ibẹ̀, àwọn erin náà rí ibi kan tí ẹrẹ̀ wà ni wọ́n bá sọ ọ́ di omi ìwẹ̀. Zechariah ṣàlàyé pé àwọ̀ àwọn erin náà máa ń yí padà láti dúdú tó jẹ́ àwọ̀ wọn gangan sí pupa tàbí àwọ̀ ilẹ̀—ìyẹn sì sinmi lórí irú ẹrẹ̀ tí wọ́n bá wẹ̀ nínú ẹ̀.

A rìn síwájú díẹ̀ a sì túbọ̀ rí bí àyíká ilẹ̀ ọgbà ẹranko náà ṣe rí dáadáa. Àwọn igi bọn-ọ̀n-ní àti igi ẹmi wà láàárín koríko ibẹ̀. Nígbà táa ń padà bọ̀, a gba ibi táwọn erin yẹn gbà. Wọ́n ṣì fi mítà díẹ̀ jìnnà sí wa, àmọ́ ńṣe lèyí tó tóbi jù lọ nínú àwọn erin náà na etí rẹ̀ wọnwọn tó múra ìjà, tó sì ń bọ̀ lápá ọ̀dọ̀ wa. Àbó fẹ́ jà ni?

Zechariah sọ pé ká má mikàn o, àmọ́ lẹ́sẹ̀ kan náà, ó gbé ìbọn rẹ̀ kúrò léjìká ó sì mú wa gba ọ̀nà míì tí kì í ṣe ibi táwọn erin náà gbà. A ń rìn lọ, afinimọ̀nà wa gbé ìbọn rẹ̀ lọ́wọ́, àwa náà gbé kámẹ́rà wa gbágbáágbá—táa ṣe tán láti lò ó. Kò pẹ́ táa fi kúrò níbi tí erin náà ti lè rí wa.

Zechariah sọ fún wa pé èèyàn ò ṣàjèjì sáwọn erin inú ọgbà yìí àti pé àwọn kan tiẹ̀ máa ń wá tòsí èèyàn. Tó bá di pé àwọn afinimọ̀nà ń rí àwọn erin náà déédéé, wọ́n máa ń fún wọn lórúkọ. Wọ́n pe ọ̀kan ní Oníkókó nítorí pé kókó ńlá kan wà lára rẹ̀. Wọ́n sọ òmíràn ní Kògbérèégbè nítorí pé ó máa ń dẹ́rù ba àwọn arìnrìn-àjò afẹ́.

A tún bá àwọn ìrò pàdé. À ń wò wọ́n bí wọn ti ń rọ̀ dirodiro lórí igi tàbí tí wọ́n ń sá kiri ilẹ̀. Afinimọ̀nà wa ní ká wo ìyá àwọn ìrò kan tó gbé ọmọ méjì dání, ó pọn ọ̀kan sẹ́yìn ó sì gbé ìkan yòókù sí àyà. Ó ní ìbejì ni wọ́n.

Ká sòótọ́, àwọn ẹranko ìgbẹ́ táa ti rí lónìí kúrò ní díẹ̀. Zechariah sọ fún wa pé téèyàn bá fẹ́ rí àwọn ẹranko ìgbẹ́ lásìkò ẹ̀ẹ̀rùn, ìyẹn láàárín oṣù April sí June, kéèyàn sáà ti lọ dúró síbi táwọn ihò omi wà, nítorí pé àwọn ẹran náà á wá lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti wá mu omi. Ó tún sọ pé tó bá jẹ́ ọkọ̀ arinkòtò-ringegele lèèyàn gbé lọ sínú igbó náà, èèyàn á tún rí ọ̀pọ̀ ẹranko mìíràn bí ẹfọ̀n àti kìnnìún.

Àsìkò oúnjẹ ọ̀sán ti tó báyìí. Níbi táa ti ń jẹun lọ́wọ́, ìrò ńlá kan jókòó sórí ibi pẹrẹsẹ kan lórí ọkọ̀ akẹ́rù kékeré tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wa ó sì ranjú mọ́ oúnjẹ mi láìbẹ̀rù rárá. Àwọn ìrò mìíràn tún kọjá, pẹ̀lú àwọn ẹtu àti ìmàdò bíi mélòó kan, níkẹyìn erin mẹ́rin yọ lórí òkè kan nítòsí. Ó jọ pé ibi táa wà yẹn fún wa láǹfààní láti ya fọ́tò àwọn ẹranko yìí!

Ní Àárín Ọjà

Àkókò táa lò ní Ọgbà Ẹranko Mole kò pọ̀ rárá, la bá wa ọkọ̀ wa lórí títì tí kò lọ́dà fún wákàtí méjì lọ sí Sawla, abúlé kan táwọn ẹ̀yà Lobi tó jẹ́ àgbẹ̀ ń gbé. Àwọn obìnrin wọn ní àṣà yíyanilẹ́nu kan ti sísọ ètè wọn di ńlá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lónìí, àṣà yẹn ti ń pòórá díẹ̀díẹ̀ bí ọ̀làjú òde ìwòyí ti ń nípa lórí àwọn ọ̀dọ́bìnrin, síbẹ̀, púpọ̀ obìnrin ló ṣì gba ti kí ètè wọ́n tóbi. Kódà, nǹkan ìwọ̀sí ni wọ́n kà á sí pé kí ẹnì kan sọ fún obìnrin Lobi pé ètè ẹ̀ kéré bíi tọkùnrin.

A dé abúlé kan a sì wọnú ọjà lọ. Ẹ̀ka igi mẹ́ta ni wọ́n fi ṣe àwọn àtíbàbà rẹ̀ wọ́n sì fi koríko ṣe àwọn òrùlé rẹ̀. Òyìnbó kan dúró sáàárín ọjà náà láàárín àwọn adúláwọ̀ ọmọ Áfíríkà. A sún mọ́ ọn, a sì wá rí i pé o ṣẹ̀ṣẹ̀ dé síbí láti wá tú Bíbélì sí èdè Lobi ni. Abúlé kan tó wà nítòsí ló ń gbé láàárín àwọn ẹ̀yà Lobi kó lè mọ èdè wọn sọ dáadáa. Ìyẹn rán mi létí Robert Moffat, tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìjíhìn láàárín àwọn èèyàn tó ń sọ èdè Tswana ní ìhà gúúsù Áfíríkà ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún tó sì túmọ̀ Bíbélì sí èdè wọn.

Obìnrin àgbàlagbà kan tó jẹ́ ẹ̀yà Lobi pẹ̀lú ètè rẹ̀ fífẹ̀ jókòó lórí àga gbọọrọ kan lábẹ́ ọ̀kan lára àwọn àtíbàbà ọjà náà. Wọ́n ki àwọn igi pẹlẹbẹ funfun méjì tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn tóbi tó èékánná àtàǹpàkò sínú ihò kan nínú ètè rẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Mo fẹ́ yà á ní fọ́tò, àmọ́ bí mo ṣe gbé kámẹ́rà mi sókè báyìí, ló bá yíjú síbòmíì. Ọ̀kan lára àwọn táa jọ ń lọ ló wá sọ fún mi pé àwọn ẹ̀yà Lobi gbà gbọ́ pé tí ẹnì kan bá yà wọ́n ní fọ́tò, ó lè ṣe nǹkan tí kò dáa fún ọkàn wọn.

Báa ti ń padà sí Sawla níbi táa máa sùn sí, mo ronú nípa ọgbọ́n àti onírúurú nǹkan táa ti rí nínú ìṣẹ̀dá Ọlọ́run. Ọgbọ́n ọnà tó fi dá àwọn ẹranko àtàwọn ènìyàn ga lọ́lá. Ńṣe ló rí gẹ́lẹ́ bí onísáàmù náà ti kókìkí rẹ̀ pé: “Àwọn iṣẹ́ rẹ mà pọ̀ o, Jèhófà! Gbogbo wọn ni o fi ọgbọ́n ṣe. Ilẹ̀ ayé kún fún àmújáde rẹ.”—Sáàmù 104:24.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 20, 21]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

GÁNÀ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Ìmàdò

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Pẹnlẹpẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Agbo àwọn ẹtu

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Erin

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Erinmi

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Ìyá àwọn ìrò tó gbọ́mọ méjì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ìrá kùnnùgbá

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ibi ọjà