Ṣé Omi Ń tán Lọ Láyé Ni?
Ṣé Omi Ń tán Lọ Láyé Ni?
“Rírí omi tó dára tí kò sì lẹ́gbin nínú fún mímu àti níní àwọn ibi táa ti lè rí wọn ní ànító àti àníṣẹ́kù jẹ́ kòṣeémánìí fún ìwàláàyè, wíwà lálàáfíà, àti ìdàgbàsókè ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà àti ètò ọrọ̀ ajé gbogbo ẹ̀dá lápapọ̀. Àmọ́ ń ṣe là ń ṣe bí ẹni pé títí lọ kánrin lomi tó dára fún mímu á máa wà. Kò sóhun tó jọ bẹ́ẹ̀.”—KOFI ANNAN, Ọ̀GÁ ÀGBÀ FÚN ÌPARAPỌ̀ ÀWỌN ORÍLẸ̀-ÈDÈ.
FÚN ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn ni kóòtù àkànṣe kan tó wà nílùú Valencia ní Sípéènì ti máa ń ṣe ìgbẹ́jọ́ ní gbogbo ọ̀sán ọjọ́ Thursday. Iṣẹ́ tó gbà ni pé kó máa yanjú aáwọ̀ tọ́ràn omi bá dá sílẹ̀.
Bíbomi rin ilẹ̀ làwọn àgbẹ̀ tó ń dáko ní ilẹ̀ ọlọ́ràá Valencia gbára lé, bẹ́ẹ̀ sì rèé, omi tí ìbomirinlẹ̀ ń gbà ò kéré, omi ọ̀hún kì í sì í tó ní àgbègbè yìí ní ilẹ̀ Sípéènì. Àwọn àgbẹ̀ náà láǹfààní láti pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí kóòtù olómi náà nígbàkigbà tí wọ́n bá rí i pé wọ́n ò fún wọn tó bó ṣe yẹ. Awuyewuye nítorí omi ò ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ o, àmọ́, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má sígbà kan tí wọ́n rí ọ̀rọ̀ náà yanjú bíi ti Valencia.
Ó ń lọ sí bí ẹgbàajì [4,000] ọdún báyìí tí wàhálà rannto kan ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn olùṣọ́ àgùntàn kan, nípa ẹni tó ni kànga kan tó wà nítòsí Bíá-ṣébà ní Ísírẹ́lì. (Jẹ́nẹ́sísì 21:25) Látìgbà náà wá, ìṣòro omi tí burú sí i ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé. Ó kéré tán, méjì lára àwọn aṣáájú pàtàkì lágbègbè náà ló ti sọ pé ọ̀ràn omi jẹ́ ohun kan tó lè mú káwọn dìde ogun sí Orílẹ̀-èdè kan tó múlé gbè wọ́n.
Kì í ṣòní kì í ṣàná tọ́rọ̀ omi ti ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwọn orílẹ̀-èdè kan lágbàáyé níbi tí òjò kì í ti í dunlẹ̀. Ìdí tí èyí sì fi rí bẹ́ẹ̀ kò ṣòro láti mọ̀: Omi ṣe pàtàkì fún ìwàláàyè. Kò tàsé ohun tí Kofi Annan sọ pé, “omi ò lọ́tàá: láìsí omi a ò lè gbáyé. Kò láàrọ̀: kò sóhun táa lè fi dípò rẹ̀. Nǹkan sì tún tètè ń nípa lórí ẹ̀: ìgbòkègbodò ẹ̀dá ń kópa tó jọjú lórí bí omi tó dára fún mímu tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó á ṣe pọ̀ tó àti bó ṣe máa jẹ́ ojúlówó sí.”
Kò tíì sígbà kan tí ewu wu omi tó dára, tó ṣe é mu, tó sì tún pọ̀ tó nínú ilẹ̀ ayé wa bíi tọjọ́ òní. Kò yẹ ká jẹ́ kí pípọ̀ tómi pọ̀ rẹpẹtẹ
láwọn apá ibi tí nǹkan ti ṣẹnuure láyé tàn wá jẹ.Omi Tó Wà Láyé Ń Dínkù
Igbákejì Ọ̀gá Àgbà fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, Elizabeth Dowdeswell sọ pé: “Ọ̀kan lára àwọn ohun ńlá tó takora nínú àbùdá ẹ̀dá èèyàn ni pé, tí nǹkan ò bá sí mọ́ la máa ń mọyì ẹ̀. Ìgbà tí kò bá sómi mọ́ la máa ń tó mọyì omi. Bẹ́ẹ̀ kẹ̀ rèé omi ti ń tán lọ, kì í ṣe láwọn àgbègbè tí ọ̀dá ti ń ṣẹlẹ̀ nìkan àmọ́ láwọn àdúgbò tí a kò mọ̀ mọ́ ọ̀wọ́n omi pàápàá.”
Àwọn tí ìṣòro yìí yé jù lọ làwọn tó ń kojú ọ̀wọ́n omi lójoojúmọ́. Asokan, tó ń ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì nílùú Madras ní Íńdíà gbọ́dọ̀ jí ní wákàtí méjì kílẹ̀ tó mọ́ láràárọ̀. Korobá márùn-ún ló máa ń kó lọ́wọ́ lọ sídìí omi ẹ̀rọ àdúgbò, ìyẹn sì jẹ́ ìrìn ìṣẹ́jú márùn-ún sílé ẹ̀. Nítorí pé àárín aago mẹ́rin sí mẹ́fà òwúrọ̀ nìkan ni wọ́n máa ń ṣí omi, ó di dandan kó tètè lọ tò sórí ìlà. Omi tó bá fi àwọn korobá rẹ̀ pọn wá sílé ló máa lò ṣúlẹ̀ ọjọ́ yẹn. Púpọ̀ àwọn ará Íńdíà bíi tiẹ̀ àtàwọn bílíọ̀nù kan èèyàn míì láyé ni kò tiẹ̀ nírú àǹfààní yìí. Wọn ò lómi ẹ̀rọ, wọn ò lódò, bẹ́ẹ̀ ni kò sí kànga ní tòsí ilé wọn.
Ọ̀kan lára irú wọn ni Abdullah, ọmọdékùnrin kan tó ń gbé lágbègbè Sahel ní Áfíríkà. Pákó ìsọfúnni tó ń tọ́ka sí ọ̀nà abúlé rẹ̀ kékeré sọ pé pápá oko tútù ni abúlé ọ̀hún; àmọ́ ọjọ́ pẹ́ tómi ti dàwátì níbẹ̀, eku káká lèèyàn sì fi lè fojú gán-án-ní igi kankan. Iṣẹ́ Abdullah ni pé kó lọ máa pọn omi tí ìdílé rẹ̀ máa lò wá látinú kànga kan tó jìnnà ju kìlómítà kan lọ sílé wọn.
Láwọn apá ibi kan láyé, omi tó mọ́ tó sì ṣeé mu táwọn èèyàn nílò lójú méjèèjì ti bẹ̀rẹ̀ sí kéré kọjá ohun tí wọ́n ń rí. Ohun tó fà á kò fara sin: Ibi tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn ń gbé láyé jẹ́ àgbègbè tó ti gbẹ táútáú tàbí tí òjò kì í ti í dunlẹ̀, ti omi sì ti di ohun tó ṣọ̀wọ́n. (Wo àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 15.) Gẹ́gẹ́ bí Ilé Ẹ̀kọ́ Nípa Àyíká ní Stockholm ti sọ, lọ́wọ́lọ́wọ́, ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta àwọn èèyàn tó wà láyé ló ń gbé láwọn àgbègbè tí ìyà omi ti ń jẹ wọ́n díẹ̀ tàbí tó ń jẹ wọ́n lójú méjèèjì. Bẹ́ẹ̀ sì ni wíwá táwọn èèyàn ń wá omi ti fi ohun tó lé ní ìlọ́po méjì ga ju bí iye àwọn olùgbé ayé ṣe ń pọ̀ sí lọ.
Yàtọ̀ síyẹn, omi tó wà kò pọ̀ sí i. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kànga tí wọ́n gbẹ́ jìn àtàwọn ibi tí wọ́n ń tọ́jú omi sí lè dín wàhálà
náà kù níwọ̀nba, àmọ́ kò sí ìyàtọ̀ nínú iye òjò tó ń rọ̀ sórí ilẹ̀ àti iye omi tó wà lábẹ́ ilẹ̀. Fún ìdí yìí, àwọn tó ń fi wíwo ojú ọjọ́ sọ àsọtẹ́lẹ̀ sọ pé láàárín ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sígbà táa wà yìí, iye omi tó máa wà fún ẹnì kọ̀ọ̀kan láyé láti lò lè máà ju ìdajì ti ìsinsìnyí lọ.Bó Ṣe Kan Ìlera àti Oúnjẹ
Ọ̀nà wo ni àìtó omi fi ń nípa lórí àwọn èèyàn? Lákọ̀ọ́kọ́, ó máa ń ba ìlera wọn jẹ́. Kì í kúkú ṣe pe òùngbẹ máa gbẹ wọ́n kú; àmọ́, omi tí kò mọ́ tí wọ́n fi ń gbọ́únjẹ tí wọ́n sì ń mu lè kó àìsàn bá wọn. Elizabeth Dowdeswell sọ pé “ẹ̀gbin omi ló ń fa nǹkan bí ìpín ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo àìsàn tó ń ṣe àwọn èèyàn tó ń gbé láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀sẹ̀ ń gòkè àgbà àti ìdá kan nínú mẹ́ta gbogbo ikú tó ń pa wọ́n.” Láwọn ilẹ̀ tí òjò kì í rọ̀ déédéé ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà yìí, ìgbà gbogbo ni ìgbẹ́ èèyàn tàbí ti ẹranko, oògùn apakòkòrò, ajílẹ̀, tàbí àwọn kẹ́míkà tó ń wá láti àwọn ilé iṣẹ́ máa ń sọ omi wọn di ẹlẹ́gbin. Ìdílé kan tí ìyà ń jẹ lè máà rí ọgbọ́n ta sí i ju pé kí wọ́n lo irú omi bẹ́ẹ̀ lọ.
Bí ara wa ṣe nílò omi láti fọ ìdọ̀tí dànù, bẹ́ẹ̀ náà lomi gbọ́dọ̀ pọ̀ yanturu kí àyíká wa tó lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀gbin, omi ọ̀hún ni kò sì wá sí ní àrọ́wọ́tó ọ̀pọ̀ èèyàn yìí. Iye àwọn èèyàn tí kò ní ìmọ́tótó tó bó ṣe yẹ fò látorí ohun tó lé ní bílíọ̀nù méjì àtààbọ̀ ní 1990 sí ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó bílíọ̀nù mẹ́ta ní 1997. Àwọn wọ̀nyí fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì gbogbo èèyàn tó ń gbé ilẹ̀ ayé. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọ̀rọ̀ ìyè tàbí ikú ni ọ̀rọ̀ ìmọ́tótó jẹ́. Nínú ìwé kan táwọn àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè pawọ́ pọ̀ kọ, Carol Bellamy àti Nitin Desai kìlọ̀ pé: “Bí àwọn ọmọdé kò bá rí omi tó dára mú àti láti wà ní mímọ́ tónítóní, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìlera àti ìdàgbàsókè wọn ló máa wà nínú ewu.”
Bí kò bá sómi, a ò lè mú oúnjẹ jáde. Òótọ́ ni pé òjò ló ń pèsè omi fún ọ̀pọ̀ irè oko, àmọ́ bíbomirinlẹ̀ lọ́nà àtọwọ́dá ti wá di ọ̀nà pàtàkì tí wọ́n ń lò lẹ́nu àìpẹ́ yìí fún bíbọ́ àwọn olùgbé ayé tí iye wọn túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Lónìí, ìpín mẹ́rìndínlógójì nínú ọgọ́rùn-ún irè oko tí wọ́n ń kó lágbàáyé ló sinmi lórí bíbomirin oko. Gbogbo àgbègbè iṣẹ́ ọ̀gbìn tí wọ́n ń bomi rin lágbàáyé pọ̀ dórí góńgó ní nǹkan bí ogún ọdún
sẹ́yìn, àtìgbà náà ló sì ti ń dínkù láìdáwọ́dúró.Ó lè ṣòro láti gbà gbọ́ pé omi tó máa tó aráyé lò ti ń tán lọ tó bá jẹ́ pé kọ̀ọ́kọ̀ọ́ lomi ń tú jáde nínú àwọn ẹ̀rọ omi tó wà nínú ilé wa, táa sì tún ní ilé ìyàgbẹ́ tó mọ́ tónítóní táa sì ń rí omi fọ ìdọ̀tí ibẹ̀ ní fàlàlà. Àmọ́ ó yẹ ká máa rántí pé ìpín ogún péré nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó ń gbé ayé ló ń jẹ irú ìgbádùn bẹ́ẹ̀. Ní ilẹ̀ Áfíríkà, púpọ̀ àwọn obìnrin ibẹ̀ ló ń lo ohun tí kò dín sí wákàtí mẹ́fà lójúmọ́ fún wíwá omi, ọ̀pọ̀ ìgbà sì lomi ọ̀hún á ti dìdàkudà. Irú àwọn obìnrin yìí ni ìnira tó wà nídìí ọ̀rọ̀ yìí yé jù, pé: Omi tó mọ́, tó ṣe é mu ṣọ̀wọ́n, ńṣe ló sì túbọ̀ ń ṣọ̀wọ́n sí i.
Ṣé ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ lè rí ojútùú sí ìṣòro yìí? Ṣé ọ̀nà wà táa fi lè túbọ̀ ṣọ́ omi lò? Ibo tiẹ̀ ni gbogbo omi ọ̀hún lọ ná? Àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e ló máa wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
IBI TÍ OMI TÓ DÁRA WÀ
Inú òkun ni nǹkan bí ìpín mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo omi ilẹ̀ ayé wà àmọ́, ìyọ inú ẹ̀ pọ̀ kọjá ohun tó ṣe é mu, tó ṣe é dáko, àti fún ṣíṣe àwọn nǹkan jáde.
Kìkì nǹkan bí ìpín mẹ́ta nínú ọgọ́rùn-ún omi tó wà láyé ló wúlò fún mímu. Síbẹ̀, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú rẹ̀ náà ni kò tún rọrùn láti rí, gẹ́gẹ́ bí àpèjúwe tó wà níhìn-ín ti fi hàn.
[Àwòrán]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Omi àti ìrì tó dì gbagidi 68.7%
Omi abẹ́ ilẹ̀ 30.1%
Yìnyín, tó dì gbagidi lábẹ́ ilẹ̀ 0.9%
Adágún, odò, àti irà 0.3%
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]
WÀHÁLÀ OMI
◼ ÌSỌDÈÉRÍ Ní Poland kìkì ìpín márùn-ún péré nínú ọgọ́rùn-ún omi odò tó wà níbẹ̀ ló wúlò fún mímu, ìpín márùndínlọ́gọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún ló sì bàjẹ́ kọjá ohun tí wọ́n lè lò láwọn ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ.
◼ OMI ÀÁRÍN ÌGBORO Ní Ìlú Mẹ́síkò tó jẹ́ ìlú tó tóbi jù lọ ṣìkejì lágbàáyé, ọ̀nà tí omi abẹ́lẹ̀ tó ń pèsè ìpín ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún omi ìlú náà fi ń lọ sílẹ̀ kúrò ní kèrémí. Omi tí wọ́n ń fà jáde nínú rẹ̀ fi ìpín àádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún kọjá agbára tó ní láti pèsè òmíràn. Wàhálà yìí kan náà ló ń kojú ìlú Beijing tí í ṣe olú-ìlú China. Agbára rẹ̀ láti ti omi sókè ti lọ sílẹ̀ ju mítà kan lọ lọ́dún, ìdá kan nínú mẹ́ta àwọn kànga rẹ̀ ló sì ti gbẹ táútáú.
◼ ÌBOMIRINLẸ̀ Iyanrìn tó ń gba omi dúró lábẹ́ ilẹ̀ nílùú Ogallala lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti lọ sílẹ̀ débi pé àwọn ilẹ̀ oko tí wọ́n máa ń bomi rin ní àríwá ìwọ̀ oòrùn Texas ti fi ìdá kan nínú mẹ́ta dín kù nítorí àìsí omi. Ìṣòro kan náà ni Orílẹ̀-èdè China àti Íńdíà, tí wọ́n wà ní ipò kejì àti ìkẹta nínú àwọn tó ń pèsè oúnjẹ jù lọ láyé ń fojú winá. Ní ìlú Tamil Nadu tó wà lápá gúúsù Íńdíà, bíbomirinlẹ̀ ti mú kí iyanrìn tó ń gba omi dúró lábẹ́ ilẹ̀ fi nǹkan tó ju mítà mẹ́tàlélógún lọ sílẹ̀ láàárín ọdún mẹ́wàá.
◼ ÀWỌN ODÒ TÓ Ń PÒÓRÁ Tó bá dìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, alagbalúgbú odò Ganges kì í ṣàn dé inú òkun mọ́, nígbà tó jẹ́ pé ọ̀tọ̀ nibi tí gbogbo omi rẹ̀ máa yà sí kó tó dé ibẹ̀. Bákan náà lọ̀rọ̀ rí fún Odò Colorado tó wà ní Àríwá Amẹ́ríkà.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 15]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
ÀWỌN IBI TÍ OMI TI ṢỌ̀WỌ́N
Àwọn àgbègbè tí omi kò ti tó