Oògùn Olóró—Kí Ló Fà á Táwọn Èèyàn Fi Ń lò Ó?
Oògùn Olóró—Kí Ló Fà á Táwọn Èèyàn Fi Ń lò Ó?
“ỌMỌ ọdún mẹ́tàlá ni mí nígbà yẹn, obìnrin kan tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ sọ pé ká wá sílé àwọn lálẹ́ ọjọ́ kan. Gbogbo èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí mu igbó. Mo kọ́kọ́ sọ pé mi ò mu, àmọ́ nígbà tí wọ́n fi lọ̀ mí fúngbà bí mélòó kan, lèmi náà bá tọ́ ọ wò.” Bí Michael, láti Gúúsù Áfíríkà ṣe ṣàlàyé bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí lo oògùn olóró nìyẹn.
“Inú ìdílé tó dára ni mo ti jáde, iṣẹ́ orin sì ni wọ́n ń ṣe lójú méjèèjì. Mo ń bá ẹgbẹ́ olórin kan ṣeré, gbogbo ìgbà sì ni ọ̀kan lára àwọn olórin náà máa ń mu igbó lásìkò ìsinmi. Fún oṣù bíi mélòó kan ló fi rọ̀ mí pé kí n tọ́ ọ wò. Mo tọ́ ọ wò nígbà tó yá, èmi náà sì bẹ̀rẹ̀ sí lò ó déédéé.” Bí Darren, ọmọ ilẹ̀ Kánádà, ṣe bẹ̀rẹ̀ sí lo oògùn olóró nìyẹn.
Àwọn méjèèjì yìí tún bá a débi lílo àwọn oògùn olóró mìíràn, bíi LSD, opium, àtàwọn èròjà amáragbépẹ́pẹ́. Nígbà tí wọ́n ronú nípa bí wọ́n ti ṣe lo oògùn olóró sẹ́yìn, wọ́n gbà pé àwọn ojúgbà wọn ló sún àwọn dédìí lílo oògùn olóró. Michael sọ pé “Mi ò ronú pé màá loògùn olóró láyé mi, àmọ́ kìkìdá àwọn ọmọ yẹn ni mo ní lọ́rẹ̀ẹ́, ohun táwọn ọ̀rẹ́ bá sì ń ṣe lo máa bá wọn ṣe.”
Lágbo Eré Ìnàjú
Ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe ló ń mú kí ọ̀pọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí lo oògùn olóró, àwọn èwe ló sì tètè máa ń kó sọ́fìn yìí. Bákan náà, wọ́n ń rí àpẹẹrẹ àwọn òṣèré tí wọ́n fẹ́ràn gan-an, àwọn wọ̀nyí sì lágbára láti nípa lórí èrò àti ìṣe àwọn èwe tó nífẹ̀ẹ́ wọn.
Lílo oògùn olóró jẹ́ ìṣòro kan tó ń bá àwọn òṣèré fínra. Lọ́pọ̀ ìgbà làwọn kọrinkọrin tí wọ́n jẹ́ gbajúgbajà máa ń lo àwọn oògùn olóró tí wọ́n bá bá iṣẹ́ wọn dé àyè kan. Ọ̀pọ̀ àwọn gbajúgbajà eléré orí ìtàgé ni kò lè ṣe kí wọ́n má lo oògùn olóró.
Àwọn òṣèré lè ṣàpọ́nlé oògùn líle títí á fi di ohun àrímáleèlọ fún àwọn èwe. Ìwé ìròyìn Newsweek sọ lọ́dún 1996 pé: “Ńṣe ni pópó Seattle kún bámúbámú fáwọn ògo wẹẹrẹ tí wọ́n wá mu heroin, nítorí pé ọ̀gbẹ́ni [olórin rọ́ọ̀kì] tó ń jẹ́ Cobain ń mu ún.”
Ńṣe làwọn ìwé ìròyìn, fíìmù, àti tẹlifíṣọ̀n ń polówó oògùn líle bí ohun kan tó gbádùn mọ́ni. Bẹ́ẹ̀ náà làwọn gbajúgbajà aránṣọ kan máa ń gbádùn ríránṣọ fáwọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ ọ̀pẹ́lẹ́ńgẹ́, tí ìrísí wọn dà bí tàwọn ajoògùnyó.
Kí Ló Fà Á Táwọn Kan Fi Di Ajoògùnyó?
Ọ̀pọ̀ nǹkan mìíràn ló mú kí lílo oògùn olóró máa ràn bí iná ọyẹ́. Lára wọn ni ìjákulẹ̀, ìdààmú ọkàn, àti kí ìgbésí ayé èèyàn máà nítumọ̀. Àwọn ohun mìíràn tún ni ìṣòro ìṣúná owó, àìríṣẹ́ṣe, àti káwọn òbí má fi àpẹẹrẹ tó péye lélẹ̀.
Ńṣe làwọn kan tí wọn ò mọ béèyàn ṣe ń lájọṣe pẹ̀lú àwọn èèyàn ń lo oògùn olóró kára wọn lè balẹ̀ láàárín ẹgbẹ́. Èrò wọn ni pé oògùn olóró á jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ láyà dáadáa, pé á jẹ́ kórí àwọn jí pépé káwọn èèyàn sì fẹ́ràn wọn. Ó sì rọrùn fáwọn míì láti joògùn yó ju kí wọ́n wá bí ìgbésí ayé wọn ṣe máa lójútùú lọ.
Sísú tí nǹkan máa ń sú àwọn èwe máa ń jẹ́ kí wọ́n lo oògùn olóró. Ìwé The Romance of Risk—Why Teenagers Do the Things They Do sọ̀rọ̀ lórí sísú tí nǹkan máa ń sú wọn àti àìsí àbójútó òbí, ó sọ pé: “Bí ilé ìwé bá parí, àwọn ọmọ á wálé tí wọn ò sì ní rí àwọn òbí wọn. Kò yani lẹ́nu pé, ńṣe ni wọ́n máa ń dá wà tí wọn ò
sì fẹ́ bẹ́ẹ̀. Àwọn ọ̀rẹ́ á wá bá wọn, síbẹ̀ ó ṣì máa ń sú wọn lọ́pọ̀ ìgbà. Wọ́n á wo tẹlifíṣọ̀n àwòòwòtán tí wọ́n á sì máa gbọ́ orin tàbí kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá ohun tó máa múnú wọn dùn káàkiri orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Wọ́n lè tipa bẹ́ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mu sìgá, kí wọ́n máa lo oògùn olóró, kí wọ́n sì máa mu ọtí.”Michael, táa mẹ́nu kàn ṣáájú, sọ nípa àìsí àbójútó òbí pé: “Ìdílé wa jẹ́ aláyọ̀. A máa ń fara rora gan-an ni. Àmọ́ àwọn òbí mi méjèèjì ló ń lọ síbi iṣẹ́, kò sì sẹ́ni tó ń mójú tó wa látàárọ̀ ṣúlẹ̀. Bákan náà, àwọn òbí wa fún wa lómìnira tó pọ̀ gan-an ni. Kò sí ìbáwí. Àwọn òbí mi ò mọ̀ pé mo ń loògùn olóró.”
Bí ọ̀pọ̀ bá ti lè bẹ̀rẹ̀ sí loògùn olóró pẹ́nrẹ́n, wọn ò ní lè jáwọ́ mọ́ nítorí pé: Wọ́n máa ń gbádùn rẹ̀. Michael, tó ń fojoojúmọ́ kóògùn jẹ sọ bó ṣe máa ń rí, ó sọ pé: “Ńṣe ló máa ń dà bí pé mo wà ní párádísè. Gbogbo ohun tó ń dà mí lọ́kàn rú tẹ́lẹ̀ á ti fò lọ. Ohunkóhun kì í bà mí lẹ́rù. Ohun gbogbo kàn ń lọ ní mẹ̀lọmẹ̀lọ ni.”
Dick, tóun náà ń loògùn olóró tẹ́lẹ̀ ní Gúúsù Áfíríkà, ṣàlàyé bí igbó ṣe máa ń ṣe é nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí lò ó lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá, ó wí pé: “Mo kàn máa ń rẹ́rìn-ín wẹ̀sìwẹ̀sì ni. Gbogbo nǹkan ló máa ń pa mí lẹ́rìn-ín.”
Àwọn ìkìlọ̀ nípa ìpalára tóògùn olóró lè ṣe kì í ba àwọn èwe lẹ́rù. Ìwàa “kò-lè-ṣẹlẹ̀-sí-mi” ni wọ́n máa ń hù. Ìwé Talking With Your Teenager sọ ohun tó fà á táwọn ọ̀dọ́langba kì í fi í kọbi ara sí ìkìlọ̀ pé oògùn olóró ò dára fún ìlera, ó wí pé: “Bí ara wọn ṣe wà kanpe tókun sì ń bẹ nínú wọn kò jẹ́ kí wọ́n gbà pé ìlera wọn lè mẹ́hẹ. Èrò pé ‘kò sóhun tó lè ṣe mi’ yìí wọ́pọ̀ láàárín àwọn èwe gan-an. Ńṣe làwọn ọ̀dọ́langba máa ń ronú pé àwọn àgbàlagbà ló máa ń ní jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀fóró, àwọn ló ń mu ọtí nímukúmu, àwọn náà ló ń sọ oògùn olóró di bárakú, pé kì í ṣàwọn.” Bí oògùn líle tí wọ́n ń pè ní ecstasy ṣe gbòde kan fi hàn pé ọ̀pọ̀ ò tiẹ̀ mọ ewu tó wà nínú lílo oògùn olóró. Kí lewu ọ̀hún?
Oògùn Líle Ecstasy àti Ijó Rave
Oògùn líle MDMA tí wọ́n fi kẹ́míkà amphetamine ṣe, tí wọ́n tún ń pè ní ecstasy ni wọ́n sábàá máa ń lò níbi ijó àjómọ́jú tí wọ́n ń pè ní raves. Àwọn tó ń tà á máa ń fẹnu pọ́n ọn pé béèyàn bá lo oògùn lílé ecstasy, ńṣe ni inú rẹ̀ á máa dùn ṣìnkìn àti pé ó máa lágbára láti jó mọ́jú kẹlẹlẹ. Oògùn líle yìí máa ń jẹ́ káwọn oníjó ṣáà máa jó títí dìgbà tí “wọn ò ní lè ta pútú mọ́,” gẹ́gẹ́ bí ọ̀gbẹ́ni kan ṣe sọ. Ọ̀dọ́bìnrin kan ṣàlàyé bí oògùn líle ecstasy ṣe máa ń tan èèyàn, ó sọ pé: “Ọmọ ìka ẹsẹ̀ rẹ ló ti kọ́kọ́ máa bẹ̀rẹ̀ sí gbádùn mọ́ ẹ, á wá bẹ̀rẹ̀ sí
ṣe ọ́ wìnnìwìnnì táá sì máa dùn mọ́ ọ títí táá fi dé agbárí rẹ.”Ṣíṣe àyẹ̀wò ọpọlọ àwọn tó ń lo oògùn líle ecstasy déédéé ti fi hàn kedere pé kì í ṣe oògùn tí kì í pani lára táwọn tó ń tà á pè é ló jẹ́. Dájúdájú, ńṣe ni oògùn líle ecstasy máa ń ba àwọn iṣan inú ọpọlọ jẹ́. Irú jàǹbá bẹ́ẹ̀ sì lè má ní àtúnṣe. Bó bá yá, èyí lè yọrí sí àìfararọ tàbí iyè ríra. A gbọ́ pé àwọn kan lára àwọn tó ń lo oògùn líle ecstasy ti dèrò sàréè. Kò tán síbẹ̀ o, lára àwọn tó máa ń ta oògùn olóró máa ń po ecstasy pọ̀ mọ́ oògùn líle heroin káwọn oníbàárà wọn lè sọ ọ́ di bárakú.
Báwo Ló Ṣe Wọ́n Tó?
Bí oògùn olóró ṣe ń wọ ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè wìtìwìtì ti jẹ́ kí iye owó tí wọ́n ń tà á lọ sílẹ̀ gan-an. Lọ́nà kan, ìyípadà nínú ètò ìṣèlú àti ọrọ̀ ajé ló fa èyí. Àpẹẹrẹ kan ni ti Gúúsù Áfíríkà, níbi tí ìyípadà ètò òṣèlú ti mú kí ṣíṣòwò pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ṣeé ṣe. Èyí pẹ̀lú ṣíṣàì fọwọ́ dan-indan-in mú àbójútó ẹnubodè ti mú kí àwọn tí ń ṣòwò oògùn olóró pọ̀ sí i. Pẹ̀lú bí àìríṣẹ́ṣe ti wá ń pọ̀ sí i, ìdí títa oògùn olóró làìmọye èèyàn ti ń rówó. Oògùn olóró àti ìwà ọ̀daràn bíburú jáì sì rèé, ọmọ ìyá ni wọ́n. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn kan ṣe sọ, ńṣe làwọn ọlọ́pàá ń ṣọ́ àwọn ọmọdé tó wà láwọn ilé ìwé Gauteng, ní Gúúsù Áfíríkà lójú méjèèjì nítorí oògùn olóró, àwọn míì ò sì ju ọdún mẹ́tàlá péré lọ. Àwọn ilé ìwé bíi mélòó kan tiẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àyẹ̀wò fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn láti mọ̀ bóyá wọ́n ti ń lo oògùn olóró.
Kí Ni Kúlẹ̀kúlẹ̀ Ohun Tó Fà Á?
Ó hàn gbangba pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń mú káwọn èèyàn máa lo oògùn olóró. Àmọ́ gbogbo ìwọ̀nyí wulẹ̀ jẹ́ àmì ìṣòro ńlá kan ni, ìyẹn ohun tó fà á gan-an. Òǹkọ̀wé Ben Whitaker mẹ́nu ba èyí, ó sọ pé: “Bí lílo oògùn olóró lọ́wọ́ táa wà yìí ṣe ń gbalẹ̀ sí i jẹ́ àmì àìlera tó wà láwùjọ wa yàtọ̀ sí ìnìkanwà àti àìsírètí tó wà: bí kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀, kí ló fà á táa fi ń bá ọ̀pọ̀ lára àwọn táa ń wárí fún nídìí oògùn olóró dípò tí wọn ì bá fi yanjú ìṣòro tó wà ńlẹ̀?”
Òdodo ọ̀rọ̀ gbáà nìbéèrè yìí, torí ó jẹ́ ká mọ̀ pé àwùjọ wa tí kò mọ̀ ju ọrọ̀ lọ kì í pèsè àwọn ohun táa nílò ní ti ìmọ̀lára àti tẹ̀mí fún wa. Kódà ọ̀pọ̀ ìsìn ni kò lè pèsè àwọn nǹkan wọ̀nyẹn torí pé wọn kò yà sídìí ohun tó jẹ́ olórí ìṣòro ènìyàn.
Ká tó lè rí ojútùú sí ìṣòro oògùn olóró, a gbọ́dọ̀ wá kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó fà á láwàárí. Èyí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn gbajúgbajà máa ń polówó oògùn olóró bí ohun to dára nígbà míì
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Lílo oògùn olóró ló kúnnú orin òde òní fọ́fọ́
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Oògùn líle “ecstasy” sábàá máa ń wà ní agbo ijó “raves”
[Àwọn Credit Line]
Fọ́tò AP/Greg Smith
Gerald Nino/U.S. Customs