Ibi Gbogbo Ni Wọ́n Ti Ń Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́
Ibi Gbogbo Ni Wọ́n Ti Ń Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́
BAXTER, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, tó wà nílé ẹ̀kọ́ gíga máa ń fi gbogbo ọ̀sán Saturday rẹ̀ ṣe nǹkan alárinrin kan. Ó máa ń bẹ àwùjọ àwọn arúgbó kan wò nílé ìtọ́jú àwọn arúgbó, á feré dá wọn lára yá, á sì ní kí wọ́n máa kọrin tẹ̀ lé òun. Olùkọ́ Baxter sọ pé: “Ó máa ń dẹ́rìn-ín pa wọ́n, ó máa ń mórí wọn yá, ó sì ń fún wọn ní ìdùnnú nínú ìgbésí ayé wọn.” Lucille tó jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlọ́gọ́rin náà ń ṣe irú iṣẹ́ àánú bẹ́ẹ̀. Ó máa ń pín oúnjẹ fáwọn aláìní ó sì máa ń bẹ àwọn aláìsàn tí kò ní alábàárò wò láwọn ọsibítù. Ọ̀rẹ́ Lucille kan sọ pé: “Tó bá rí i pé ibì kan wà tí òun ti lè ṣèrànwọ́, á rí i pé òún débẹ̀.”
Ohun Tí Yíyọ̀ǹda Ara Ẹni Túmọ̀ Sí
Irú ọ̀nà ìgbésí ayé yìí, ìyẹn ‘Kéèyàn wà lárọ̀ọ́wọ́tó níbi tí wọ́n ti nílò ìrànwọ́’ jẹ́ ohun tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn káàkiri ayé nífẹ̀ẹ́ sí. Wọ́n ń ṣèrànwọ́ níbi iṣẹ́ ìkọ́lé àti ní ọ́fíìsì, ní iléeṣẹ́, ní ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó, ibùdó àwọn olùwá-ibi-ìsádi, ibùdó àwọn aláìrílégbé, iléeṣẹ́ panápaná, ibi táwọn èèyàn lè lọ
tí wọ́n bá níṣòro, ibi ààbò fáwọn ẹranko, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àní, kò síbi tí wọn kì í sí! Wọ́n ń lo òye iṣẹ́ tí wọ́n ní láti ṣe àwọn ohun tó bẹ̀rẹ̀ látorí bíbá àwọn èèyàn kọ́ àká dórí ṣíṣe ìkówójọ àti látorí kíkó àwọn ọmọ ọwọ́ tí wọ́n ti pa tì mọ́ra dórí títu àwọn tó wà lẹ́sẹ̀ kan ayé ẹsẹ̀ kan sàréè lára. Àwọn táa ń sọ̀rọ̀ wọn làwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni, ìyẹn àwọn tí ohun tí wọ́n ń ṣe ń mú àǹfààní wá fáwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́.Iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni ni wọ́n pè ní “níní èrò tó dára gan-an kéèyàn sì ṣiṣẹ́ lé e lórí.” Ó tún jẹ́ fífara ẹni jìn fún ète kan, fífi àwọn nǹkan kan du ara ẹni, ṣíṣe iṣẹ́ kan láìsí ìrètí ìsanpadà, àti ṣíṣàì dágunlá sí ìṣòro àwọn ẹlòmíràn. Àwọn méjì kan tí wọ́n ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ yìí sọ pé: “Iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni jẹ́ fífi ara wa jìn: èyí tó ní nínú lílo àkókò wa, lílo tapátẹsẹ̀ wa, èrò wa, àwọn ohun táa lè ṣe láti ran ẹlòmíràn lọ́wọ́, àtàwọn ọ̀nà táa mọ̀ láti fi yanjú ìṣòro títí kan ìmọ̀ iṣẹ́ táa dìídì kọ́.” Ó dùn mọ́ni pé, àwọn nǹkan táwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni ń ṣe yìí tún ń ṣàǹfààní fáwọn náà.—Wo àpótí náà, “Àwọn Olùyọ̀ǹda Ara Ẹni Pàápàá Ń Jàǹfààní.”
Wọ́n Ń Pọ̀ Sí I, Àmọ́ Ìṣòro Kò Dín Kù
Ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù èèyàn ni wọ́n fojú bù pé wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni, iye ọ̀hún sì ń pọ̀ sí i ni. Kathleen Behrens, olùdarí àgbà fún àjọ ìyọ̀ǹda ara ẹni kan tó ń jẹ́, New York Bìkítà sọ fún Jí! láìpẹ́ yìí pé: “Ńṣe lẹgbẹ́ wa túbọ̀ ń gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ sí i. Lọ́dún tó kọjá nìkan, ẹgbẹ̀rún márùn-ún àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tuntun ló dara pọ̀ mọ́ wa.” Nílẹ̀ Yúróòpù, ńṣe làwọn ẹgbẹ́ olùyọ̀ǹda ara ẹni náà ń ròkè sí i. Fún àpẹẹrẹ, ní ilẹ̀ Faransé, láti ogún ọdún sẹ́yìn ni iye àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni ti ń fi ìpín mẹ́fà nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ sí i lọ́dọọdún. Àmọ́ o, ohun táa torí ẹ̀ nílò àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni kò torí ẹ̀ dín kù. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ẹgbẹ́ Olùyọ̀ǹda Ara Ẹni ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè (àjọ kan tó wà lábẹ́ àjọ UN) sọ pé táa bá fojú wo ipò náà yíká ayé, “a nílò ìtìlẹyìn àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni lónìí ju ti ìgbàkígbà rí lọ.” Alábòójútó ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí kan sọ pé: “Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tó ń bá wa mójú tó ibí yìí.”
Síbẹ̀, ohun kan ṣì ń rúni lójú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ olùdarí, ọ̀gá ilé iṣẹ́, àtàwọn alábòójútó tó ń bá àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni ṣiṣẹ́ ló ń sọ pé “iyán wọn kò ṣe é kó kéré rárá,” ọ̀pọ̀ iṣẹ́ táwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni ń ṣe yìí làwọn èèyàn kò kà sí. Láti lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàtúnṣe ọ̀ràn yìí ni Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fi pinnu láti lo ọdún 2001 bí àkókò fún dídarí àfiyèsí sí àwọn òṣìṣẹ́ tó ń yọ̀ǹda ara wọn. Àpótí náà, “Àyájọ́ Ọdún Àwọn Olùyọ̀ǹda Ara Ẹni” sọ díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè retí pé kọ́wọ́ òun tẹ̀.
Ní báyìí ná, àwọn ìyípadà kan ń wáyé nínú iṣẹ́ yìí, èyí tó jẹ́ ìpèníjà fún àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni àtàwọn tó ń darí iṣẹ́ wọn. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ṣì wà káàkiri ayé tí wọ́n fẹ́ láti lo ara wọn fún àǹfààní àwọn ẹlòmíràn. Kí ló ń sún wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀? Kí ni wọ́n ń ṣàṣeparí rẹ̀? Báwo ni wọ́n sì ṣe lè nípa lórí ìgbésí ayé rẹ?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwọn Olùyọ̀ǹda Ara Ẹni Pàápàá Ń Jàǹfààní
Michael, ẹni tó máa ń yọ̀ǹda ara rẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, sọ pé: “Ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ ti ṣàǹfààní fún mi lọ́pọ̀lọpọ̀ àti lọ́nà jíjinlẹ̀, ó sì gbádùn mọ́ mi ju ohun tí mo lè rí nípa gbígbájúmọ́ kìkì iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ mi lọ.” Michael nìkan kọ́ o. Adarí àgbà fún Àwọn Olùyọ̀ǹda Ara Ẹni ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, Sharon Capeling-Alakija, sọ pé: “Jákèjádò ayé, àwọn èèyàn tó . . . yọ̀ọ̀da ara wọn mọ̀ gbangba pé, àǹfààní kékeré kọ́ làwọn ń jẹ látinú ohun tí wọ́n ń ṣe yìí.” Dókítà Douglas M. Lawson tó jẹ́ ògbógi nínú iṣẹ́ yíyọ̀ọ̀da ara ẹni sọ pé, àwọn olùwádìí ti rí i pé “ọ̀pọ̀ ìgbà ni yíyọ̀ọ̀da ara ẹni, àní fún kìkì wákàtí díẹ̀ péré máa ń mú ìrònú ẹnì kan àti ìṣesí rẹ̀ sáwọn èèyàn àti sí òun fúnra rẹ̀ sunwọ̀n sí i débi pé, wọ́n ti pe àbájáde yìí ní ‘Amárayágágá Fáwọn Olùyọ̀ǹda Ara Ẹni.’” Èyí kì í sì í ṣe ohun kan tó ń tán lára ẹni. Àwọn olùwádìí ní Yunifásítì Cornell ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà wádìí àwùjọ èèyàn kan fún ohun tó lé lọ́gbọ̀n ọdún wọ́n sì rí i pé “àwọn tó ń yọ̀ǹda ara wọn ló láyọ̀ jù tí ìlera wọn sì dára ju ti àwọn tí kì í ṣe bẹ́ẹ̀ lọ.” Abájọ, tí Bíbélì fi sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35; Òwe 11:25.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Àyájọ́ Ọdún Àwọn Olùyọ̀ǹda Ara Ẹni
Ní November 20, 1997, Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Gíga Jù Lọ fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè kéde ọdún 2001 bí “Àyájọ́ Ọdún Àwọn Olùyọ̀ǹda Ara Ẹni,” (IYV 2001). Níbàámu pẹ̀lú ohun tí Ẹgbẹ́ náà sọ, àwọn nǹkan mẹ́rin kan wà tí wọ́n fẹ́ kí ọwọ́ wọn tẹ̀ láàárín ọdún yìí.
Títúbọ̀ mọ̀ wọ́n sí i Wọ́n rọ àwọn ìjọba láti máa fi ìmọrírì hàn fún àwọn tó ń yọ̀ǹda ara wọn nípa kíkíyèsí àwọn àṣeyọrí wọn àti ṣíṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ kí wọ́n sì máa fi ẹ̀bùn dá àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tí wọ́n bá dáńgájíá lọ́lá.
Kí òfin ṣe kóríyá fún iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni Gbogbo orílẹ̀-èdè ni wọ́n rọ̀ láti fún ẹ̀mí ìyọ̀ǹda ara ẹni níṣìírí, fún àpẹẹrẹ, kí wọ́n tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni bí àfidípò fún iṣẹ́ ológun tàbí kí wọ́n ní káwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni yéé san oríṣi àwọn owó orí kan.
Gbígbé wọn jáde nínú ìròyìn Wọ́n rọ àwọn iléeṣẹ́ tó ń gbé ìròyìn jáde láti túbọ̀ ṣèrànwọ́ ní pípolongo àṣeyọrí àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n á lè máa gbé àwọn ohun tí wọ́n ń ṣe jáde léraléra, “tí kò sì ní ṣẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ pé àdúgbò kọ̀ọ̀kan ni yóò máa wá ọ̀nà bí wọ́n á ṣe ṣèyẹn.”
Ìgbélárugẹ Wọ́n rọ àwọn àjọ tó wà fún iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni láti ṣètò àwọn ìpàtẹ tó máa jẹ́ kí àwọn ará ìlú mọ̀ nípa àwọn àǹfààní tí àwùjọ ń jẹ̀gbádùn rẹ̀ látinú iṣẹ́ táwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni ń ṣe.
Ìrètí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀ Èdè ni pé, Àyájọ́ Ọdún Àwọn Olùyọ̀ǹda Ara Ẹni ti ọdún 2001 yóò túbọ̀ sún àwọn èèyàn láti béèrè fún ìrànlọ́wọ́ àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni, yóò jẹ́ káwọn èèyàn túbọ̀ mú ara wọn wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni, pé yóò yọrí sí ìpèsè owó àtàwọn ohun mìíràn táwọn àjọ olùyọ̀ǹda ara ẹni nílò láti kójú àwọn ìṣòro àwùjọ tó túbọ̀ ń ga sí i. Orílẹ̀-èdè mẹ́tàlélọ́gọ́fà ló ti dara pọ̀ báyìí ní ṣíṣe onígbọ̀wọ́ àwọn ohun tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fẹ́ kọ́wọ́ òun tẹ̀ yìí.