Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Ǹjẹ́ O Mọ̀?
(A lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí, a sì kọ àwọn ìdáhùn náà ní kíkún sí ojú ìwé 18. Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìtẹ̀jáde “Insight on the Scriptures,” tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.)
1. Gẹ́gẹ́ bí Pétérù ṣe sọ, àwọn ohun wo ló “ń bá ìforígbárí nìṣó lòdì sí ọkàn”? (1 Pétérù 2:11)
2. Lẹ́yìn tí orí Nebukadinésárì Ọba wálé, kí ló sọ nípa Jèhófà? (Dáníẹ́lì 4:34, 35)
3. Kí ló dé tí Jésù ‘kò fi jẹ́ kí ẹnikẹ́ni gbé nǹkan èlò la tẹ́ńpìlì kọjá’? (Máàkù 11:16)
4. Ọ̀rọ̀ ìwọ̀sí wo ni Senakéríbù Ọba ti Ásíríà sọ sí Hesekáyà Ọba ti Júdà? (2 Àwọn Ọba 18:23)
5. Dípò kéèyàn kàn máa búra bó ṣe wù ú, kí ni Jésù sọ pé ó dáa láti ṣe? (Mátíù 5:37)
6. Kí ni Òfin Mósè ní kí wọ́n ṣe fún ẹni tó bá gbé sísin ọlọ́run mìíràn lárugẹ, kódà kí ẹni náà jẹ́ ìbátan tímọ́tímọ́? (Diutarónómì 13:6-10)
7. Èèyàn olódodo mélòó ni Jèhófà ṣèlérí fún Ábúráhámù pé bí òun bá pàpà rí òun kò ní torí wọn pa Sódómù àti Gòmórà run? (Jẹ́nẹ́sísì 18:32)
8. Báwo ni Sọ́ọ̀lù Ọba ṣe kú? (1 Sámúẹ́lì 31:3, 4)
9. Kí ló mú kí Úsà rí ikú he nígbà tó di Àpótí mú kó má bàa dojú dé? (Númérì 4:15, 19, 20; 2 Sámúẹ́lì 6:6, 7)
10. Ìlú àwọn ará Makedóníà wo ni wọ́n ń fi orúkọ ọlọ́run oòrùn àwọn ará Gíríìkì pè? (Ìṣe 17:1)
11. Gbólóhùn wo nínú Bíbélì ló sọ nípa ọ̀nà ìlà oòrùn? (Ìṣípayá 16:12)
12. Ọdún mélòó ni Dáfídì fi jọba lórí Ísírẹ́lì?
13. Ibo ni Jésù ti ń sinmi nígbà tó fọ̀rọ̀ jomitoro ọ̀rọ̀ pẹ̀lú obìnrin ará Samáríà náà? (Jòhánù 4:6)
14. Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì púpọ̀ láti “máa yẹ àwọn òfìfo ọ̀rọ̀ sílẹ̀, tí ó máa ń fi àìmọ́ ba ohun mímọ́ jẹ́”? (2 Tímótì 2:16)
15. Kí lorúkọ àwọn ọmọkùnrin mẹ́ta tí Nóà bí? (Jẹ́nẹ́sísì 10:1)
16. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ṣe fi hàn, èwo nínú àwọn ọmọ Gádì akíkanjú mọ́kànlá “tí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ sí ìhà ọ̀dọ̀ Dáfídì” nínú aginjù ni a sọ pé ẹgbẹ́ “ẹgbẹ̀rún” ní í ṣe? (1 Kíróníkà 12:8-14)
17. Ọ̀rọ̀ ẹ̀dùn wo ni Jésù sọ nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ já a kulẹ̀ nígbà tí wọ́n sùn lọ ní òru ọjọ́ tí a dà á? (Máàkù 14:38)
18. Ìlà ìdílé ọba Ísírẹ́lì wo ni Jésù ti ṣẹ̀ wá? (Róòmù 1:3)
19. Àwọn obìnrin mẹ́rin wo la sọ pé wọ́n lọ sí ibojì Jésù láti fi àwọn èròjà atasánsán pa á lára? (Máàkù 16:1; Lúùkù 24:10)
Ìdáhùn Sáwọn Ìbéèrè
1. “Àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ara”
2. Agbára ìṣàkóso rẹ̀ jẹ́ èyí tí ó wà “fún àkókò tí ó lọ kánrin,” ẹnikẹ́ni kò sì lè dí i lọ́wọ́ láti má ṣe ohun tó jẹ́ ète rẹ̀
3. Nítorí pé wọ́n máa ń fi àgbàlá tẹ́ńpìlì náà ṣe ọ̀nà ẹ̀bùrú tí wọ́n ń gbà lọ sáwọn àdúgbò mìíràn nínú ìlú náà
4. Pé kó gba ẹgbàá ẹṣin, kí wọ́n sì rí i bóyá yóò lè fi àwọn agẹṣin sórí wọn
5. “Kí ọ̀rọ̀ yín Bẹ́ẹ̀ ni sáà túmọ̀ sí Bẹ́ẹ̀ ni, Bẹ́ẹ̀ kọ́ yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́”
6. Kí wọ́n pa á
7. Mẹ́wàá
8. Nígbà tí ọfà àwọn Filísínì ti dọ́gbẹ́ sí i lára yánna-yànna, ó mọ̀ọ́mọ̀ ṣubú lórí idà òun fúnra rẹ̀ ó sì kú
9. Òfin Ọlọ́run ni pé, ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, ẹni tí a kò yàn láti fọwọ́ kan Àpótí náà kò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kàn án
10. Apolóníà
11. “Láti ibi yíyọ oòrùn”
12. Ogójì
13. Níbi ìsun omi Jákọ́bù
14. “Wọn yóò tẹ̀ síwájú sí àìṣèfẹ́ Ọlọ́run síwájú àti síwájú”
15. Ṣémù, Hámù àti Jáfẹ́tì
16. Esérì
17. “Ní tòótọ́, ẹ̀mí ń háragàgà, ṣùgbọ́n ẹran ara ṣe aláìlera”
18. Dáfídì
19. Màríà Magidalénì, Sàlómẹ̀, Jòánà àti Màríà ìyá Jákọ́bù