Kí Ló Dé Táwọn Èèyàn Ń Fi Àwọn Ẹ̀sìn Tó Ti Wà Látayébáyé Sílẹ̀?
Kí Ló Dé Táwọn Èèyàn Ń Fi Àwọn Ẹ̀sìn Tó Ti Wà Látayébáyé Sílẹ̀?
ÀWỌN ÌSÌN tó sọ pé orí ohun tí Jésù fi kọ́ni làwọn gbé ẹ̀kọ́ àwọn kà ní ọmọ ìjọ tó lé ní bílíọ̀nù kan ààbọ̀. Ẹ̀sìn Kristẹni la gbọ́ pé ó tóbi jù lọ lágbàáyé, kódà wọ́n pọ̀ ju àwọn ìsìn gbígbajúmọ̀ bíi Búdà, Híńdù àti Ìsìláàmù lọ. Àmọ́, ìròyìn fi hàn pé àwọn èèyàn ò kà á sí mọ́ ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè tí wọn kì í fi ẹ̀sìn Kristi ṣeré tẹlẹ̀.
Onírúurú èèyàn láti àwùjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló ń pa ṣọ́ọ̀ṣì wọn tì. Ronald F. Inglehart, olùwádìí ní Yunifásítì Michigan àti olùdarí fún Wíwádìí Bí Àwọn Èèyàn Ṣe Ń Hùwà Ọmọlúwàbí Sí Láyé sọ pé, ìsìn kò já mọ́ nǹkan kan mọ́ fún àwọn èèyàn tó ń gbé láwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà. Ìwé ìròyìn Bible Review fa ọ̀rọ̀ ọ̀gbẹ́ni yìí yọ pé: “Kì í ṣe pé lílọ sí ṣọ́ọ̀ṣì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ lọ sílẹ̀ lọ́nà tó bùáyà nìkan ni, àmọ́ àwọn orílẹ̀-èdè Látìn Amẹ́ríkà ló tún wá ń rán àwọn míṣọ́nnárì jáde báyìí láti lọ ṣe iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà fún àwọn tó là wọ́n lójú.” Ó sọ pé kàyéfì ńlá ló jẹ́ pé “ìsìn kò rọ́wọ́ mú mọ́” ní àwọn orílẹ̀-èdè kan lápá àríwá ilẹ̀ Yúróòpù. Ní Norway àti Denmark, kìkì ìdá márùn-ún nínú
ọ̀gọ́rùn-ún lára àwọn tó ń gbé ibẹ̀ ló ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì déédéé. Ní Sweden, ọ̀rọ̀ tún burú jùyẹn lọ, ìdá mẹ́rin péré nínú ọgọ́rùn-ún ló máa ń lọ déédéé nígbà tí ti Rọ́ṣíà sì jẹ́ kìkì ìdá méjì nínú ọgọ́rùn-ún.Àwọn ìròyìn tó wá láti orílẹ̀-èdè Jámánì fi hàn pé láàárín ọdún 1984 sí 1993, àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì déédéé lọ sílẹ̀ látorí ìdá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ó lé díẹ̀ nínú ọgọ́rùn-ún sí ìdá mọ́kàndínlógún. Nígbà tó fi máa di ọdún 1992, kìkì ìdá mẹ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì ló ń lọ sí ìsìn Sunday déédéé. Lọ́dún 1999, ìwé ìròyìn Christianity Today sọ pé: “Ẹyọ kan péré nínú ọmọ ilẹ̀ Jámánì mẹ́wàá ló kù tí kì í pa ṣọ́ọ̀ṣì jẹ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.”
Nípa bí àwọn onígbàgbọ́ ṣe túbọ̀ ń dín kù nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ìwé ìròyìn The Guardian sọ pé: “Kò tíì sígbà kan tó burú fún ẹ̀sìn Kristẹni tó ti àkókò yìí rí.” Àpilẹ̀kọ náà sọ pé: “Ọdún 1950 sí ọdún 2000 jẹ́ àádọ́ta ọdún tó tíì burú jù lọ fún àwọn àlùfáà àtàwọn aláṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì.” Nígbà tí ìwé ìròyìn náà ń tọ́ka sí àkànṣe ìròyìn kan tó dá lórí bí ọ̀ràn ìsìn ti rí nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ó fi hàn pé kì í ṣe àwọn ọ̀dọ́ nìkan ni kò nígbàgbọ́ nínú ìsìn mọ́ o, ó kan àwọn arúgbó pàápàá. Ó sọ pé: “Báwọn àgbàlagbà ṣe ń dàgbà sí i ni ìgbàgbọ́ wọn nínú Ọlọ́run ń pòórá. Ìwádìí tuntun ò ní pẹ́ fi hàn pé lóòótọ́ lọ̀ràn yìí rí bẹ́ẹ̀ yóò sì da jìnnìjìnnì bo àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tí ìṣòro ti bá tẹ́lẹ̀, tó jẹ́ pé títí di àkókò yìí, wọ́n ṣì ń wo àwọn àgbàlagbà bí òpómúléró fún àwọn ìjọ wọn tó ń fi ojoojúmọ́ dín kù.”
Bákan náà lọ̀rọ̀ ṣe rí láwọn ilẹ̀ míì yàtọ̀ sáwọn ilẹ̀ Yúróòpù o. Bí àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn ilẹ̀ Kánádà náà Alberta Report, sọ pé “àwọn èèyàn ò nígbàgbọ́ mọ́ nínú ọ̀ràn ẹ̀sìn àti ìjọsìn” ní ilẹ̀ Kánádà. Ó tún sọ pé “ìdámẹ́ta àwọn ọmọ ilẹ̀ Kánádà ló tẹ́ lọ́rùn kí wọ́n tẹ̀ lé èrò ọkàn wọn nípa Ọlọ́run ju kí wọ́n tẹ̀ lé ìgbàgbọ́ kan pàtó tí ẹ̀sìn là kalẹ̀.”
Ohun tó ń ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn ni pé, pẹ̀lú bí wọ́n ṣe ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì tó, kò ṣe wọ́n bí ẹni pé wọ́n ń sún mọ́ Ọlọ́run sí i tàbí pé ìmọ̀ wọn nípa tẹ̀mí ń pọ̀ sí i. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Maclean ilẹ̀ Kánádà ṣe sọ, àwọn ẹlẹ́sìn Júù àti ẹlẹ́sìn Kátólíìkì tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò níbi ìpàdé àdúrà ìsìn Híńdù tó wáyé lórí àwọn òkè Himalaya sọ èrò ọkàn wọn jáde. Wọ́n sọ pé: “Àwọn ètò ìsìn ò mórí wa yá mọ́, kò tiẹ̀ jẹ́ nǹkankan sí wa mọ́.” Kódà, lẹ́yìn táwọn kan ti fi tinútinú lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì fún ọ̀pọ̀ ọdún, wọ́n rí i tí wọ́n ṣì ń bi ara wọn pé, ‘Kí ni mo rí kọ́ látọjọ́ tí mo ti ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ná? Ṣé mo torí ẹ̀ sún mọ́ Ọlọ́run sí i?’ Abájọ tọ́rọ̀ wọn ò fi yàtọ̀ sí ohun tí òǹkọ̀wé Gregg Easterbrook kọ pé: “Ní àwọn ilẹ̀ Ìwọ̀ Oòrùn ayé, òṣì tẹ̀mí ló rọ́pò òṣì tara. Nǹkan tẹ̀mí ni olórí àìní wọn lákòókò tá a wà yìí.”
Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè wà táwọn èèyàn ti máa ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì dáadáa. Àmọ́, pé wọ́n ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì kò fìgbà gbogbo túmọ̀ sí pé wọ́n ń fi tinútinú tẹ̀ lé ohun tí wọ́n ń kọ́ níbẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn ilẹ̀ Ọsirélíà náà The Age sọ pé, láwọn ilẹ̀ Ìwọ̀ Oòrùn ayé, “ńṣe ni iye àwọn Kristẹni tó ń fi ohun tí ìsìn wọn ń kọ́ wọn ṣèwà hù ń lọ sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ ibi nílẹ̀ Áfíríkà, Éṣíà àti Látìn Amẹ́ríkà ló sì jẹ́ pé ńṣe làwọn èèyàn ń fi ẹ̀sìn Kristẹni bojú láti lè máa bá ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà àti iṣẹ́ òkùnkùn wọn lọ. Àwọn ìwà wọ̀nyí kò bá ohun tí ẹ̀sìn Kristẹni fi kọ́ni mu rárá, ó tiẹ̀ máa ń ta kò ó lọ́pọ̀ ìgbà, ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn sì ni ṣọ́ọ̀ṣì ti sọ pé òun ò ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú wọn.”
Kí ló tiẹ̀ ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn, àtọmọdé àtàgbà máa fi ṣọ́ọ̀ṣì wọn sílẹ̀? Kókó pàtàkì kan tó jọ pé ó fà á ni bí ọwọ́ àwọn èèyàn ò ṣe tẹ ohun tí wọ́n ń fẹ́.
Àkọsílẹ̀ Burúkú Tí Ìsìn Ní
Ìwé ìròyìn The Guardian sọ ọ̀rọ̀ tó wà nísàlẹ̀ yìí pé: “Àkọsílẹ̀ tí ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì ní kò dára rárá, nípa bó ṣe lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn Ìjọba Aláṣẹ Oníkùmọ̀ jálẹ̀ gbogbo ọ̀rúndún ogún. Látorí sàdáńkátà tó ṣe fún Ọ̀gágun Franco lẹ́yìn ogún abẹ́lé ilẹ̀ Sípéènì títí dórí akitiyan rẹ̀ ẹnu àìpẹ́ yìí tó fi ṣètìlẹyìn fún Ọ̀gágun Pinochet.” Ìwé ìròyìn Guardian tún sọ pé, Póòpù Pius Kejìlá tó wà lórí oyè lásìkò Ogun Àgbáyé Kejì “fi tayọ̀tayọ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú [Hitler] àmọ́ ó kọ̀ láti ṣe àwọn nǹkan tó ronú pé ó lè kó ìtìjú bá òun, irú bíi bíbu ẹnu àtẹ́ lu Ìpakúpa Rẹpẹtẹ tó wáyé lásìkò náà.”
Ìwé ìròyìn The Age ní tiẹ̀ sọ pé: “Ohun táwọn aṣáájú ẹ̀sìn Kristẹni máa ń sọ lọ́pọ̀ ìgbà kì í kọjá orí ahọ́n wọn. Àwọn ẹlẹ́sìn Kristi kò tíì rí oògùn àlàáfíà àti ìṣọ̀kan ṣe láàárín ara tiwọn gan-an alára. . . . Ọ̀pọ̀ ogun tí wọ́n ń jà láti fi jalè tàbí láti fi gba ilẹ̀ tí wọ́n á sì máa dá ara wọn láre pé àwọ́n
fi ń jèrè ọkàn fún Kristi ni jẹ́ ẹ̀rí pé ọwọ́ wọn ò tíì tẹ àlàáfíà àti ìṣọ̀kan. Ẹ̀sìn Kristẹni lè máa tẹnu mọ́ àwọn ànímọ́ gbígbayì bí ìgbàgbọ́, ìrètí àti ìfẹ́ lóòótọ́. Àmọ́ àwọn Kristẹni tó ń fẹ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ìwà wọn kò yàtọ̀ sí tàwọn tí kì í ṣe ẹlẹ́sìn Kristẹni tó bá di ọ̀ràn kéèyàn fọkàn tán ẹlòmíràn, kéèyàn ní ìrètí tàbí kó láàánú ẹlòmíràn lójú. . . . Orílẹ̀-èdè ẹlẹ́sìn Kristi ló wà lẹ́yìn Ìpakúpa Rẹpẹtẹ ìgbà ìjọba Násì, orílẹ̀-èdè mìíràn tó tún jẹ́ ẹlẹ́sìn Kristi ló lọ rọ̀jò àdó olóró tí ń kó jìnnìjìnnì báni sórí ilẹ̀ Japan nígbà ogun.”Àwọn kan lè máa sọ pé ọjọ́ pẹ́ tí ìsìn Kristẹni ti mú àwọn ànímọ́ dídára kan ní ọ̀kúnkúndùn, irú bíi mímọ nǹkan lò lọ́nà tó mọ́gbọ́n dání, fífàyà rán ìṣòro, níní ìkóra-ẹni-níjàánu, àti àìṣègbè. Àmọ́ ìwé ìròyìn The Age sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn Kristẹni ní ilẹ̀ Yúróòpù, Àríwá Amẹ́ríkà àti Ọsirélíà ti máa ń mú ju ohun tó jẹ́ ẹ̀tọ́ wọn nínú àwọn nǹkan àlùmọ́ọ́nì Ilẹ̀ Ayé. Bákan náà, wọn ò tíì jáwọ́ nínú kíkó àwọn orílẹ̀-èdè tí kò lágbára tó wọn nífà, níni wọ́n lára àti bíba àyíká wọn jẹ́ nítorí kí wọ́n lè tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn.”
Nígbà tí ìwé ìròyìn The Age, ń sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la ìsìn Kristẹni, ó sọ pé: “Láìjẹ́ pé ètò kan tó ní láárí tó sì múná dóko bá wà, kí ẹ̀sìn Kristẹni má retí pé ọwọ́ àwọn á tún padà tẹ irú agbára àti ipò tí wọ́n dì mú láwọn ọ̀rúndún tó kọjá. Èyí lè jẹ́ fún ire wọn, ó sì lè máà jẹ́ bẹ́ẹ̀, ó sinmi lórí ojú tí ẹnì kọ̀ọ̀kan fi wò ó. Àmọ́ ohun tó dájú ni pé, ohun tí ẹ̀sìn Kristẹni máa dojú kọ láwọn ọdún tó ń bẹ níwájú nìyẹn.”
Nítorí bí ètò ẹ̀sìn ti ṣe dìdàkudà yìí, ọ̀pọ̀ ló ń kúrò nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó ti wà látọdúnmọ́dún. Àmọ́ ṣé inú àwọn ìsìn tí wọ́n tún kọjá sí pèsè ohun tí wọ́n ń wá fún wọn? Ṣé ìyẹn ni ojútùú sí ìṣòro wọn?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ọ̀pọ̀ ló ti kúrò nínú àwọn ẹ̀sìn tó ti wà látọdúnmọ́dún nítorí ipa tí wọ́n ń kó nínú ogun àti nínú àwọn ètò ìṣèlú aninilára
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ọ̀pọ̀ èèyàn rí i pé àwọn ààtò ìsìn aláṣerégèé kò pèsè ohun tí àwọn nílò nípa tẹ̀mí
[Credit Line]
fọ́tò: age fotostock