Ohun Kan Tó Jẹ́ Àdámọ́ Gbogbo Èèyàn
Ohun Kan Tó Jẹ́ Àdámọ́ Gbogbo Èèyàn
KÒṢEÉMÁNÌÍ LOÚNJẸ. Omi ò ṣe é bá ṣọ̀tá. Atẹ́gùn ò ṣe é bá yodì. Ibùgbé ṣe kókó, o sì gbọ́dọ̀ níbi tí wàá máa forí pa mọ́ sí nítorí oòrùn àti òjò. Àwa èèyàn nìkan kọ́ la nílò àwọn nǹkan wọ̀nyí, àìmọye àwọn ohun abẹ̀mí mìíràn tó ń gbé lórí ilẹ̀ ayé náà nílò wọn. Àmọ́ ohun kan wà tó jẹ́ pé èèyàn nìkan ló nílò rẹ̀. Kí lohun náà?
Onímọ̀ nípa àjọṣe ẹ̀dá, Reginald W. Bibby tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Kánádà kọ̀wé pé: “Àwọn ohun kan wà táwọn èèyàn nílò tó jẹ́ pé ìsìn nìkan ló lè pèsè wọn.” Ìwé ìròyìn àtìgbàdégbà náà, American Sociological Review sì sọ nínú àpilẹ̀kọ kan tó gbé jáde nínú ìtẹ̀jáde rẹ̀ ti February 2000 pé: “Ó jọ pé nínífẹ̀ẹ́ àwọn nǹkan tẹ̀mí kò lè kúrò nínú ìrònú ènìyàn láéláé.”
Òdodo ọ̀rọ̀, kò sígbà kankan nínú ìtàn tí ìfẹ́ láti jọ́sìn kì í sí lọ́kàn ọmọ ẹ̀dá. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, ìsìn tó lérò lẹ́yìn ni ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn máa ń ṣe. Àmọ́ nǹkan ti ń yí padà o. Ní ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tó ti rọ́wọ́ mú láyé, irú bíi ní Àríwá Amẹ́ríkà àti Àríwá Yúróòpù, ńṣe làwọn tó ń pa ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n ń lọ tẹ́lẹ̀ tì ń pọ̀ sí i. Ṣé àmì pé ìsìn ti n di ohun ìgbàgbé lèyí jẹ́ ni? Ọ̀rọ̀ ò kúkú rí bẹ́ẹ̀.
Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Sweden náà, Svenska Dagbladet sọ pé: “Ariwo táwọn èèyàn ń pa pé ìsìn ti ń di ohun ìgbàgbé ti pọ̀ jù.” Nígbà náà, kí ni wọ́n wá ń fi rọ́pò àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó ti wà látayébáyé? Ìwé ìròyìn náà ń bá a lọ pé: “Nǹkan tuntun tó ń ṣẹlẹ̀ báyìí ni pé, a kì í dara pọ̀ mọ́ ṣọ́ọ̀ṣì kan pàtó mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, a lè yan èyí tó bá wù wá nínú ìgbàgbọ́ àwọn ìsìn tó pọ̀ bí ilẹ̀ bí ẹní báyìí ká sì wá fi tiwa kún un. . . . Èyí lè ní nínú, gbígbàgbọ́ pé gíláàsì aláràbarà kan tàbí aṣọ gbàgìẹ̀ táwọn ẹlẹ́sìn Búdà tó jẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé ń wọ̀ lágbára láti woni sàn. Tí àwọn ohun tó o gbà gbọ́ yìí bá wá sú ọ, o tún lè yan àwọn mìíràn láìsí wàhálà.”
Àwọn olùwádìí nípa àjọṣe ẹ̀dá pe èrò yìí ní “àdábọwọ́ ẹ̀sìn” tàbí “ẹ̀sìn téèyàn kì í fojú rí.” Bibby, onímọ̀ nípa àjọṣe ẹ̀dá tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níbẹ̀rẹ̀ mú gbólóhùn kan jáde tó túmọ̀ sí “bó ti wuni là á ṣègbàgbọ́ ẹni.” Àwọn kan tún máa ń pe irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ ni “ṣe é bó bá ti wù ẹ́.” Láwọn ilẹ̀ kan tí wọ́n mọ̀ mọ́ ẹ̀sìn Kristi tipẹ́, ẹ̀sìn tó tóbi jù lọ níbẹ̀ báyìí ni èyí tá a lè sọ pé ohun tó wu àwọn èèyàn ni wọ́n ń gbà gbọ́.
Wo ohun tí ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní orílẹ̀-èdè Sweden gbé jáde, níbi tí ọ̀rọ̀ ìsìn ò ti jẹ́ nǹkankan lójú àwọn èèyàn. Ìwádìí náà fi hàn pé èèyàn méjì nínú mẹ́ta ló ka ara wọn sí ẹlẹ́sìn Kristi àmọ́ “lọ́nà tó wù wọ́n.” Díẹ̀ lára wọn sọ pé: “Ní tèmi, ojú tí mo fi ń wo ẹ̀sìn Kristẹni yàtọ̀,” “kò sígbà tí mo lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì tí ara mi ń balẹ̀,” “kì í wù mí kí n lọ máa tẹ́tí sí àwọn àlùfáà ní ṣọ́ọ̀ṣì,” “ó tẹ́ mi lọ́rùn kí n kúkú wọnú yàrá mi lọ kí n sì gbàdúrà fúnra mi.” Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn yìí ló sì gbà gbọ́ nínú àtúnwáyé tàbí kádàrá. Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wọn sọ pé àwọn gbà gbọ́ pé ó ṣeé ṣe kí ohun kan tó dà bí Ọlọ́run tàbí agbára kan wà níbì kan àmọ́ àwọn ò lè ṣàlàyé rẹ̀.
Ìwádìí mìíràn fi hàn pé àkókò tí ọ̀pọ̀ èèyàn bá ń najú jáde, tí wọ́n ń gbádùn àwọn ìṣẹ̀dá tó wà láyìíká wọn ni wọ́n máa ń ronú nípa ìsìn. Obìnrin àgbẹ̀ kan tí kò dàgbà púpọ̀ sọ pé: “Mo ronú pé ìgbà téèyàn bá wà ní àrọko lèèyàn máa ń ráyè sún mọ́ Ọlọ́run jù.” Ẹlòmíràn tí wọ́n tún fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò tí kò ka ara rẹ̀ sí ẹlẹ́sìn kankan sọ pé: “Nígbàkigbà tí mo bá wà ní àrọko, ńṣe ló máa ń dà bíi pé mo wà nínú tẹ́ńpìlì gìrìwò kan. . . . Ìkáwọ́ ta ló sì wà, mi ò mọ̀, àmọ́ mo máa ń nímọ̀lára pé ó wà níkàáwọ́ ẹnì kan.” Àwọn kan sọ pé ohun mímọ́, ohun ọlọ́wọ̀ làwọn àrọko jẹ́, wọ́n ní ńṣe ló dà bí Ọlọ́run, ó sì máa ń mú àwọn kún fún ẹ̀rù. Wọ́n ní ìgbàkigbà tí àwọn bá ti wà níbẹ̀, àwọn máa ń ní àkọ̀tun agbára, àlàáfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn. Nígbà tí olùfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan ń ṣàkópọ̀ gbogbo ohun táwọn èèyàn sọ, ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Inú igbó ni Ọlọ́run wà báyìí o.”
Irú èrò yìí kò ṣọ̀wọ́n lọ́pọ̀ ibi láyé. Thomas Luckmann, ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà kan tó jẹ́ ògbógi nínú ìmọ̀ nípa báwọn èèyàn ṣe ń ṣe ẹ̀sìn sọ pé, láwọn orílẹ̀-èdè tó ti rọ́wọ́ mú, àwọn èèyàn ti ń pa ẹ̀sìn lílọ sí ṣọ́ọ̀ṣì tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. “Ìsìn gbẹ̀fẹ́” ló kù tí wọ́n ń ṣe. Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé, fúnra ẹnì kan ló ń gbé èrò rẹ̀ nípa ìgbésí ayé kalẹ̀, nípa pípa àwọn èrò tó ní í ṣe pẹ̀lú Ọlọ́run pọ̀ mọ́ àwọn ìgbàgbọ́ tó fúnra rẹ̀ gbé kalẹ̀.
O lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘Ṣé kì í ṣe pé àwọn ìsìn àtàwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó ti wà látayébáyé fẹ́ di aláìjámọ́ nǹkankan mọ́ báyìí? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kí ló fà á?’ A ó dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Nígbà tí olùwádìí kan ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó gbòde báyìí, tó jẹ́ pé àrọko ló kù táwọn èèyàn ń wá nǹkan tẹ̀mí lọ, ó parí ọ̀rọ̀ pé: “Inú igbó ni Ọlọ́run wà báyìí o”