Ǹjẹ́ Ó Yẹ Káwọn Kristẹni Máa Wàásù Fáwọn Ẹlòmíràn?
Ojú Ìwòye Bíbélì
Ǹjẹ́ Ó Yẹ Káwọn Kristẹni Máa Wàásù Fáwọn Ẹlòmíràn?
ÓṢEÉ ṣe kí àṣà ìbílẹ̀ rẹ tàbí bí wọ́n ṣe tọ́ ọ dàgbà kà á léèwọ̀ pé èèyàn ò gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ ẹ̀sìn níbòmíràn yàtọ̀ sí láàárín ìdílé tàbí nínú ṣọ́ọ̀ṣì. Èyí lè mú kí inú bí ọ bí ẹnì kan bá ṣàdédé wá sílé rẹ tòun ti Bíbélì lọ́wọ́. Ní ti àwọn mìíràn, ohun tó mú kí wọ́n ní irú èrò yìí ni ìwà ipá táwọn ẹlẹ́sìn kan ti hù, tí wọ́n ń fi ẹ̀sìn bojú pé ńṣe làwọn fẹ́ fún àwọn èèyàn ní ìgbàlà.
Ìtàn ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè fi hàn bí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn ṣe di ẹlẹ́sìn Kristi ọ̀sán gangan. Kì í kúkú ṣe pé ńṣe ni wọ́n fẹ́ràn Kristi ọ̀hún, àmọ́ ẹ̀rù tó ń bà wọ́n pé táwọn ò bá ṣe bẹ́ẹ̀ àwọn èèyàn lè gbẹ̀mí àwọn ló fà á. Àwọn mìíràn sì rèé, dípò kí wọ́n ṣe ẹ̀sìn àwọn tó ń hàn wọ́n léèmọ̀ ńṣe ni wọ́n á lọ sá pa mọ́, wọ́n á sá kúrò nílé, wọ́n á sá kúrò ní orílẹ̀-èdè wọn, tàbí kí wọ́n tiẹ̀ pa wọ́n pàápàá nítorí ńṣe ni wọ́n máa ń gbé àwọn mìíràn kọ́gi tí wọ́n á sì dáná sun wọ́n.
Àwọn ọ̀rọ̀ Bíbélì tí Ọlọ́run mí sí kò fọwọ́ sí mímú àwọn èèyàn yí ẹ̀sìn wọn padà lápàpàǹdodo bí irú èyí. Àmọ́ síbẹ̀, ṣé èèwọ̀ wá ni pé kéèyàn sọ nípa ẹ̀sìn rẹ̀ fún ẹlòmíràn? Bíbélì fúnra rẹ̀ dáhùn ìbéèrè yìí.
Kíkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Pẹ̀lú Ọlá Àṣẹ
Kọ́kọ́ gbé àpẹẹrẹ tí Jésù Kristi fi lélẹ̀ yẹ̀ wò. Olùkọ́ tó dáńgájíá ni ó sì nípa lórí ìgbésí ayé àwọn tó fetí sílẹ̀ sí i. (Jòhánù 13:13, 15) Ọ̀nà tó gbà kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ nínú Ìwàásù Lórí Òkè rọrùn ó sì fa kíki. Ohun tó tìdí rẹ̀ jáde ni pé ‘háà ṣe àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀; nítorí ó ń kọ́ wọn bí ẹnì kan tí ó ní ọlá àṣẹ.’ (Mátíù 7:28, 29) Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ọdún lẹ́yìn náà, ẹ̀kọ́ rẹ̀ ṣì ń nípa lórí ìgbésí ayé àwọn tó ń ṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀kọ́ náà. Ọ̀jọ̀gbọ́n Hans Dieter Betz sọ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, ó ní “Ìwàásù Lórí Òkè nípa lórí àwọn èèyàn gan-an ju ẹ̀sìn àwọn Júù, ẹ̀sìn Kristẹni àti àṣà àwọn ará ìhà Ìwọ̀ Oòrùn ayé lọ.”
Nígbà tó kù díẹ̀ kí Jésù gòkè re ọ̀run, ó fi àṣẹ kan lélẹ̀ láti rí i dájú pé lẹ́yìn tóun bá kú, iṣẹ́ ìkọ́ni tóun bẹ̀rẹ̀ kò ní í dáwọ́ dúró ńṣe lá máa gbòòrò sí i. (Jòhánù 14:12) Ó ní káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè, kí wọ́n ‘máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí òun ti kọ́ wọn mọ́.’ Nínú ọ̀rọ̀ yìí, Jésù sọ ohun tó jẹ́ olórí ète iṣẹ́ náà, ó sọ pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn . . . di ọmọ ẹ̀yìn.” —Mátíù 28:19, 20; Ìṣe 1:8.
Síwájú sí i, tún wo àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Lẹ́yìn tóun fúnra rẹ̀ yí padà di Kristẹni, kò fà sẹ́yìn láti sọ nípa ìsìn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ rí náà fún àwọn ẹlòmíràn. (Ìṣe 9:17-19, 22) Àṣà Pọ́ọ̀lù ni pé kó máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ ní sínágọ́gù kó sì mú un dá wọn lójú “nípasẹ̀ àwọn ìtọ́ka pé ó pọndandan kí Kristi jìyà, kí ó sì dìde kúrò nínú òkú.” Pẹ̀lú ọgbọ́n, “ó . . . bá wọn fèrò-wérò láti inú Ìwé Mímọ́” kó bàa lè “yí àwọn Júù àti Gíríìkì lérò padà.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìwádìí kan ṣe sọ, ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí wọ́n lò fún “yí lérò padà” túmọ̀ sí “yíyí èrò inú èèyàn padà nípa ríronú jinlẹ̀ tàbí nípa kíkíyèsí ìwà rere ẹlòmíràn.” Bí Pọ́ọ̀lù ṣe bá àwọn èèyàn fèrò wérò láti yí wọn lérò padà yìí ló mú kó lè “yí ogunlọ́gọ̀ tí ó tóbi púpọ̀ lérò padà, tí ó sì ti yí wọn padà sí èrò mìíràn.”—Ìṣe 15:3; 17:1-4, 17; 18:4; 19:26.
Ṣé Tipátipá Ni àbí Lọ́wọ́ Ẹ̀rọ̀?
Láyé òde òní, ọ̀rọ̀ náà “ìyínilẹ́sìnpadà” ni wọ́n ń lò fún fífi tìpá-tìkúùkù mú kí ẹnì kan yí ẹ̀sìn rẹ̀ padà. Àmọ́ Bíbélì kò fọwọ́ sí irú àṣà bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ká mọ̀ pé a dá àwọn èèyàn lọ́nà tí wọ́n á fi lè yan ohun tó bá wù wọ́n, ọwọ́ wọn ló sì kù sí láti yàn bí wọ́n ṣe máa gbé ìgbésí ayé wọn. Èyí kan yíyan ọ̀nà tí wọ́n á gbà jọ́sìn Ọlọ́run.—Diutarónómì 30:19, 20; Jóṣúà 24:15.
Jésù bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ tí Ọlọ́run fún èèyàn yìí, ìdí rèé tí kò fi fi agbára tó ju agbára lọ tó ní àti ọlá àṣẹ rẹ̀ mú ẹnikẹ́ni ní tipátipá tàbí kó fúngun mọ́ wọn pé nǹkan tóun bá ti sọ ni wọ́n gbọ́dọ̀ gbà. (Jòhánù 6:66-69) Ó ń mú àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe ohun tó yẹ nípa bíba wọn fèrò wérò lọ́nà tó gbéṣẹ́, nípa lílo àwọn àkàwé tó dára àti nípa bíbéèrè àwọn ìbéèrè tó máa mú káwọn yẹn sọ èrò wọn jáde kó bàa lè dé ọkàn wọn. (Mátíù 13:34; 22:41-46; Lúùkù 10:36) Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti bọ̀wọ̀ fáwọn ẹlòmíràn gẹ́gẹ́ bóun ṣe ṣe.—Mátíù 10:14.
Ẹ̀rí fi hàn pé Jésù ni Pọ́ọ̀lù fara wé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù fi àwọn èrò tó péye látinú Ìwé Mímọ́ yí àwọn tó gbọ́rọ̀ rẹ̀ lérò padà, ó fi sọ́kàn pé bọ́rọ̀ ṣe ń rí lára kálukú yàtọ̀ síra ó sì bọ̀wọ̀ fún èrò àwọn ẹlòmíràn. (Ìṣe 17:22, 23, 32) Ó mọ̀ pé ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run àti Kristi ló yẹ kó máa sún wa láti jọ́sìn Ẹlẹ́dàá wa nígbà gbogbo. (Jòhánù 3:16; 21:15-17) Nítorí náà, àwa ló ni ìpinnu èyíkéyìí tá a bá ṣe.
Ìpinnu Àdáṣe
Nígbà tá a bá ń ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì ní ìgbésí ayé wa, irú bíi ilé tá a fẹ́ kọ́, ibi tá a ti fẹ́ máa ṣiṣẹ́ àti bá a ṣe máa tọ́ àwọn ọmọ, àwọn olóye èèyàn kì í fi gìràgìrà ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀. Wọ́n á ṣèwádìí nípa onírúurú ọ̀nà tí wọ́n lè gbà ṣe é, wọ́n á ronú jinlẹ̀ lórí ìwádìí náà, wọ́n tiẹ̀ tún lè fọ̀rọ̀ náà lọ àwọn ẹlòmíràn pàápàá. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti gbé àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí ní wọ́n á tó ṣe ìpinnu.
Ó yẹ kí àkókò tá a máa lò àti ìsapá tá a máa ṣe láti pinnu ọ̀nà tó yẹ láti gbà jọ́sìn Ọlọ́run ju èyí tá a máa lò láti ṣe ìpinnu èyíkéyìí mìíràn ní ìgbésí ayé wa lọ. Nítorí ó máa kan bá a ṣe ń gbé ìgbésí ayé wa ní báyìí, èyí tó sì tún ṣe pàtàkì jù níbẹ̀ ni pé òun ló máa pinnu bóyá a máa wà láàyè títí láé lọ́jọ́ iwájú. Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ní Bèróà lóye èyí dáadáa. Àní nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀ ṣàlàyé ìhìn rere náà fún wọn pàápàá, àwọn fúnra wọn tún fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ kó bàa lè dá wọn lójú pé òótọ́ làwọn nǹkan tí wọ́n ń kọ́ wọn. Àbájáde rẹ̀ ni pé “púpọ̀ nínú wọ́n di onígbàgbọ́.”—Ìṣe 17:11, 12.
Lónìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bá iṣẹ́ kíkọ́ni àti sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn tí Jésù ṣètò rẹ̀ nìṣó. (Mátíù 24:14) Wọ́n ń fi sọ́kàn pé àwọn èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ẹ̀sìn tó bá wù wọ́n. Àmọ́ ní ti ọ̀ràn sísọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ nínú ẹ̀sìn wọn fún àwọn ẹlòmíràn, àpẹẹrẹ tó wà nínú Bíbélì ni wọ́n ń tẹ̀ lé. Bẹ́ẹ̀ ni, ojúlówó ìfèròwérò tó wà nínú Ìwé Mímọ́ ni wọ́n ń lò nínú iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà tí wọ́n ń ṣe.—Jòhánù 17:3; 1 Tímótì 4:16.