Àwọn Orílẹ̀-Èdè Kò Tíì Kọ́gbọ́n Síbẹ̀
Àwọn Orílẹ̀-Èdè Kò Tíì Kọ́gbọ́n Síbẹ̀
“Ká láwa èèyàn lè kọ́gbọ́n látinú àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá ni—ẹ̀kọ́ ńlá là bá mà rí kọ́ o! Àmọ́ ńṣe la máa ń jẹ́ kí Ìfẹ́ Àìníjàánu àtọ̀rọ̀ Ìṣèlú dí wa lójú, ẹ̀yìn wa sì ni ìmọ́lẹ̀ tí Ìrírí ń fúnni máa ń tàn sí, kì í tàn síwájú wa!”—Samuel Taylor Coleridge.
ṢÉ O gbà pé òótọ́ ọ̀rọ̀ ni Samuel Coleridge, akéwì ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì yìí sọ? Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí ohun kan tá a nífẹ̀ẹ́ sí gan-an ru bò wá lójú débi pé, a lè ṣe àṣìṣe tó máa yọrí sí ìbànújẹ́ irú èyí táwọn ìran tó ṣáájú wa ti ṣe?
Àwọn Ogun Ẹ̀sìn
Bí àpẹẹrẹ, gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára ohun táwọn èèyàn dán wò lákòókò tí Ogun Ẹ̀sìn ń ṣẹlẹ̀. Lọ́dún 1095 Sànmánì Tiwa, Póòpù Urban Kejì rọ “àwọn Kristẹni” láti gba Ilẹ̀ Mímọ́ lọ́wọ́ àwọn Mùsùlùmí. Làwọn ọba, àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn, àwọn olóyè, àtàwọn èèyàn tó wà ní gbogbo ìlú tí Urban Kejì ń ṣàkóso lé lórí bá dìde sí ìpè rẹ̀ yìí. Gẹ́gẹ́ bí òpìtàn kan nípa sànmánì ojú dúdú ṣe sọ, “bóyá làwọn èèyàn kankan wà tó ń gbé níbàámu pẹ̀lú òfin Kristi” tí wọn ò yára gbárùkù ti ogun ẹ̀sìn yìí.
Òpìtàn Zoé Oldenbourg sọ pé, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ajagun ẹ̀sìn náà “ló dá lójú hán-únhán-ún pé, bí àwọ́n ṣe ń kópa nínú ogun yìí, Ọlọ́run Gan-an [làwọ́n] ń ṣiṣẹ́ sìn.” Òpìtàn náà tún sọ pé, wọ́n máa ń wo ara wọn bí “áńgẹ́lì apanirun tó ń gbógun ti àwọn ọmọ èṣù.” Òǹkọ̀wé Brian Moynahan sọ pé wọ́n tún gbà gbọ́ pé, “gbogbo ẹni tó bá kú nínú ogun náà ló máa rí adé àwọn ajẹ́rìíkú gbà bó bá dé ọ̀run.”
Bóyá àwọn Ajagun Ẹ̀sìn yìí kò mọ̀ pé nǹkan kan náà làwọn ọ̀tá wọn gbà gbọ́. Òpìtàn J. M. Roberts, nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní Shorter History of the World sọ pé, ìgbàgbọ́ tí àwọn jagunjagun ẹlẹ́sìn Ìsìláàmù náà ní bí wọ́n ti ń lọ sójú ogun ni pé, Ọlọ́run làwọ́n ń jà fún àti “pé àlùjánnà lẹni tó bá kú lójú ogun níbi tó ti ń bá àwọn kèfèrí jà máa lọ,” ìyẹn ní ọ̀run.
Ohun tí wọ́n kọ́ àwọn ẹgbẹ́ méjèèjì náà ni pé ogun òdodo ni wọ́n ń jà, pé Ọlọ́run lọ́wọ́ sí i àti pé ó ní ìbùkún Ọlọ́run. Ńṣe làwọn aṣáájú ẹ̀sìn àtàwọn aṣáájú ìṣèlú máa ń tẹ èrò yìí mọ́ àwọn ọmọ abẹ́ wọn lọ́kàn ṣáá, wọ́n á sì máa fẹ́ná mọ́ ọn. Èyí ló mú kí àwọn ẹgbẹ́ méjèèjì hu ìwà ìkà tó burú jáì.
Irú Èèyàn Wo Ni Wọ́n?
Irú àwọn èèyàn wo ló hu àwọn ìwà aburú yìí? Aráàlú lèyí tó pọ̀ jù nínú wọn, wọn ò sì fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sáwọn èèyàn òde òní. Ó dájú pé ẹ̀mí kí nǹkan lè dára sí i, àti ìfẹ́ tí wọ́n ní láti ṣàtúnṣe àwọn ipò tó ti dàrú tí wọ́n ń rí nígbà náà ló kó sí ọ̀pọ̀ lórí. Àmọ́, táwọn nǹkan yìí bá ti ru bò wọ́n lójú, ó jọ
pé wọn kì í mọ̀ pé níbi táwọn bá ti ń jà fún “ẹ̀tọ́,” ńṣe làwọ́n ń hu ìwà tí kò tọ́ sí ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ọkùnrin, obìnrin àtàwọn ọmọdé tí wọn ò mọwọ́mẹsẹ̀, tí ogún ká mọ́ àgbègbè tí ìjà ti ṣẹlẹ̀, tí wọ́n sì ń kó ọ̀pọ̀ ìrora àti ìnira bá àwọn èèyàn náà.Ṣé kì í ṣe ohun tó ti ṣẹlẹ̀ léraléra jálẹ̀ ìtàn nìyẹn? Ṣé àwọn aṣáájú tó mọ ọgbọ́n àyínìke láti fi yí àwọn èèyàn lérò padà ò ti sún ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn lọ́pọ̀ ìgbà láti ṣe ohun táwọn yẹn ò jẹ́ ronú fúnra wọn láti ṣe, ìyẹn láti bá àwọn ọ̀tá wọn nínú ẹ̀sìn tàbí nínú ìṣèlú ja ogun rírorò tó sì burú jáì? Kíkó tí wọ́n ń kó àwọn èèyàn jọ sínú ẹgbẹ́ méjì tó ń bára wọn jà, tí wọ́n á sì sọ fún wọn pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló mú kí ogun di ohun tí wọ́n ń lò láti tẹ àtakò ìṣèlú àti ti ìsìn rì lọ́nà tó mú ìwà ipá dání. Èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlànà tó ti wà látọjọ́ pípẹ́, tí àwọn alákòóso rírorò ti máa ń lò fún àǹfààní ara wọn láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá. Òǹkọ̀wé Moynahan sọ pé ìlànà yìí “làwọn tó wà nídìí Ìpakúpa Rẹpẹtẹ àti ìpẹ̀yàrun tó ń wáyé lóde òní máa wá gùn lé tó bá yá, nígbà tó kúkú jẹ́ pé òun náà ló pilẹ̀ àwọn ogun ẹ̀sìn àkọ́kọ́ pàá.”
Síbẹ̀, ìwọ bí ẹnì kan lè sọ pé: ‘Àwọn èèyàn tí orí wọn pé lónìí kò jẹ́ gbà kí wọ́n yí àwọn lérò padà mọ́ lọ́nà yẹn. Ṣé ojú ò ti wá là jùyẹn lọ ni?’ Bó ṣe yẹ kí ọ̀rọ̀ rí nìyẹn. Àmọ́ ṣé lóòótọ́ làwọn èèyàn ti fi ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá ṣàríkọ́gbọ́n? Ta ló lè sọ pé bí ọ̀rọ̀ ṣe rí nìyẹn téèyàn bá ń ronú dáadáa nípa àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún tó kọjá?
Ogun Àgbáyé Kìíní
Bí àpẹẹrẹ, nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, àwọn èèyàn tún tẹ̀ lé ìlànà tí wọ́n fi lélẹ̀ nígbà Ogun Ẹ̀sìn. Òpìtàn Roberts sọ pé: “Ọ̀kan lára àwọn ohun yíyanilẹ́nu gbáà tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1914 ni bí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè, látinú oríṣiríṣi ẹgbẹ́, ìsìn àti ìran ṣe tú yááyáá jáde lọ́nà tó jọni lójú, tí wọ́n sì fi tinútinú àti tayọ̀tayọ̀ lọ sógun.”
Kí ló mú kí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn fi “tinútinú àti tayọ̀tayọ̀ lọ sógun”? Ìdí ni pé, bíi tàwọn tó fi tinútinú lọ sógun ṣáájú wọn, èrò tó wọ́pọ̀ nígbà yẹn ló ń darí ìrònú wọn àti ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé rírí òmìnira àti ẹ̀tọ́ gbà lè ti sún àwọn kan jagun, kò sí àní-àní pé ẹ̀mí ìgbéraga ló mú ọ̀pọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀mí pé orílẹ̀-èdè tiwọn lọ̀gá àti pé ńṣe ló yẹ káwọn orílẹ̀-èdè tó kù máa wárí fún wọn.
Wọ́n yí àwọn èèyàn wọ̀nyí lérò padà láti gbà pé ogun ò lè ṣe kó máà wáyé torí pé àdámọ́ èèyàn ni, àti pé “ó ti wà nínú ẹ̀jẹ̀ èèyàn.” Bí àpẹẹrẹ, òǹkọ̀wé Phil Williams sọ pé: “Èrò kan tó wọ́pọ̀ tí wọ́n ń pè ní àbá èrò orí Darwin” gbé ìrònú náà lárugẹ pé, ogun jẹ́ ọ̀nà tó bójú mu láti “pa àwọn ìṣẹ̀dá kan tí wọn ò lẹ́tọ̀ọ́ láti máa wà láàyè run.”
Ó dájú pé ẹgbẹ́ kọ̀ọ̀kan tó kópa nínú ogun náà gbà pé ohun táwọn ń ṣe tọ̀nà. Kí wá ni àbájáde rẹ̀? Martin Gilbert, tó jẹ́ òǹkọ̀wé àti òpìtàn sọ pé: “Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní ń lọ lọ́wọ́, àwọn ìjọba ò yéé fún àwọn èèyàn wọn níṣìírí láti kórìíra àwọn ẹ̀yà mìíràn, láti nífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè wọn, àti láti di akọni ológun.” Àwọn èèyàn náà ò sì ronú lẹ́ẹ̀mejì tí wọ́n fi gbá tọ̀ wọ́n lẹ́yìn. Àgbègbè kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ lajú ní orílẹ̀-èdè Kánádà ni onímọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé kan, John Kenneth Galbraith gbé dàgbà lákòókò tí ogun náà ń lọ lọ́wọ́. Ó sọ pé, àwọn èèyàn tó wà láyìíká òun máa ń sọ pé “ńṣe ni ìjà tó ń lọ lọ́wọ́ nílẹ̀ Yúróòpù fi bí àwọn èèyàn ṣe ya òpònú tó hàn.” Wọ́n ní: “Àwọn èèyàn tí orí wọn pé . . . kò jẹ́ bá wọn lọ́wọ́ nínú ìwà wèrè náà.” Àmọ́ nígbà tó yá, àwọn náà ṣe bẹ́ẹ̀. Kí ni àbájáde rẹ̀? Nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́ta [60,000] jagunjagun ọmọ ilẹ̀ Kánádà ló wà lára mílíọ̀nù mẹ́sàn-án jagunjagun tó ṣòfò ẹ̀mí ní apá méjèèjì ohun akóninírìíra tí wọ́n pè ní Ogun Àgbáyé Kìíní lẹ́yìn náà.
Wọn Ò Kọ́ Ẹ̀kọ́ Kankan Rárá
Kí ó tó tó ogún ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn, irú ẹ̀mí yìí kan náà tún ti bẹ̀rẹ̀ sí í fara hàn, nígbà tí ètò ìjọba Aláṣẹ Oníkùmọ̀ àti ètò ìjọba Násì rú yọ. Òǹkọ̀wé Hugh Purcell kọ̀wé pé, àwọn Aláṣẹ Oníkùmọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í lo “ọ̀nà kan tó ti wà látọjọ́ pípẹ́, ìyẹn títan irọ́ kálẹ̀ nípa lílo àwọn àmì kan àtàwọn ìtàn àròsọ, láti ru ìmọ̀lára àwọn èèyàn sókè.” Ọ̀nà kan tó wá gbéṣẹ́ jù tí wọ́n lò ni dída ìsìn pọ̀ mọ́ ìṣèlú, tí wọ́n á máa gbàdúrà fún ìbùkún Ọlọ́run lórí àwọn ọmọ ogun wọn.
Ẹnì kan tó jẹ́ “ògbóǹtarìgì nínú yíyí àwọn èèyàn lérò padà, tó sì tún jẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tí kò lẹ́gbẹ́” ni Adolf Hitler. Nínú ìwé Hitler and Nazism tí Dick Geary kọ, ó sọ pé, bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú burúkú tó ti wà ṣáájú ìgbà tirẹ̀, Hitler gbà pé ‘kì í ṣe ọgbọ́n orí àwọn èèyàn ló sún wọn ṣe ohun tí wọ́n ṣe, àmọ́, ìmọ̀lára wọn ló tì wọ́n ṣe é.’ Purcell sọ pé àléébù ẹ̀dá èèyàn yìí, ìyẹn ìmọ̀lára, ni Hitler lò. Ó lo ọgbọ́n kan tó ti wà tipẹ́, ìyẹn ni nípa mímú káwọn èèyàn máa kórìíra àwọn tí wọ́n kà sí ọ̀tá ìlú wọn, bí irú ìgbà tó “ti àwọn ará Jámánì láti bẹ̀rẹ̀ sí í fura sáwọn Júù tí wọ́n sì kórìíra wọn bí ìgbẹ́.” Ó ba àwọn Júù jẹ́ lójú wọn, ó ní, ‘Àwọn Júù ló ń sọ ilẹ̀ Jámánì dìdàkudà.’
Ohun tó bani lẹ́rù nípa gbogbo àkókò yẹn ni pé, pẹ̀lú ìrọ̀rùn ni wọ́n fi ti ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ọmọlúwàbí èèyàn sínú pípa ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn nípakúpa. Òǹkọ̀wé Geary béèrè pé: “Báwo ló ṣe jẹ́ ná, tí orílẹ̀-èdè tó pera rẹ̀ ní ọ̀làjú kò ṣe lè mú nǹkan mọ́ra, àmọ́ tó jẹ́ pé ńṣe làwọn èèyàn inú rẹ̀ dìídì kópa nínú ìwà ẹhànnà tí ń dáyà foni tí ìjọba Násì hù?” Kì í tún wá ṣe pé orílẹ̀-èdè yìí jẹ́ orílẹ̀-èdè “ọ̀làjú” nìkan ni, àmọ́ orílẹ̀-èdè ẹlẹ́sìn Kristi ni wọ́n tún mọ̀ ọ́n sí! Ohun tó sún wọn sí èyí ni pé, ó tẹ́ wọn lọ́rùn láti tẹ̀ lé ọgbọ́n orí èèyàn àtàwọn ètò táwọn èèyàn gbé kalẹ̀ ju kí wọ́n tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ tí Jésù Kristi fi kọ́ni lọ. Látìgbà náà wá, kò sẹ́ni tó mọ iye ọkùnrin àtobìnrin tí wọ́n jẹ́ èèyàn dáadáa tí wọ́n sì fẹ́ kí nǹkan dára, táwọn aláṣẹ wọ̀nyí ti sún láti hu àwọn ìwà ìkà bíburú jáì lónírúurú!
Onímọ̀ ọgbọ́n orí ọmọ ilẹ̀ Jámánì, Georg Hegel wá sọ pé: “Ẹ̀kọ́ táwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ àti ìtàn fi kọ́ni ni pé, àwọn orílẹ̀-èdè àtàwọn ìjọba kò tíì kọ́ ẹ̀kọ́ kankan rárá látinú àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, àti pé bí wọ́n bá tiẹ̀ rí ohunkóhun kọ́, wọn ò fi ṣèwà hù.” Ọ̀pọ̀ lè máà fara mọ́ èrò tí Hegel ní yìí nípa ìgbésí ayé, àmọ́ ìwọ̀nba èèyàn ló máa kó ọ̀rọ̀ tó sọ yẹn dà nù. Ó mà ṣe o, ńṣe ló dà bíi pé ó máa ń ṣòro gan-an fáwọn èèyàn láti fi àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá ṣàríkọ́gbọ́n. Àmọ́ ṣé ó yẹ kí tìẹ rí bẹ́ẹ̀?
Dájúdájú, ẹ̀kọ́ kan tó hàn gbangba tó yẹ ká kọ́ ni pé: Tá ò bá fẹ́ kí àwọn àgbákò tó ti bá àwọn ìran tó ti kọjá ṣẹlẹ̀ sí wa, a nílò ohun kan tó ṣeé gbára lé gan-an ju ọgbọ́n orí èèyàn tó láṣìṣe lọ. Àmọ́ tá ò bá ní í gbára lé ọgbọ́n orí èèyàn, kí lohun tó yẹ kó máa darí ìrònú wa? Ní ẹgbẹ̀rún ọdún kan ó lé, ṣáájú kí Ogun Ẹ̀sìn tóó máa ṣẹlẹ̀, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi fi ohun tó yẹ kó jẹ́ ìlànà Kristẹni hàn, ìlànà yìí nìkan ṣoṣo ló sì bọ́gbọ́n mu. Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí wọ́n ṣe tí wọn ò fi lọ́wọ́ nínú àwọn ìjà fẹ̀míṣòfò táwọn èèyàn ń jà nígbà ayé wọn. Àmọ́ ṣé a lè sọ pé àwọn orílẹ̀-èdè lóde òní á kọ́ láti ṣe bíi tiwọn, tí wọn ò sì ní í bára wọn jà mọ́? Láìka ohun yòówù táwọn orílẹ̀-èdè ń ṣe sí, kí ni ojútùú tí Ọlọ́run máa mú wá láti fòpin sí gbogbo ìrora ọkàn tó ń kojú aráyé?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Ìwà ẹhànnà àti ìnira ló máa ń kún inú ìjà táwọn èèyàn ń bára wọn jà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Òkè: Àwọn olùwá-ibi-ìsádi tó wà ní àgbègbè tí ogun ti ṣe báṣubàṣu
Báwo làwọn èèyàn tí wọ́n pera wọn ní ọ̀làjú ṣe lè lọ́wọ́ nínú irú àwọn ìwà tó burú jáì bẹ́ẹ̀?
[Àwọn Credit Line]
Àwọn olùwá-ibi-ìsádi ọmọ ilẹ̀ Rwanda: FỌ́TÒ UN 186788/J. Isaac; Ilé ìtajà World Trade Center tó ń ya lulẹ̀: AP Photo/Amy Sancetta