Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Tẹ́tẹ́ Títa—Ti Di Ohun Táwọn Èèyàn nífẹ̀ẹ́ Sí Kárí Ayé

Tẹ́tẹ́ Títa—Ti Di Ohun Táwọn Èèyàn nífẹ̀ẹ́ Sí Kárí Ayé

Tẹ́tẹ́ Títa—Ti Di Ohun Táwọn Èèyàn nífẹ̀ẹ́ Sí Kárí Ayé

ÈRÒ tó máa ń gba John, ẹni tó gbé orílẹ̀-èdè Scotland dàgbà, lọ́kàn ni pé lọ́jọ́ ọjọ́ kan ṣáá, òún á jẹ tẹ́tẹ́ lọ́tìrì. Ó sọ pé: “Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni mo máa ń ra tíkẹ́ẹ̀tì lọ́tìrì. Owó táṣẹ́rẹ́ ló máa ń ná mi, àmọ́ tíkẹ́ẹ̀tì yẹn máa ń fi mí lọ́kàn balẹ̀ pé gbogbo ohun tí mo fẹ́ ni màá rí jẹ.”

Kazushige, tó ń gbé ní Japan, fẹ́ràn láti máa kọ́ iyàn lórí ẹni tó máa borí nínú ìdíje fífi ẹṣin sáré. Ó sọ pé: “Bíbá àwọn ọ̀rẹ́ mi ta tẹ́tẹ́ ní pápá eré ìje máa ń gbádùn mọ́ mi gan an, mo sì máa ń jẹ owó tabua nígbà míì.”

Linda, tó ń gbé ní Ọsirélíà sọ pé: “Tẹ́tẹ́ bingo ni mo yàn láàyò. Àṣà yìí máa ń ná mi ní ọgbọ̀n dọ́là lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, àmọ́ mo fẹ́ràn ìmóríyá tí jíjẹ tẹ́tẹ́ máa ń fúnni.”

John, Kazushige, àti Linda ka tẹ́tẹ́ títa sí eré ìnàjú tí kò lè fi bẹ́ẹ̀ pani lára. Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn kárí ayé ló ní irú èrò bẹ́ẹ̀. Ìwádìí tí wọ́n ṣe ní 1999 láti mọ èrò àwọn aráàlú lórí ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé, ìdá méjì nínú mẹ́ta àwọn ará Amẹ́ríkà ló fojúure wo tẹ́tẹ́ títa. Lọ́dún 1998, àwọn atatẹ́tẹ́ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ná nǹkan bí àádọ́ta bílíọ̀nù owó dọ́là sórí tẹ́tẹ́ tí ìjọba fọwọ́ sí—owó yìí sì ju àpapọ̀ iye tí wọ́n ná sórí ríra tíkẹ́ẹ̀tì sinimá, ríra àwo orin, lílọ síbi eré ìdárayá, lílọ sí ibùdó ìgbafẹ́, àti ṣíṣe eré ìdárayá orí fídíò.

Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí ti sọ, láàárín ọdún kan ṣoṣo, iye tó ju ìdá ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn olùgbé orílẹ̀-èdè Ọsirélíà ló ta tẹ́tẹ́ lẹ́ẹ̀kan ó kéré tán, nígbà tí ìdá ogójì nínú ọgọ́rùn-ún sì ń ta á lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ní ìpíndọ́gba, àwọn àgbàlagbà tó wà ní orílẹ̀-èdè yẹn máa ń ná ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù dọ́là lọ́dọọdún sórí tẹ́tẹ́ títa, ìyẹn sì fi nǹkan bí ìlọ́po méjì ju iye tí àwọn ará Yúróòpù tàbí àwọn ará Amẹ́ríkà ń ná lé e lórí. Èyí mú kí àwọn ará Ọsirélíà wà lára àwọn tí tẹ́tẹ́ títa wọ̀ lẹ́wù jù lọ lágbàáyé.

Ọ̀pọ̀ àwọn ará Japan ló ti sọ tẹ́tẹ́ pachinko di bárakú, ìyẹn eré ìdárayá kan tí wọ́n máa ń fi ẹ̀rọ kan tó ń jẹ́ pinball ṣe, wọ́n sì máa ń ná ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù dọ́là lé e lórí lọ́dọọdún. Ní orílẹ̀-èdè Brazil, wọ́n máa ń ná bílíọ̀nù mẹ́rin owó dọ́là ó kéré tán lọ́dọọdún lórí tẹ́tẹ́ títa, ọ̀pọ̀ jù lọ lára owó yìí ló sì jẹ́ lórí ríra tíkẹ́ẹ̀tì lọ́tìrì. Àmọ́ kì í ṣe àwọn ará Brazil nìkan ló nífẹ̀ẹ́ tẹ́tẹ́ lọ́tìrì o. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ìwé ìròyìn Public Gaming International fojú bù ú pé ‘oríṣiríṣi tẹ́tẹ́ lọ́tìrì tó jẹ́ ọ̀ọ́dúnrún ó lé mẹ́fà [306] ló wà ní orílẹ̀-èdè méjìlélọ́gọ́rùn-ún [102].’ Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n pé, kárí ayé làwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí tẹ́tẹ́ títa—àwọn kan tiẹ̀ sọ pé ó máa ń mú èrè gọbọi wá.

Sharon Sharp tó jẹ́ aṣojú fún Àjọ Tó Ń Ṣèwádìí Nípa Tẹ́tẹ́ Títa Láwùjọ sọ pé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, láti ọdún 1964 sí 1999, owó tí tẹ́tẹ́ lọ́tìrì pa wọlé “ló pèsè nǹkan bíi bílíọ̀nù márùnlélọ́gọ́fà [125] dọ́là lára owó tí ìjọba ìpínlẹ̀ yà sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìwéwèé ìṣúnná owó, iye tó sì pọ̀ jù lára owó yìí ti ń ya sápò ìjọba látọdún 1993.” Ọ̀pọ̀ jù lọ lára owó yìí ni wọ́n yà sọ́tọ̀ fún ètò ẹ̀kọ́ aráàlú, fún bíbójútó àwọn ọgbà ìgbafẹ́, àti fún bíbójútó àwọn ibùdó eré ìdárayá. Àwọn iléeṣẹ́ tó ń ṣagbátẹrù tẹ́tẹ́ títa tún máa ń gba ọ̀pọ̀ èèyàn síṣẹ́. Ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà nìkan, àwọn èèyàn tó tó nǹkan bí ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] ni wọ́n gbà síṣẹ́ ní àwọn ibùdó tẹ́tẹ́ títa tó lé ní ẹgbẹ̀rún méje.

Nípa báyìí, àwọn tó ń ṣalágbàwí tẹ́tẹ́ títa gbà pé láfikún sí bí tẹ́tẹ́ tí ìjọba fọwọ́ sí ṣe ń pèsè eré ìnàjú fáwọn aráàlú, ó tún ń jẹ́ kí wọ́n rí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ ṣe, ó ń pèsè owó láti fi sanwó orí, ó sì ń jẹ́ kí ọrọ̀ ajé tó ti dẹnu kọlẹ̀ gbé pẹ́ẹ́lí sí i.

Nítorí náà, ìbéèrè tó máa wá sọ́kàn ọ̀pọ̀ èèyàn ni pé, ‘Kí ló burú nínú tẹ́tẹ́ títa?’ Ó ṣeé ṣe kí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, tá a jíròrò nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e, yí èrò tó o ti ní nípa tẹ́tẹ́ títa padà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

John

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Kazushige

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Linda