Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Yàgò Fún Ìdẹkùn Tẹ́tẹ́ Títa

Yàgò Fún Ìdẹkùn Tẹ́tẹ́ Títa

Yàgò Fún Ìdẹkùn Tẹ́tẹ́ Títa

“Kò sí ìpalára tí tẹ́tẹ́ títa ń ṣe fún ìlera mi, mo sì máa ń ṣọ́ owó ná tí mo bá ń ta tẹ́tẹ́. Àmọ́ kí n sòótọ́, gbogbo ìgbà tí mo bá ń ta tẹ́tẹ́ lọ́tìrì ni mo máa ń mú àwọn nọ́ńbà kan tí mo gbà pé wọ́n jẹ́ nọ́ńbà oríire mi.”Linda.

Ọ̀PỌ̀ àwọn atatẹ́tẹ́ ló ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn nọ́ńbà oríire tàbí nínú oògùn oríire. Wọ́n lè rò pé àwọn ò fi gbogbo ara ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ohun asán, àmọ́ ìgbàgbọ́ yìí ṣì lè máa jọba lọ́kàn wọn ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá ń ta tẹ́tẹ́.

Kódà, àwọn atatẹ́tẹ́ kan máa ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run pé kó jọ̀wọ́ ran àwọn lọ́wọ́ láti lè jẹ ayò tí wọ́n ta. Síbẹ̀, àkọsílẹ̀ bí Ọlọ́run ṣe dá àwọn kan lẹ́bi wà nínú Bíbélì, ìyẹn àwọn tó sọ pé àwọn ń jọ́sìn Ọlọ́run àmọ́ tí wọ́n “ń tẹ́ tábìlì fún ọlọ́run Oríire.” (Aísáyà 65:11) Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run kórìíra àwọn àṣà tó bá ń gbé ìgbàgbọ́ asán nínú ọlọ́run oríire lárugẹ. Tẹ́tẹ́ títa gan an fúnra rẹ̀ máa ń jẹ́ kéèyàn ní ìgbẹ́kẹ̀lé tí kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ nínú ohun tí wọ́n ń pè ní Ìyáàfin Oríire, ìyẹn ìrònú bóyá-á-jẹ́-bọ́-sí-i.

Tẹ́tẹ́ títa tún máa ń gbé ìfẹ́ owó lárugẹ láìfibò rárá. Nínú ayé tá à ń gbé lónìí tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ ka ọ̀ràn ẹ̀sìn sí, owó gan-an fúnra rẹ̀ ti wá di ọlọ́run àfirọ́pò, tẹ́tẹ́ títa sì jẹ́ ọ̀nà kan tó gbajúmọ̀ láti jọ́sìn owó. Àwọn ilé tẹ́tẹ́ àwòṣífìlà tí ń kọ mànà ti gba ipò ìjọsìn mọ́ àwọn èèyàn lọ́wọ́, ìlànà tuntun tí tọmọdétàgbà ń tẹ̀ lé sì ni pé ìwọra bójú mu. Gẹ́gẹ́ bí ohun táwọn olùwádìí ṣàwárí, wọ́n ní ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn tó ń lọ sí ilé tẹ́tẹ́ ló sọ pé kì í ṣe torí àtilọ ṣe eré ìnàjú tàbí láti lọ wòran lásán làwọ́n fi ń lọ, àmọ́ ó jẹ́ torí àtilè jẹ “owó tabua, owó tó pọ̀ yamùrá.” Àmọ́ ṣá o, Bíbélì kìlọ̀ pé: “Ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo, àti nípa nínàgà fún ìfẹ́ yìí, a ti mú àwọn kan ṣáko lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.”—1 Tímótì 6:10.

1 Kọ́ríńtì 6:9, 10, Bíbélì sojú abẹ níkòó pé: “Kí a má ṣì yín lọ́nà. Kì í ṣe àwọn . . . abọ̀rìṣà . . . tàbí àwọn oníwọra . . . ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.” Kì í ṣe pé ìwọra lè pa àwùjọ lára bópẹ́ bóyá nìkan ni; ó jẹ́ àìsàn tẹ̀mí tó lè ṣekú pani—ṣùgbọ́n kì í ṣe àìsàn tí kò gbóògùn.

Wọ́n Gba Okun Tó Mú Kí Wọn Yí Padà

Kazushige tá a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo ti gbìyànjú láti jáwọ́ nínú tẹ́tẹ́ títa. Mo rí i pé bí mo ṣe ń bá àwọn ọ̀rẹ́ mi ta tẹ́tẹ́ níbi ìdíje fífi ẹṣin sáré ń ṣàkóbá fún ìdílé mi. Mo sábà máa ń pàdánù owó tí mo bá fi ta. Àní, mo tiẹ̀ tún fi owó tí ìyàwó mi fi pa mọ́ nítorí ìgbà tá a bá bí ọmọ wa kejì ta tẹ́tẹ́. Nígbà tó sì yá, ńṣe ni mo kúkú wá bẹ̀rẹ̀ sí í jí owó ibi iṣẹ́ mi láti fi ta tẹ́tẹ́. Látàrí èyí, mi ò wá gbayì kankan mọ́ páàpáà. Ìyàwó mi á kàn máa sunkún ṣáá ni, á sì máa bẹ̀ mí láti jáwọ́ nínú tẹ́tẹ́ títa, àmọ́ kò rọrùn fún mi rárá.”

Kazushige wá bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó sọ pé: “Bí mo ṣe túbọ̀ ń ka Bíbélì sí i ló túbọ̀ ń dá mi lójú pé Ọlọ́run wà, àti pé màá jàǹfààní bí mo bá ń fetí sílẹ̀ sí i. Mo wá pinnu pé lágbára Ọlọ́run, màá jáwọ́ nínú tẹ́tẹ́ títa. Sí ìyàlẹ́nu mi, kì í ṣe pé mo ti jáwọ́ nínú tẹ́tẹ́ títa nìkan ni, àmọ́ mo tún ti wá kórìíra rẹ̀. Nísinsìnyí, tí mo bá wá ń ronú nípa ìnira tí tẹ́tẹ́ títa ti mú bá ìdílé mi, ńṣe lọkàn mi máa ń gbọgbẹ́. Mo mà dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà Ọlọ́run o, fún bó ṣe ràn mí lọ́wọ́ láti bọ́ lọ́wọ́ tẹ́tẹ́ títa tó ti di bárakú fún mi, àti pé ó ń ràn mí lọ́wọ́ láti máa gbé ìgbésí ayé tó nítumọ̀ báyìí!”—Hébérù 4:12.

John tá a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bákan náà. Ó sọ pé: “Ẹ̀kọ́ Bíbélì tí mo kọ́ ló mú kí n fara balẹ̀ gbé ọ̀ràn ara mi yẹ̀ wò. Fún ìgbà àkọ́kọ́ pàá, ńṣe ni ojú mi wá là kedere sí àdánù tí tẹ́tẹ́ títa mi ń mú bá ìdílé mi àti èmi alára. Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wá mọ̀ ni pé ńṣe ni tẹ́tẹ́ títa máa ń jẹ́ kéèyàn ní ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan àti ìwọra—àwọn ànímọ́ tí Jèhófà kórìíra. Bí mo ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ mi, ìfẹ́ tí mo ní fún Jèhófà fún mi lókun láti já ara mi gbà lọ́wọ́ tẹ́tẹ́ títa. Bí mo ṣe máa ń fojú sọ́nà lọ́nà tí ó ga fún ìgbésí ayé tó dára tẹ́lẹ̀ ló sún mi dédìí tẹ́tẹ́ títa. Nísinsìnyí tí mo ti fi tẹ́tẹ́ títa sílẹ̀ tí mo sì ń fi tayọ̀tayọ̀ sin Jèhófà, ọkàn mi ti balẹ̀, ayé mi sì ti dára.”

Linda, tó jẹ́ ìyàwó John, náà pinnu láti ta kété sí tẹ́tẹ́ títa. Ó sọ pé: “Kò rọrùn o, àmọ́ lẹ́yìn tí èmi àti ọkọ mi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mo wá pọkàn pọ̀ sórí àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé. Kì í ṣe pé mo kẹ́kọ̀ọ́ láti nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ohun tí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ sí nìkan ni, ṣùgbọ́n mo tún wá kórìíra àwọn ohun tó kórìíra, títí kan ojúkòkòrò lónírúurú. Yàtọ̀ sí pé ìgbésí ayé tí mò ń gbé báyìí nítumọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, mo ti wá lówó lọ́wọ́ sí i.”—Sáàmù 97:10.

Bó o bá mú àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run dàgbà, ìwọ náà yóò lè ní okun àti ọgbọ́n tó o nílò láti lè yàgò fún ìdẹkùn tẹ́tẹ́ títa. Ṣíṣe èyí yóò jẹ́ kí ipò ìṣúnná owó rẹ gbé pẹ́ẹ́lí sí i, wàá túbọ̀ ní ìfọ̀kànbalẹ̀, wàá sì lè ní ìlera tẹ̀mí tó jíire. Ìgbà yẹn gan an ni ọ̀rọ̀ tó wà nínú Òwe 10:22 á wá ṣẹ sí ọ lára, èyí tó kà pé: “Ìbùkún Jèhófà-èyíinì ni ohun tí ń sọni di ọlọ́rọ̀, kì í sì í fi ìrora kún un.”

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 21]

Kì í ṣe pé ìwọra lè pa àwùjọ lára bópẹ́ bóyá nìkan ni; ó jẹ́ àìsàn tẹ̀mí tó lè ṣekú pani

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Tẹ́tẹ́ Títa Àtàwọn Agbára Àìrí

Nínú ìròyìn kan tí àwọn olùwádìí ní Yunifásítì Duke fi ránṣẹ́ sí Ìgbìmọ̀ Tí Ìjọba Àpapọ̀ Gbé Kalẹ̀ Láti Ṣàyẹ̀wò Ipa Tí Tẹ́tẹ́ Títa Ń Ní Lórí Àwùjọ, wọ́n tọ́ka sí i pé àjọṣe kan wà láàárín ọ̀nà tí wọ́n ń gbà polówó tẹ́tẹ́ àti bí àwọn atatẹ́tẹ́ ṣe ń ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn agbára tó ju ti ẹ̀dá lọ. Ìròyìn náà sọ pé: “Ariwo ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì ni ọ̀pọ̀ ìpolówó [tẹ́tẹ́ lọ́tìrì] máa ń pa ṣáá . . . Síbẹ̀, wọn ò jẹ́ sọ pé ṣíṣe iṣẹ́ àṣekára àti níní ìforítì lẹ́nu iṣẹ́ ló lè mú kéèyàn ní àwọn ohun ìní wọ̀nyí, àmọ́ wọ́n á ní béèyàn bá ti lè ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn agbára tó ju ti ẹ̀dá lọ, gbogbo ohun tó bá ń fẹ́ ló máa ní. Gbogbo àwọn máníjà ilé tẹ́tẹ́ ló mọ̀ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn oníbàárà wọn lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló máa ń ta tẹ́tẹ́ níbàámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tí kálukú wọn ní nínú ohun asán, nínú ìwé ìwòràwọ̀, nínú àwọn ẹni tó ń woṣẹ́, àti nínú ‘àwọn ìwé àlá’ tí wọ́n ń gbé gẹ̀gẹ̀, èyí tó ṣètòlẹ́sẹẹsẹ àwọn nọ́ńbà oríire tó bá orúkọ, déètì, àti àlá dọ́gba. Dípò tí wọn ì bá fi máa tẹnu mọ́ ọn pé kò sí nọ́ńbà téèyàn ò lè ṣèèṣì mú, àti pé títa àwọn nọ́ńbà kan pàtó ní gbogbo ìgbà lè dín owó tí ẹnì kan lè jẹ kù nínú ìdíje fífi ẹṣin sáré, ńṣe làwọn iléeṣẹ́ tẹ́tẹ́ máa ń rọ àwọn tó ń ta á pé kí wọ́n máa mú àwọn nọ́ńbà tó bá ń jẹ́ wọn lọ́wọ́, kí wọ́n sì máa (lò wọ́n lọ).”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

“Ìfẹ́ tí mo ní fún Jèhófà fún mi lókun láti já ara mi gbà lọ́wọ́ tẹ́tẹ́ títa—John

“Yàtọ̀ sí pé ìgbésí ayé tí mò ń gbé báyìí nítumọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, mo ti wá lówó lọ́wọ́ sí i.”—Linda

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

“Sí ìyàlẹ́nu mi, kì í ṣe pé mo ti jáwọ́ nínú tẹ́tẹ́ títa nìkan ni, àmọ́ mo tún ti wá kórìíra rẹ̀”—Kazushige