“Gbẹgẹdẹ Lè Gbiná Lọ́jọ́ Iwájú O”
“Gbẹgẹdẹ Lè Gbiná Lọ́jọ́ Iwájú O”
FOJÚ inú wo ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ná. Àwọn apániláyà fọgbọ́n da fáírọ́ọ̀sì àrùn ìgbóná sínú ilé ìtajà ńlá mẹ́ta ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Ni fáírọ́ọ̀sì náà bá bẹ̀rẹ̀ sí kéèràn ran àwọn tó ń rajà láìfura. Láìpẹ́—ọ̀sẹ̀ kan kọjá tàì kọjá—làwọn dókítà bá ṣàkíyèsí pé àwọn èèyàn bí ogún ni àrùn ìgbóná ti kọ lù. Láwọn ọjọ́ tó tẹ̀ lé e, fáírọ́ọ̀sì náà ti ran àwọn ẹlòmíràn. Jìnnìjìnnì bo gbogbo èèyàn. Ìwọ́de ń lọ lọ́tùn-ún lósì. Iṣẹ́ pá àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn lórí, torí pé aláìsàn ti pọ̀ ju oníṣègùn lọ. Ìjọba ti gbogbo ààlà ẹnubodè orílẹ̀-èdè pa. Ọrọ̀ ajé ń múra àtidẹnukọlẹ̀. Ọjọ́ mọ́kànlélógún péré lẹ́yìn tí àrùn ìgbóná ọ̀hún bẹ́ sílẹ̀, ó ti tàn dé ìpínlẹ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n àti orílẹ̀-èdè mẹ́wàá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Nígbà yẹn, àwọn bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógún ló ti kó àrùn náà, ó sì ti pa ẹgbẹ̀rún kan èèyàn. Àwọn dókítà fojú díwọ̀n rẹ̀ pé tó bá fi máa di ọ̀sẹ̀ mẹ́ta sí àsìkò yẹn, iye àwọn tó ti máa kó àrùn ìgbóná á ti tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún [300,000]. Ìdá mẹ́ta lára wọn làrùn náà sì máa pa.
Èyí kì í ṣe ìdánrawò eré sinimá kan tó dá lórí àròsọ ohun tí a lè fi ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ ṣe o. Ó jẹ́ àfidánrawò kan tí wọ́n fi ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà ṣe, láti lè pinnu jàǹbá tó lè tìdí irú ìṣẹ̀lẹ̀ aburú bẹ́ẹ̀ yọ bó bá lọ wáyé pẹ́nrẹ́n. Àwùjọ àwọn ògbógi, tí wọ́n jẹ́ ọ̀mọ̀ràn tí ń moyún ìgbín nínú ìkarahun, ló ṣagbátẹrù àfidánrawò yìí ní oṣù June 2001.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti gbà pé àfàìmọ̀ ni gbẹgẹdẹ ò fi ní gbiná lọ́jọ́ iwájú látàrí àjálù tó wáyé ní September 11, 2001. Báwọn apániláyà ṣe kọlu Ilé Ìtajà Tó Tóbi Jù Lọ Lágbàáyé (World Trade Center) tó wà ní ìpínlẹ̀ New York City, àti Orílé-Iṣẹ́ Tó Ń Rí Sí Ọ̀ràn Ààbò Nílẹ̀ Amẹ́ríkà (Pentagon) ní ìpínlẹ̀ Washington, D.C. fi hàn gbangba-gbàǹgbà pé, àwọn ẹ̀dá kan ń bẹ tó jẹ́ òṣìkà paraku àti abínú ẹni, tí wọ́n ti pinnu láti gbẹ̀mí gbogbo èèyàn nípasẹ̀ ìparun runlérùnnà. Yàtọ̀ síyẹn, ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú bùrùjà yìí fi hàn pé irú àjálù yìí lè wáyé ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà àtàwọn orílẹ̀-èdè mìíràn pàápàá.
Nínú ayé tá à ń gbé yìí, àwọn apániláyà lè gbẹ̀mí ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn láàárín ìṣẹ́jú bíi mélòó kan.Ní wéré tí àjálù September 11 wáyé, àwọn òṣèlú àtàwọn òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ ìròyìn nílẹ̀ Amẹ́ríkà ti bẹ̀rẹ̀ sí gba àwọn lẹ́tà tó ní èròjà anthrax nínú, ìyẹn kòkòrò bakitéríà kan tó jẹ́ aṣekúpani. Lẹ̀rù bá bẹ̀rẹ̀ sí ba tọmọdé tàgbà. Ohun tó tún wá dá kún ẹ̀rù tó ń ba àwọn èèyàn ni bí àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn, àtàwọn ògbóǹkangí ṣe ń méfò pé àwọn apániláyà tún lè ṣe jàǹbá nípa lílo àwọn kòkòrò àrùn tó tún léwu fíìfíì ju kòkòrò bakitéríà tí wọ́n ń pè ní anthrax lọ—irú bíi kòkòrò bakitéríà tó ń jẹ́ plague tàbí fáírọ́ọ̀sì ìgbóná. Àfàìmọ̀ káwọn “orílẹ̀-èdè abẹ́gbẹ́yodì” kan má tiẹ̀ ti máa ṣe àwọn èròjà aṣekúpani ọ̀hún lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ láwọn ibi ìwádìí ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ kan tó wà ní kọ́lọ́fín. Gbé ohun táwọn àkọsílẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́ kan sọ yẹ̀ wò:
“Àjọ Ìlera Àgbáyé mọ̀ nípa ewu tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i pé, ó ṣeé ṣe káwọn ẹni ibi kan lo àwọn ohun ìjà oníkòkòrò àrùn láti fi fa àjàkálẹ̀ àrùn tó burú jáì jù lọ, èyí tó lè tàn káàkiri àgbáyé. Ewu yìí kò yọ orílẹ̀-èdè kankan sílẹ̀ o. Bí wọ́n bá lọ tan àwọn kòkòrò àrùn kan kálẹ̀, irú bíi fáírọ́ọ̀sì ìgbóná, bakitéríà plague, tàbí bakitéríà anthrax, àgbákò ọ̀hún á kọjá sísọ nítorí àìsàn tó máa dá sílẹ̀, tí ikú á sì gbẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn lọ bí ilẹ̀ bí ẹní, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti ìpayà tó máa fà.”—Àjọ Ìlera Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà.
“Láìdàbí bọ́ǹbù àtàwọn gáàsì aséniléèémí tó ń pani lójú ẹsẹ̀, adọ́gbọ́nṣọṣẹ́ làwọn ohun ìjà oníkòkòrò àrùn: ọṣẹ́ tí àrùn ọ̀hún ti máa ṣe lára èèyàn á ti pọ̀ gan-an kéèyàn tó fura, díẹ̀díẹ̀ sì ni, torí kò ní tètè hàn sí onítọ̀hún. Nígbà tó bá kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí gbèèràn, ení tere èjì tere làwọn èèyàn á máa dé sílé ìwòsàn. Àwọn àmì táwọn dókítà máa rí lè yà wọ́n lẹ́nu tàbí kó fara jọ irú ti àwọn àmódi kan tó sábà máa ń ṣèèyàn. Ìgbà táwọn olùtọ́jú aláìsàn bá fi máa mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀, àrùn yìí lè ti ran odindi ìlú.”—Ìwé ìròyìn Scientific American.
“Bí wọ́n bá tan fáírọ́ọ̀sì ìgbóná kálẹ̀ lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé ni kò ní ní àjẹsára, bá a bá sì wo bó ṣe jẹ́ pé ìdá ọgbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí àrùn yìí bá kọlù ló sábà máa ń ṣekú pa, ó fi hàn pé nǹkan bíi bílíọ̀nù méjì èèyàn ló lè gbẹ̀mí wọn.”—Ìwé ìròyìn Foreign Affairs.
‘Ewu yìí kò yọ orílẹ̀-èdè kankan sílẹ̀. Àrùn yìí lè ran odindi ìlú. Ó lè gbẹ̀mí àwọn èèyàn tó tó bílíọ̀nù méjì.’ Àwọn gbólóhùn wọ̀nyí ń da jìnnìjìnnì boni. Síbẹ̀, báwo ló ṣe dájú tó pé àwọn ẹni ibi kan lè lo àwọn ohun ìjà oníkòkòrò àrùn láti fi ṣe jàǹbá runlérùnnà? Àwọn ògbógi ṣì ń gbé ìbéèrè yìí yẹ̀ wò. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e á jẹ́ kó o mọ díẹ̀ lára àwọn ohun tó so mọ́ irú àjálù yìí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Àwọn ológun ń ṣe ìdánrawò bí wọ́n ṣe lè kápá ìkọluni oníkòkòrò àrùn
[Credit Line]
Fọ́tò DoD látọwọ́ Cpl. Branden P. O’Brien, U.S. Marine Corps