Wọn Ò Tíì Rí Ojútùú Rẹ̀ O
Wọn Ò Tíì Rí Ojútùú Rẹ̀ O
BẸ̀RẸ̀ látọdún 1972, àwọn orílẹ̀-èdè tó lé ní ọgọ́rùn-ún ló ti fọwọ́ sí àdéhùn àgbáyé kan tó ń fòfin de híhùmọ̀ àwọn ohun ìjà oníkòkòrò àrùn, mímú wọn jáde, àti títò wọ́n jọ pelemọ. Àdéhùn yìí, tí wọ́n pè ní Àdéhùn Lórí Àwọn Ohun Ìjà Oníkòkòrò Àrùn àti Onímájèlé, ni àkọ́kọ́ irú rẹ̀ láti fòpin sí oríṣi àwọn ohun ìjà kan ní pàtó. Àléébù tó wà nínú àdéhùn ọ̀hún ni pé, ó kùnà láti ṣètòlẹ́sẹẹsẹ ọ̀nà tí yóò fi hàn bóyá lóòótọ́ làwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé ń tẹ̀ lé ìlànà tó fi lélẹ̀ náà.
Kò rọrùn láti sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé àwọn orílẹ̀-èdè kan kì í ṣe àwọn ohun ìjà oníkòkòrò àrùn jáde, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọgbọ́n iṣẹ́ ẹ̀rọ tí wọ́n ń lò fún ète tó dára náà ni wọ́n tún ń lò fún mímú àwọn ohun ìjà oníkòkòrò àrùn jáde. Bí lílo ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè fún ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ṣe jẹ́ “aṣeburúkú-ṣere” yìí ti mú kó rọrùn láti ṣe àwọn ohun ìjà wọ̀nyí ní bòókẹ́lẹ́ nínú àwọn ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ àti àwọn ibi ìwádìí ìmọ̀-ìjìnlẹ̀, téèyàn á sì máa rò pé àǹfààní àwọn aráàlú ni wọ́n wà fún.
Láti yanjú àwọn ìṣòro rírí ẹ̀rí àrídájú, àwọn aṣojú ìjọba láti onírúurú orílẹ̀-èdè bẹ̀rẹ̀ síí ṣe àdéhùn àgbáyé kan tí gbogbo orílẹ̀-èdè ní láti fọwọ́ sí bẹ̀rẹ̀ látọdún 1995. Fún ohun tó lé ní ọdún mẹ́fà, wọ́n fara balẹ̀ jíròrò àwọn ìgbésẹ̀ pàtàkì tí wọ́n lè gbé láti rí i pé àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé tẹ̀ lé Àdéhùn Lórí Àwọn Ohun Ìjà Oníkòkòrò Àrùn àti Onímájèlé. Ní December 7, 2001, wọ́n ṣe àpérò ọlọ́sẹ̀-mẹ́ta kan, èyí tí àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́rìnlélógóje [144] tó ti fọwọ́ sí àdéhùn ti ọdún 1972 pésẹ̀ sí, àmọ́ àbọ̀ ìpàdé ọ̀hún kò lórí kò nídìí. Ìṣòro ibẹ̀ ni pé, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà kò fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ìdámọ̀ràn pàtàkì tí wọ́n ṣe nípa bí wọ́n ṣe lè rí àrídájú pé àwọn orílẹ̀-èdè ń tẹ̀ lé Àdéhùn Lórí Àwọn Ohun Ìjà Oníkòkòrò Àrùn àti Onímájèlé. Ilẹ̀ Amẹ́ríkà fàáké kọ́rí pé, gbígba àwọn àjèjì láyè láti wá ṣàyẹ̀wò
àwọn ibùdó ológun àti ti iléeṣẹ́ ẹ̀rọ wọn, yóò fún àwọn amí láǹfààní láti rí gbogbo àṣírí àwọn.Ohun Tó Ń Bẹ Níwájú
Lílo ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ láti fi mú ohun alààyè jáde lọ́pọ̀ yanturu ní àǹfààní tó gadabú láti ṣe rere àti láti ṣe búburú. Àwọn ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ mìíràn tó jẹ́ àkànṣe—irú bí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tó jẹ mọ́ ṣíṣe mẹ́táàlì, ṣíṣe àwọn ohun ìjà abúgbàù, ṣíṣe àwọn ẹ́ńjìnnì tó ń mú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ṣiṣẹ́, ṣíṣe àwọn ọkọ̀ ojú òfuurufú, àti ṣíṣe àwọn ẹ̀rọ abánáṣiṣẹ́—làwọn èèyàn ti lò, kì í ṣe fún ète àlàáfíà nìkan, àmọ́ láti fi ṣe jàǹbá fún ọmọnìkejì wọn. Ṣé ọ̀nà yìí náà ló yẹ ká gbà lo ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè? Ọ̀pọ̀ gbà pé bẹ́ẹ̀ ni, kò sóhun tó burú níbẹ̀.
Ìròyìn kan tí Àjọ Tó Ń Mójú Tó Ọ̀ràn Ààbò Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà kọ lọ́dún 1999 sọ pé: “Àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àtàwọn ẹgbẹ́ kan . . . yóò di ẹni tí agbára wà níkàáwọ́ wọn, ọ̀pọ̀ èèyàn yóò sì ní àwọn ohun èlò tó lè ṣe jàǹbá tó lékenkà lọ́wọ́. . . . Àwọn ẹgbẹ́ ajìjàgbara àtàwọn èèyàn kọ̀ọ̀kan tí ìgbónára ẹ̀sìn, ààtò ìjọsìn ẹgbẹ́ òkùnkùn, tàbí tí ìkórìíra ọmọnìkejì ẹni tìkàtẹ̀gbin sábà máa ń darí, ṣì máa wà káàkiri tí wọ́n á sì máa ṣọṣẹ́ láìdáwọ́dúró. Àwọn apániláyà lè wá máa lo onírúurú ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tó jẹ́ pé kìkì àwọn orílẹ̀-èdè alágbára nìkan ló ní wọn láyé ìgbà kan, kí wọ́n sì wá dojú ewu kọ àwọn àgbègbè tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ń gbé.”
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ láìjìnnà sí àsìkò yìí, a mọ ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe fún ìran ènìyàn. Bíbélì ṣèlérí pé àkókò kan ń bọ̀ nígbà tí àwọn èèyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé yóò “máa gbé ní ààbò ní ti tòótọ́, [tí] ẹnikẹ́ni kò [sì] ní mú wọn wárìrì.” (Ìsíkẹ́lì 34:28) Tí o bá fẹ́ láti mọ púpọ̀ sí i nípa ìlérí tí ń tuni nínú yẹn, bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ sọ̀rọ̀ tàbí kó o kọ̀wé sí àdírẹ́sì tó yẹ lára èyí tó wà lójú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Àwọn olùṣèwádìí ti ń hùmọ̀ ọgbọ́n oríṣiríṣi láti lè fòpin sí ewu kòkòrò àrùn “anthrax”
[Credit Line]
Fọ́tò yìí wá nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Sandia National Laboratories
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Àpérò Lórí Àwọn Ohun Ìjà Oníkòkòrò Àrùn, èyí tó wáyé ní November 19, 2001, ní orílẹ̀-èdè Switzerland
[Credit Line]
Fọ́tò AP/Donald Stampfli
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Bíbélì ṣèlérí pé àkókò kan ń bọ̀ nígbà tí gbogbo èèyàn yóò “máa gbé ní ààbò”