Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Lo Òmìnira Tá A ní Láti Sèpinnu?
Ojú Ìwòye Bíbélì
Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Lo Òmìnira Tá A ní Láti Sèpinnu?
ỌLỌ́RUN fún àwọn ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, ní agbára láti lè dá ṣèpinnu fúnra wọn. Ó fi Ádámù ṣe alábòójútó ọgbà Édẹ́nì. Lára iṣẹ́ tí Ọlọ́run fún Ádámù ṣe ni pé kó sọ àwọn ẹranko ní orúkọ tí wọn yóò máa jẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì 2:15, 19) Èyí tó wá jẹ́ pàtàkì ibẹ̀ ni pé, Ádámù àti Éfà lómìnira láti pinnu bóyá kí àwọn ṣègbọràn sí Ọlọ́run tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.—Jẹ́nẹ́sísì 2:17, 18.
Látìgbà náà wá, àìlóǹkà ìpinnu làwọn èèyàn ti ṣe—ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìpinnu wọ̀nyí dára, àwọn kan burú, àwọn mìíràn sì bògìrì. Díẹ̀ lára àwọn ìpinnu tí kò mọ́gbọ́n dání táwọn èèyàn ṣe ti fa aburú ńlá. Síbẹ̀, láìka gbogbo èyí sí, Ọlọ́run kò fìgbà kan rí gba ẹ̀tọ́ tó fún wa láti ṣèpinnu lọ́wọ́ wa. Níwọ̀n bí òún ti jẹ́ Baba onífẹ̀ẹ́, ó pèsè ìrànlọ́wọ́ fún wa nípasẹ̀ Bíbélì ká lè ṣe àwọn ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Ó tún ṣe kìlọ̀kìlọ̀ fún wa nípa ohun tí ṣíṣe àwọn ìpinnu tí kò bọ́gbọ́n mu máa yọrí sí. Bíbélì sọ pé ohun táa bá gbìn la óò ká.—Gálátíà 6:7.
Ṣíṣe Àwọn Ìpinnu Ara Ẹni
Nínú àwọn ọ̀ràn kan, Ọlọ́run máa ń dìídì jẹ́ ká mọ ohun tí òun fẹ́ nípa fífún wa ní àwọn ìtọ́sọ́nà pàtó. Àmọ́ nínú àwọn ọ̀ràn tó pọ̀ jù lọ, Bíbélì ò gbé àwọn òfin kalẹ̀ láti máa darí
gbogbo ohun tá a bá ń ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fún wa ní ìlànà tó gbòòrò, èyí tó fún kálukú láyè láti ṣe ohun tó wù ú àti ohun tó bá ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ mu. Bí àpẹẹrẹ, wo ohun tó sọ lórí ọ̀ràn eré ìtura.Ìwé Mímọ́ pe Jèhófà ní “Ọlọ́run aláyọ̀.” (1 Tímótì 1:11) Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé “ìgbà rírẹ́rìn-ín wà,” “ìgbà títọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri” sì wà. (Oníwàásù 3:1, 4) Bíbélì sọ fún wa pé Ọba Dáfídì kọ orin fún ìgbádùn àwọn ẹlòmíràn. (1 Sámúẹ́lì 16:16-18, 23) Jésù lọ síbi àsè ìgbéyàwó kan, ó sì mú kí ayẹyẹ ìgbéyàwó náà lárinrin sí i nípa sísọ omi di ọtí wáìnì.—Jòhánù 2:1-10.
Àmọ́ ṣá o, Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” (Òwe 13:20) “Ìṣẹ̀fẹ̀ rírùn” àtàwọn ìwà pálapàla máa ń múnú bí Ọlọ́run ó sì lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́. (Éfésù 5:3-5) Béèyàn bá ń mu ọtí líle láìbojúwẹ̀yìn níbi àríyá, àwọn ìṣòro ńláǹlà lè tìdí rẹ̀ yọ. (Òwe 23:29-35; Aísáyà 5:11, 12) Jèhófà Ọlọ́run tún kórìíra ìwà ipá.—Sáàmù 11:5; Òwe 3:31.
Àwọn ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ohun tó jẹ́ ojú ìwòye Ọlọ́run nípa eré ìtura. Nígbà tí àwọn Kristẹni bá ń ṣe ìpinnu, wọ́n máa ń fi ohun tí Bíbélì sọ sọ́kàn. Dájúdájú, gbogbo wa ni yóò dáhùn fún àwọn ohun tó bá jẹ́ àbájáde ìpinnu tá a fúnra wa ṣe, ì báà jẹ́ rere tàbí búburú.—Gálátíà 6:7-10.
Lọ́nà kan náà, a rọ àwọn Kristẹni láti máa ṣe àwọn ìpinnu ọlọ́gbọ́n, èyí tó bá àwọn ìlànà Bíbélì mu lórí àwọn ọ̀ràn tó ní í ṣe pẹ̀lú aṣọ wíwọ̀, ìgbéyàwó, ọmọ títọ́, àti ọ̀ràn iṣẹ́ ajé. Èyí kan àwọn ọ̀ràn tí Ìwé Mímọ́ ò sọ ohun kan pàtó nípa wọn, síbẹ̀ tó jẹ́ pé àwọn ìlànà tó wà nínú rẹ̀ lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tá a gbé karí ẹ̀rí ọkàn. (Róòmù 2:14, 15) Nínú gbogbo ìpinnu ara ẹni tí àwọn Kristẹni bá ń ṣe, wọ́n gbọ́dọ̀ máa fi ìlànà yìí sílò, tó sọ pé: “Yálà ẹ ń jẹ tàbí ẹ ń mu tàbí ẹ ń ṣe ohunkóhun mìíràn, ẹ máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.”—1 Kọ́ríńtì 10:31.
Ìlànà kan tún wà tó yẹ ká máa fi sọ́kàn nínú ọ̀ràn ṣíṣe ìpinnu ara ẹni, òun ni pé ‘kí a má ṣe máa yọjú sí ọ̀ràn ọlọ́ràn.’ (1 Tẹsalóníkà 4:11) Nínú ṣíṣe ìpinnu ara ẹni, onírúurú ìpinnu tí kò ta ko ìfẹ́ Ọlọ́run ló sábà máa ń wà fún àwọn Kristẹni láti ṣe. Nípa bẹ́ẹ̀, ohun tó wu Kristẹni kan lè máà jẹ́ ohun tó máa wu àwọn mìíràn. Kò ní dùn mọ́ Ọlọ́run nínú rárá láti rí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kí wọ́n máa dá ara wọn lẹ́jọ́. (Jákọ́bù 4:11, 12) Bíbélì fún wa ní ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n yìí pé: “Kí ẹnikẹ́ni nínú yín má jìyà gẹ́gẹ́ bí . . . olùyọjúràn sí ọ̀ràn àwọn ẹlòmíràn.”—1 Pétérù 4:15.
Ìpinnu Láti Sin Ọlọ́run
Léraléra ni Bíbélì sọ nípa àwọn àǹfààní tó wà nínú ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run. Síbẹ̀, Ọlọ́run kò fipá mú àwọn èèyàn láti sin òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń ké sí àwọn èèyàn tó jẹ́ ẹ̀dá ọwọ́ rẹ̀ láti wá di olùjọ́sìn òun. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé: “Ẹ wọlé wá, ẹ jẹ́ kí a jọ́sìn, kí a sì tẹrí ba; ẹ jẹ́ kí a kúnlẹ̀ níwájú Jèhófà Olùṣẹ̀dá wa.”—Sáàmù 95:6.
Irú ìkésíni yìí la nawọ́ rẹ̀ sí Ísírẹ́lì ìgbàanì. Ní ohun tó lé lẹ́gbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ [3,500] ọdún sẹ́yìn, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì dúró níwájú Òkè Sínáì, Ọlọ́run sì jẹ́ kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn náà mọ̀ nípa ìlànà tó wà fún ìjọsìn tòótọ́ tá a fi hàn nínú Òfin Mósè. Wọ́n ní láti ṣe ìpinnu kan: Ṣé wọ́n á sin Ọlọ́run àbí wọn kò ní sìn ín? Kí ni ìdáhùn wọn? Gbogbo wọn ló panu pọ̀ sọ pé: “Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ ni àwa múra tán láti ṣe, a ó sì jẹ́ onígbọràn.” (Ẹ́kísódù 24:7) Àwọn fúnra wọn ló pinnu láti jọ́sìn Jèhófà.
Ní ọ̀rúndún kìíní, Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Mátíù 4:17; 24:14) Kò fipá mú ẹnikẹ́ni láti wá dara pọ̀ mọ́ òun nínú iṣẹ́ yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló fi pẹ̀lẹ́tù ké sí àwọn mìíràn pé: “Wá di ọmọlẹ́yìn mi.” (Máàkù 2:14; 10:21) Ọ̀pọ̀ tẹ́wọ́ gba ìkésíni rẹ̀ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wàásù pẹ̀lú rẹ̀. (Lúùkù 10:1-9) Lẹ́yìn àkókò díẹ̀, àwọn kan pinnu láti fi Jésù sílẹ̀. Júdásì pinnu láti dà á. (Jòhánù 6:66; Ìṣe 1:25) Lẹ́yìn náà, lábẹ́ ìtọ́sọ́nà àwọn àpọ́sítélì, ọ̀pọ̀ èèyàn púpọ̀ sí i di ọmọ ẹ̀yìn, kì í ṣe nípa fífi idà halẹ̀ mọ́ wọn, bí kò ṣe nípa lílo òmìnira tí wọ́n ní. Wọ́n ní “ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́” wọ́n sì “di onígbàgbọ́.” (Ìṣe 13:48; 17:34) Ọ̀rọ̀ kò yàtọ̀ lónìí náà, torí pé tinútinú wọn làwọn Kristẹni tòótọ́ fi ń ṣègbọràn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé àwọn ẹ̀kọ́ Jésù.
Ó ti wá ṣe kedere pé, Ọlọ́run fẹ́ ká lo agbára tó fún wa láti ṣe ìpinnu. Ó tún pèsè ìtọ́sọ́nà nínú Bíbélì, èyí tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu ọlọgbọ́n. (Sáàmù 25:12) Nígbà tó bá sì dọ̀ràn ṣíṣe ìpinnu ara ẹni, Kristẹni kọ̀ọ̀kan ní láti gbé àwọn ìlànà tí Ọlọ́run pèsè yẹ̀ wò dáadáa. Ọ̀nà yẹn nìkan ṣoṣo la fi lè máa ṣe ‘iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ [sí Ọlọ́run] pẹ̀lú agbára ìmọnúúrò wa.’—Róòmù 12:1.