Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Nígbà Tí Iléeṣẹ́ Kan Tó Ń Ṣe Kẹ́míkà Bú Gbàù

Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Nígbà Tí Iléeṣẹ́ Kan Tó Ń Ṣe Kẹ́míkà Bú Gbàù

Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Nígbà Tí Iléeṣẹ́ Kan Tó Ń Ṣe Kẹ́míkà Bú Gbàù

LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ILẸ̀ FARANSÉ

NÍ SEPTEMBER 21, 2001, ìyẹn ọjọ́ mẹ́wàá péré lẹ́yìn tí àjálù ńlá já lu ilé ìtajà tó tóbi jù lọ lágbàáyé, tá a mọ̀ sí World Trade Center nílùú New York, iléeṣẹ́ tó ń ṣe kẹ́míkà kan ṣàdédé bú gbàù tó sì ba ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan jẹ́ ní gbogbo ìgbèríko Toulouse, ìyẹn ìlú kan tó wà ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Faransé. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni ìwé ìròyìn ilẹ̀ Faransé náà, Le Point ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí “Jàǹbá tó burú jù lọ tó tíì ṣẹlẹ̀ ní iléeṣẹ́ èyíkéyìí nílẹ̀ Faransé látìgbà Ogun Àgbáyé Kejì.”

Nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún tọ́ọ̀nù ajílẹ̀ ló bú gbàù, tó sì dáhò roboto tó fẹ̀ ní àádọ́ta mítà tó sì jìn ní mítà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sínú ilẹ̀. Ìbúgbàù náà àti afẹ́fẹ́ gbígbóná tó tẹ̀ lé e pa ọgbọ̀n èèyàn, àwọn tó ju ẹgbẹ̀rún méjì ó lé igba [2,200] lọ ló sì fara pa. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ilé ló bà jẹ́ ráúráú tí ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin [27,000] àwọn ilé mìíràn tó wà ní kìlómítà mẹ́jọ síbi ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sì bà jẹ́ gan-an. Jìnnìjìnnì bo àwọn èèyàn nítorí wọ́n ń rò pé àwọn apániláyà ló tún dé, wọ́n sì tún ń rò pé gáàsì olóró ló ń fẹ́ jáde láti inú iléeṣẹ́ náà.

Àwọn mélòó kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fara pa, tí ọ̀pọ̀ nínú wọn sì fara gbá nínú ìbúgbàù náà lọ́nà míì. Ìfẹ́ Kristẹni sún àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ wọn láti ṣètò lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti ràn wọ́n lọ́wọ́. (Jòhánù 13:34, 35) Àwọn àkọsílẹ̀ tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí fi akitiyan tí wọ́n ṣe hàn.

“Iléeṣẹ́ Náà Jó Kanlẹ̀”

Khoudir jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n la ìjábá iléeṣẹ́ kẹ́míkà yìí já. Egungun àgbọ̀n rẹ̀ fọ́, èjìká rẹ̀ sì yẹ̀ nígbà tí àwọn pàǹtírí tó ń fò kiri láti ibi àwókù náà gbá a tó sì dákú lọ gbári. Benjamin, ẹni tí ibi iṣẹ́ rẹ̀ wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ iléeṣẹ́ náà ni ìbúgbàù náà fi sọ̀kò ní mítà mẹ́ta gba inú ọ́fíìsì kan tó sì lọ sọ ọ́ lu ògiri tó wà lódìkejì. Àfọ́kù gíláàsì tó ń ta káàkiri bẹ́ ẹ lára yánnayànna, ó sì fọ́ ọ lójú ọ̀tún. Ó sọ pé: “Ọlọ́run ló yọ mí pé àyè mi kọ́ ni mo wà. Bíríkì tó wúwo tó nǹkan bí ẹgbẹ̀ta [600] kìlógíráàmù ló wó bo àga mi mọ́lẹ̀.”

Olùkọ́ kan tó ń jẹ́ Alain ní ilé ẹ̀kọ́ kan tí kò ju igba mítà sí iléeṣẹ́ náà ń fi ẹ̀rọ ṣe àdàkọ ìwé lọ́wọ́ lákòókò tílé iṣẹ́ náà bú gbàù. Ó sọ pé: “Iléeṣẹ́ náà jó kanlẹ̀, kìkì irin wọ́nganwọ̀ngan lo ṣẹ́ kù. Kí ní ń jẹ́ ògiri, ká má tiẹ̀ tún sọ̀rọ̀ òrùlé, gbogbo ẹ̀ ni iná sun. Àfọ́kù gíláàsì ṣe mí léṣe. Ńṣe ló gé mi lójú yánnayànna. Bí ìgbà tí wọ́n bá fi kóńdó lu èèyàn lójú ló rí.” Ìbúgbàù náà sọ Alain di olójú kan, kò sì jẹ́ kó gbọ́ran dáadáa mọ́.

Ìrànlọ́wọ́ Ojú Ẹsẹ̀

Kíá làwọn alàgbà ìjọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́kànlá tí ìjábá náà dé bá kàn sí àwọn ará ìjọ wọn níkọ̀ọ̀kan láti lè mọ ẹni tó fara gbọgbẹ́ àti ẹni tílé ẹ̀ bà jẹ́. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n rán àwọn to yọ̀ǹda ara wọn lọ bá àwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́ jù lọ. Àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni náà wá rí i pé nǹkan bí ọgọ́ta ilé àwọn Ẹlẹ́rìí ló ti bà jẹ́, wọ́n sì ran àwọn ìdílé bíi mẹ́wàá lọ́wọ́ láti rílé mìíràn kó sí. Àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni wọ̀nyí tún bá wọn tún Gbọ̀ngàn Ìjọba méjì tó ti bà jẹ́ ṣe. Láfikún sí i, wọ́n tún bá wọn ṣètò bí wọ́n á ṣe rí ìrànlọ́wọ́ iléeṣẹ́ ìbánigbófò.

Ilé kan ní ìsọdá iléeṣẹ́ náà ni Catherine àti Michel ń gbé. Catherine ń wakọ̀ bọ̀ lákòókò tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀. Ó sọ pé: “Bíi pé ilẹ̀ ń mì tìtì la kọ́kọ́ rò pé ó jẹ́. Àmọ́ ká tó ṣẹ́jú pẹ́ la bá gbọ́ ìró nǹkan tó bú gbàù. Lẹ́yìn náà la wá rí èéfín tó ń rú lọ sókè. Mo wa mọ́tò mi dé àdúgbò wa; ńṣe ló dà bí ìgbà téèyàn wà lójú ogun gẹ́lẹ́. Gbogbo ilé tó wà ládùúgbò ni páànù ẹ̀ ká dà nù, tí fèrèsé àwọn ilé ìtajà sì fọ́ yángá. Ó wá di bó ò lọ o yà fún mi lójú pópó. Ńṣe làwọn kan jókòó sórí títì, táwọn míì sì ń yí gbirigbiri nílẹ̀, tí wọ́n ń sunkún. Gbogbo fèrèsé tó wà nílé wa àti férémù wọn ló gbọ̀n dà nù, títí kan àwọn ilẹ̀kùn. Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tá a jọ jẹ́ Kristẹni lára wa, kíá ni wọ́n wá ràn wá lọ́wọ́. Nígbà tó máa fi di ọ̀sán, àwọn ará ìjọ wa kan rọ́ dé pẹ̀lú korobá àti ìgbálẹ̀ lọ́wọ́ wọn, wọ́n tún gbé àwọn nǹkan oníke pẹlẹbẹ dání kí wọn lè fi dí ojú fèrèsé wa.”

Ẹ̀gbẹ́ iléeṣẹ́ náà ni Alain àti Liliane pẹ̀lú ń gbé. Ìbúgbàù náà sọ ibùgbé wọn di ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀. Alain sọ pé: “Gbogbo nǹkan wa ló fọ́ sí wẹ́wẹ́. Ògiri wa àti nǹkan aláwo tí wọ́n lẹ̀ mọ́ ọn fọ́, gbogbo àga, ilẹ̀kùn, fèrèsé àti ohun ọ̀ṣọ́ inú ilé ló sì bà jẹ́ pátápátá. Kò sí nǹkankan tó ṣẹ́ kù fún wa. Lójú ẹsẹ̀ làwọn Kristẹni arákùnrin wa rọ́ dé kí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́. Àwọn ló kó gbogbo àwókù náà dà nù tí wọ́n sì bá àwọn mìíràn lára àwọn olùgbé ilé náà kó ti yàrá wọn. Ẹnu ya àwọn aládùúgbò láti rí ògìdìgbó àwọn tó wá ràn wá lọ́wọ́.” Láàárọ̀ ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan pe Alain lórí fóònù ó sì sọ fún un pé kó wá bá òun ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Liliane ní tiẹ̀ lọ ṣe àwọn nǹkan nígboro. Nítorí náà, kò sẹ́ni tó wà nílé nínú àwọn méjèèjì lákòókò tí iléeṣẹ́ náà bú gbàù.

Kì í ṣe àwọn ará ìjọ wọn nìkan làwọn Ẹlẹ́rìí ràn lọ́wọ́ o. Lẹ́yìn tí wọ́n ti ran ara wọn lọ́wọ́ tán, wọ́n tún bá àwọn aládùúgbò wọn palẹ̀ àwọn àwókù tó wà nínú ilé wọn mọ́, wọ́n sì bá wọn fi nǹkan dí ojú fèrèsé wọn. Àwọn aládùúgbò mọrírì ìrànlọ́wọ́ yìí gan-an ni, ẹnu sì yà wọ́n bí wọn ò ṣe béèrè kọ́bọ̀ lọ́wọ́ wọn.

Wọ́n tún ran àwọn aláṣẹ ìbílẹ̀ ibẹ̀, tí gbogbo àwọn nǹkan tó bà jẹ́ nílùú ti tojú sú pàápàá lọ́wọ́. Àwọn Ẹlẹ́rìí palẹ̀ ìdọ̀tí tó wà láwọn ilé ẹ̀kọ́ àtàwọn ilé tó wà fún gbogbo èèyàn mọ́. Ní àdúgbò kan níbẹ̀, àwọn aláṣẹ ìbílẹ̀ rán àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí láti máa lọ láti ojúlé dé ojúlé láti yẹ ipò táwọn èèyàn wà wò.

Pípèsè Ìrànlọ́wọ́ Nípa Tẹ̀mí

Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń gbé lágbègbè ibi ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló nílò ìrànlọ́wọ́ nípa tẹ̀mí ní àfikún sí ìrànlọ́wọ́ nípa tara. Látàrí èyí, àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà àdúgbò ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ gbogbo àwọn tí ìjábá náà kàn. Àwọn ará mọrírì ìtìlẹ́yìn yìí lọ́pọ̀lọpọ̀. Catherine sọ pe: “Àwọn alàgbà ò fi wá sílẹ̀ rárá. Wọ́n wá fún wa níṣìírí. Ká sọ tòótọ́, ohun tá a nílò gan-an nìyẹn, ó ṣe pàtàkì ju nǹkan tara lọ.”

Ìfẹ́ Kristẹni tí wọ́n fi han lẹ́yìn tí ìjábá yìí ṣẹlẹ̀ fa àwọn ọ̀rọ̀ ìwúrí. Ẹlẹ́rìí kan tó fara gbọgbẹ́ gan-an sọ pé: “Kò sí bá a ṣe lè mọ ohun tí ọ̀la yóò mú wá. A gbọ́dọ̀ máa sin Jèhófà bí ẹni pé òní la óò wà láàyè mọ.” (Jákọ́bù 4:13-15) Ẹlẹ́rìí mìíràn parí ọ̀rọ̀ nígbà tó sọ pé: “Gbogbo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti mọ̀ pé a ò gbọ́dọ̀ sọ pé nǹkan tara la óò bá kú. Àárín àwọn èèyàn Jèhófà lèèyàn ti lè rí ohun tó ṣe iyebíye jù lọ.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Benjamin àti Khoudir

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Alain

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Àwòrán ìlú Toulouse nìyí, lọ́jọ́ kejì ìbúgbàù náà

[Credit Line]

© LE SEGRETAIN PASCAL/CORBIS SYGMA

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Alain àti Liliane