Ìmọ̀ràn Àtàtà fún Àwọn Ọ̀dọ́
Ìmọ̀ràn Àtàtà fún Àwọn Ọ̀dọ́
Nígbà tí Bill, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fi ìwé ìròyìn lọni nítòsí ilé ẹjọ́ kan ní ìpínlẹ̀ California, ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ọkùnrin kan wá bá a ó sì sọ fún un pé kó jẹ́ kí òun rí gbogbo ẹ̀dà ìwé ìròyìn Jí! tó ní lọ́wọ́. Bill sọ pé: “Ṣáájú ìgbà yẹn, àwọn kan nínú ìjọ wa ti kó àwọn ìwé ìròyìn tọ́jọ́ wọn ti pẹ́ díẹ̀ fún mi, nípa bẹ́ẹ̀ ó ṣeé ṣe fún mi láti rí ọ̀kan-ò-jọ̀kan ìwé ìròyìn láti fi han ọkùnrin náà.
“Kíákíá ni ọkùnrin yìí yanjú àwọn ìwé ìròyìn náà sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ tó sì ṣa gbogbo àwọn tí kò tíì kà jọ gègèrè. Ó béèrè bóyá òun lè gba gbogbo wọn. Ó sọ pé òṣìṣẹ́ ilé ẹjọ́ ìjọba ìbílẹ̀ náà ni òun àti pé òun lòún máa ń gba àwọn ọ̀dọ́ tó bá wà nínú ìṣòro nímọ̀ràn. Ó ṣàlàyé pé ìdí tí òun fi ń gba Jí! ni láti lè ṣe ẹ̀dà àwọn àpilẹ̀kọ ‘Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé’ tó máa ń wà nínú rẹ̀. Lẹ́yìn náà, yóò tò wọ́n níbàámu pẹ̀lú kókó tí wọ́n jíròrò, yóò sì kó wọn sí àrọ́wọ́tó rẹ̀ láti máa fún àwọn ọ̀dọ́ tó ń gbà nímọ̀ràn. Ọkùnrin náà sọ pé: ‘Àwọn ìṣòro tó ń dààmú àwọn ọ̀dọ́ ayé òde òní gẹ́lẹ́ ni àwọn kókó tí wọ́n jíròrò dá lé.’ Ó wá gbóríyìn fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún títẹ̀ tí wọ́n ń tẹ irú àwọn ìsọfúnni tó wúlò bẹ́ẹ̀ jáde láti fi ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́. Ó fi kún un pé, òun á máa wò mí níbẹ̀ lóòrèkóòrè láti gba àwọn ìwé ìròyìn Jí! tuntun èyíkéyìí tí mo bá lè rí fún òun.”
Púpọ̀ lára àwọn ìsọfúnni tá a ti tẹ̀ jáde nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè” wà nínú ìwé náà, Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́. O lè béèrè fún ẹ̀dà kan ìwé olójú ewé 320 yìí nípa kíkàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.