Kí Nìdí Tí Wọ́n Fi Fi Mí Sọ́dọ̀ Alágbàtọ́?
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Kí Nìdí Tí Wọ́n Fi Fi Mí Sọ́dọ̀ Alágbàtọ́?
“Ńṣe ló dà bíi pé èèyàn ní àbùkù ara kan tó máa wà títí ayé. Ọgbẹ́ ọkàn tí kò lè sàn ni.”—Robert.
ỌKÙNRIN kan, tí wọ́n lọ fi sí ọ̀dọ̀ alágbàtọ́ lẹ́yìn tí wọ́n bí i, ló sọ ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí láti ṣàpèjúwe bí ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe rí. Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ọjọ́ ayé rẹ ni àwọn ìbéèrè kan tó ń fẹ́ ìdáhùn á máa jà gùdù lọ́kàn rẹ, irú bí, Àwọn wo gan-an ni ìdílé mi? Ibo ni wọ́n ń gbé? Kí nìdí tí wọ́n fi gbé mí fún ẹlòmíràn?”
Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Chantial, ẹni tí ìdílé kan gba bàbá rẹ̀ tọ́ nígbà tó wà lọ́mọdé, máa ń kédàárò pé òun kò mọ àwọn òbí òun àgbà. Ó sọ pé: “Mo máa ń nímọ̀lára pé wọ́n rẹ́ mi jẹ torí pé mi ò ní ìfararora pẹ̀lú àwọn mọ̀lẹ́bí àti ìbátan mi.” Kì í ṣe gbogbo àwọn ọmọ tí wọ́n gbà tọ́ ló máa ń ní irú ìmọ̀lára yìí. Ṣùgbọ́n àwọn kan máa ń ronú bẹ́ẹ̀. Kí nìdí?
Ipò Tí Wọ́n Wà Ń Mú Wọn Bínú
Mímọ̀ tí ọmọ kan mọ̀ pé òun kò sí lọ́dọ̀ ìdílé òun gan-gan lè jẹ́ kó máa ní ẹ̀dùn ọkàn ńláǹlà. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Catrina, ẹni tí ìdílé kan gbà tọ́ nígbà tó ṣì kéré gan-an, sọ pé: “Inú máa ń bí mi torí pé mi ò mọ ìdí tí ìyá tó bí mi lọ́mọ fi ní láti mú mi sọ́dọ̀ èèyàn kan. Mo ronú pé bóyá nítorí pé mi ò lẹ́wà rárá ni ìyá mi ṣe pa mí tì. Ká ní ó lè tọ́ mi fúnra rẹ̀ ni, mo mọ̀ pé mo lè ṣe é tó jẹ́ pé á máa fi mí yangàn. Gbogbo ìgbà tí mo bá ń rántí ìyá tó bí mi ni inú mi máa ń ru ṣùṣù.”
Bákan náà, àárín Catrina àtàwọn òbí tó ń gbà á tọ́ kò gún rárá. Ó sọ pé: “Mo máa ń ronú pé ńṣe làwọn òbí tó gbà mí tọ́ já mi gbà lọ́wọ́ ìyá tó bí mi. Nítorí náà, àwọn ni mò ń fi ìkanra mọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ọmọ tí wọ́n bá fi sọ́dọ̀ ẹlòmíràn máa ń bínú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nítorí ipò tí wọ́n bá ara wọn.
Sáàmù 37:8) Báwo ni ìyẹn ṣe lè ṣeé ṣe? Ó dára, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kan náà ló tún sọ pé: “Ìjìnlẹ̀ òye tí ènìyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ dájúdájú.” (Òwe 19:11) Ríronú jinlẹ̀ nípa ipò rẹ lè mú kí ìbínú rẹ rọlẹ̀. Lọ́nà wo?
Irú ìbínú bẹ́ẹ̀ léwu. Nígbà míì, gẹ́gẹ́ bí ìrírí Catrina ti fi hàn, ó ṣeé ṣe kó o máa bínú láìtọ́ tàbí kó o máa fi ìkanra mọ́ àwọn ẹni tí kò ṣẹ̀ ọ́. Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn pé: “Jáwọ́ nínú ìbínú, kí o sì fi ìhónú sílẹ̀.” (Mímú Èrò Tí Kò Tọ́ Kúrò Lọ́kàn
Ríronú jinlẹ̀ nípa ipò rẹ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ àwọn ohun tó máa ń súnná sí ìbínú rẹ. Bí àpẹẹrẹ, bó bá jẹ́ pé ọ̀dọ̀ alágbàtọ́ lo wà, ṣé o rò pé torí pé o ní àbùkù kan lára làwọn òbí tó bí ọ ṣe fi ọ sọ́dọ̀ ẹlòmíràn? Ohun tó wà lọ́kàn Catrina nìyẹn. Àmọ́ ǹjẹ́ gbogbo ìgbà ló máa ń jẹ́ pé torí ìdí yẹn làwọn òbí ṣe ń fi ọmọ wọn sọ́dọ̀ alágbàtọ́? Ó lè má ṣeé ṣe fún ọ láti mọ ohun náà gan-an tó mú kí àwọn òbí rẹ ṣe ohun tí wọ́n ṣe, síbẹ̀síbẹ̀, ó yẹ kó o yẹra fún níní irú àwọn èrò tí kò tọ̀nà bẹ́ẹ̀. Ó dára ná, kí ló máa ń sábà mú kí àwọn òbí fi àwọn ọmọ wọn sọ́dọ̀ ẹlòmíràn láti tọ́? Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń ronú pé kò sí ohun mìíràn tí àwọn lè ṣe mọ́.
Ronú nípa àpẹẹrẹ Mósè. Àkọsílẹ̀ Bíbélì nínú ìwé Ẹ́kísódù orí kejì jẹ́ ká mọ̀ pé, nígbà tí Fáráò ọba ilẹ̀ Íjíbítì pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn ọmọ ọkùnrin tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, Jókébédì fi Mósè, ọmọ rẹ̀ jòjòló pa mọ́ fún oṣù mẹ́ta. Níkẹyìn, kò ṣeé ṣe láti tọ́jú rẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n, ara rẹ̀ kò gbà á kí wọ́n pa ọmọ náà. Nítorí náà, “nígbà tí kò tún lè pa á mọ́ mọ́, nítorí rẹ̀, ó wá mú àpótí tí a fi òrépèté ṣe, ó sì fi ọ̀dà bítúmẹ́nì dídì àti ọ̀dà bítúmẹ́nì rírọ̀ rẹ́ ẹ, ó sì gbé ọmọ náà sínú rẹ̀, ó sì gbé e sáàárín àwọn esùsú ní bèbè Odò Náílì.”—Ẹ́kísódù 2:3.
Kò sí àní-àní pé bó ṣe gbé ọmọ rẹ̀ síbì kan yìí máa ṣòro fún un gan-an. Àmọ́ ǹjẹ́ ohun mìíràn tún wà tó lè ṣe? Ìfẹ́ tó ní sí ọmọ rẹ̀ ló mú kó ṣe ohun tó rò pé ó dára jù fún un. Ó dùn mọ́ni pé, ọmọbìnrin rẹ̀ wà nítòsí tó ń ṣọ́ ọ, ó sì dúró tì í títí dìgbà tó rí i pé ẹni tí kò lè ṣèpalára fún àbúrò òun ló wá gbé e. Àfàìmọ̀ ni kò jẹ́ pé ìyá rẹ̀ tó ń ṣàníyàn nípa ọmọ ọwọ́ náà ló sọ fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Ká sòótọ́, kì í ṣe gbogbo ìgbà tí wọ́n bá fi ẹnì kan sọ́dọ̀ alágbàtọ́ ló máa ń jẹ́ pé ọ̀ràn pàjáwìrì bí irú èyí ló fà á, àmọ́ àwọn ohun tó fara jọ èyí ló sábà máa ń sún àwọn òbí ṣe bẹ́ẹ̀. Robert sọ pé: “Ńṣe ni ìyá mi gboyún mi. Títọ́ mi dàgbà ì bá ti nira gan-an fún ìyá mi torí pé àwọn ọmọ mìíràn wà nínú ìdílé rẹ̀ yàtọ̀ sí èmi. Ìyá mi lè wò ó pé
màá rí ìtọ́jú tó dára bí òun bá gbé mi sọ́dọ̀ ẹnì kan láti máa tọ́jú mi.”Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń mú kí àwọn òbí mú àwọn ọmọ wọn sọ́dọ̀ ìdílé mìíràn láti tọ́. Àmọ́ bí àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí ṣe fi hàn, kì í wulẹ̀ ṣe tìtorí pé ìyá kan kórìíra ọmọ rẹ̀ tàbí pé ó rí àbùkù kan lára rẹ̀ ló ṣe gbé e fún ẹlòmíràn. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìyá náà gbà gbọ́ tọkàntọkàn pé ọmọ òun á rí ìtọ́jú yíyẹ gbà bí ìdílé mìíràn bá tọ́ ọ dàgbà.
Mímọ̀ Pé Àwọn Èèyàn Nífẹ̀ẹ́ Rẹ Yóò Ṣe Ọ Láǹfààní
Ríronú jinlẹ̀ dáadáa tún lè ràn ọ́ lọ́wọ́ nígbà tó o bá ronú nípa ìdí tí ìdílé kan fi gbà ọ́ tọ́. Tún gbé àpẹẹrẹ Mósè yẹ̀ wò ná. Bí àkókò ti ń lọ, “ọmọbìnrin Fáráò gbé e, ó sì tọ́ ọ dàgbà gẹ́gẹ́ bí ọmọkùnrin òun fúnra rẹ̀.” (Ìṣe 7:21) Kí ló sún ọmọbìnrin Fáráò láti pinnu pé òun á dáàbò bo ọmọ kékeré kan tó mọ̀ pé ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀yà Hébérù tí wọ́n fẹ́ pa? Bíbélì sọ pé: “Ọmọdékùnrin náà ń sunkún. Látàrí èyí, ó yọ́nú sí i.” (Ẹ́kísódù 2:6) Ó ṣe kedere pé, ohun tó mú kí Mósè di ẹni tí wọ́n gbà tọ́ kì í ṣe nítorí pé wọ́n kórìíra rẹ̀ tàbí pé wọ́n pa á tì, àmọ́ ó jẹ́ torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.
Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ tí wọ́n gbà tọ́ ló máa ń mọ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé kì í ṣe pé ńṣe làwọn òbí tó bí wọn wulẹ̀ pa wọ́n tì bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí sábà máa ń ṣẹlẹ̀ lónìí—kàkà bẹ́ẹ̀, nítorí kí wọ́n lè rí ìtọ́jú yíyẹ ni wọ́n ṣe lọ fi wọ́n sọ́dọ̀ àwọn àjọ tó ń bójú tó ọmọ. Bákan náà, gbígbà tí ẹnì kan gbà wọ́n tọ́ jẹ́ nítorí pé ẹnì kan ṣì nífẹ̀ẹ́ sí wọn débi pé ó gbà láti tọ́jú wọn. Ǹjẹ́ kì í ṣe pé bí ọ̀ràn tìrẹ náà ṣe rí nìyẹn? Ríronú lórí ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn sí ọ àti fífi ìmọrírì hàn fún èyí lè jẹ́ kí ẹ̀dùn ọkàn tó o ní dín kù.
Láfikún sí i, àwọn ẹlòmíràn lè máa fi ìfẹ́ hàn sí ọ yàtọ̀ sí ìdílé tó gbà ọ́ tọ́. Bó o bá jẹ́ ara ìjọ Kristẹni, wàá láǹfààní láti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyá, bàbá, arábìnrin àti arákùnrin tó nífẹ̀ẹ́ rẹ. (Máàkù 10:29-30) Àwọn alàgbà Kristẹni “dà bí ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù àti ibi ìlùmọ́ kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò, bí àwọn ìṣàn omi ní ilẹ̀ aláìlómi, bí òjìji àpáta gàǹgà ní ilẹ̀ gbígbẹ táútáú.” (Aísáyà 32:2) Má ṣe lọ́ra láti wá àwọn Kristẹni bíi tìrẹ tó dàgbà dénú rí, kó o lè fọ̀ràn lọ̀ wọ́n. Jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ àti bí nǹkan ṣe rí lára rẹ.
Robert mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni. Ó sọ pé: “Mo ṣì máa ń nímọ̀lára pé mi ò já mọ́ nǹkan kan. Bó ti wù kó rí, ìfẹ́ tí ìdílé mi nípa tẹ̀mí ń fi hàn sí mi kò jẹ́ kí n máa fi bẹ́ẹ̀ gbé èyí sọ́kàn mọ́.”
O Lè Ṣàṣeyọrí
Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí èrò tí kò tọ̀nà máa gbilẹ̀ lọ́kàn rẹ. Lára èrò tí kò tọ̀nà tó o ní láti yẹra fún ni, ríronú pé kò lè dára fún ọ nítorí pé wọ́n gbà ọ́ tọ́. Irú àwọn èrò tí kò tọ̀nà bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ! (Òwe 24:10) Yàtọ̀ síyẹn, kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé bí ọ̀ràn ṣe máa rí nìyẹn.
Rántí pé Mósè lo àǹfààní tó wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ dáadáa. Bíbélì sọ pé: “Nítorí náà, Mósè ni a fún ní ìtọ́ni nínú gbogbo ọgbọ́n àwọn ará Íjíbítì. Ní ti tòótọ́, ó jẹ́ alágbára nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀.” (Ìṣe 7:22) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Mósè gba ìtọ́sọ́nà tẹ̀mí sínú—ìyẹn ni pé, ó kẹ́kọ̀ọ́ gan-an nípa Ọlọ́run débi pé, Jèhófà, Baba rẹ̀ ọ̀run wá jẹ́ ẹni gidi sí i. (Hébérù 11:27) Ǹjẹ́ ó ṣàṣeyọrí nínú ìgbésí ayé?
Bẹ́ẹ̀ ni o, torí pé nígbà tí Mósè dàgbà, ó di aṣáájú orílẹ̀-èdè ńlá kan tí àwọn olùgbé rẹ̀ tó mílíọ̀nù mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó di wòlíì, adájọ́, aláṣẹ, òpìtàn, alárinà májẹ̀mú Òfin, àti òǹkọ̀wé àwọn ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Bíbélì. Síwájú sí i, ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro fi hàn pé òun ló kọ ìwé Jóòbù àti Sáàmù orí àádọ́rùn-ún. Ká sòótọ́, Mósè gbé ayé tó nítumọ̀ gidigidi. Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ tí àwọn ẹlòmíràn gbà tọ́ náà máa ń ṣàṣeyọrí bákan náà, ìwọ náà sì lè ṣàṣeyọrí.
Robert tọ́ ọmọ méjì dàgbà ní àtọ́yege, ní báyìí, ó jẹ́ alàgbà kan nínú ìjọ Kristẹni. Nígbà tó rántí àwọn ọdún tó fi ń gbé lọ́dọ̀ ìdílé tó gbà á tọ́, ó sọ pé: “Mo ti wá mọ̀ pé kò yẹ kí n máa ronú ṣáá nípa ohun tí mi ò lè ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló yẹ kí n máa dúpẹ́ fún àwọn ìbùkún tí mo ní nísinsìnyí.”
Bó bá jẹ́ pé ọ̀dọ̀ alágbàtọ́ lò ń gbé, àwọn èrò tí kò tọ́ lè máa wá sí ọ lọ́kàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ṣùgbọ́n máa gbìyànjú láti fi àwọn èrò tó tọ́ rọ́pò wọn. Fílípì 4:8, 9 ṣèlérí pé, “Ọlọ́run àlàáfíà yóò . . . wà pẹ̀lú” rẹ bí o bá ń “bá a lọ ní gbígba” àwọn nǹkan tó dùn mọ́ Ọlọ́run nínú “rò.” Àmọ́, àwọn ìgbésẹ̀ dáradára wo lo tún lè gbé síwájú sí i láti ṣàṣeyọrí bó o ṣe ń gbé pẹ̀lú àwọn ìdílé tó gbà ọ́ tọ́? Àpilẹ̀kọ tó máa jáde lọ́jọ́ iwájú lórí kókó yìí yóò dáhùn ìbéèrè yẹn.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Gbígbà tí ẹnì kan gbà ọ́ tọ́ jẹ́ ẹ̀rí pé ẹnì kan ṣì nífẹ̀ẹ́ sí ọ débi pé ó gbà láti bójú tó ọ