Ìjọba Kan Tí Yóò Rọ̀ Mọ́ Àwọn Ìlànà Ọlọ́run
Ìjọba Kan Tí Yóò Rọ̀ Mọ́ Àwọn Ìlànà Ọlọ́run
FOJÚ inú wo ayé kan, níbi tó ti jẹ́ pé ìjọba kan ṣoṣo péré ló ń ṣàkóso lórí gbogbo ẹ̀yà àti èdè. Tún fojú inú wo ìjọba kan tí àwọn èèyàn mọ̀ fún bó ṣe máa ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó dára gan-an, tó sì tún
ń mú ogun, ìkórìíra, ìwà ọ̀daràn, ìṣẹ́, ìsọdèérí, àìsàn àti ikú pàápàá kúrò!O lè sọ pé ‘Ìyẹn dára gan-an, àmọ́ kò lè ṣeé ṣe.’ Àmọ́ o, ohun tó ṣeé ṣe ni. Kódà, ó dájú pé yóò rí bẹ́ẹ̀. Irú ìjọba yìí gan-an ni Jésù Kristi ṣèlérí rẹ̀. Ó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti máa gbàdúrà fún un báyìí pé: “Nítorí náà, kí ẹ máa gbàdúrà ní ọ̀nà yìí: ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́. Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.’”—Mátíù 6:9, 10.
Ó ṣeé ṣe kó o mọ àwọn ọ̀rọ̀ inú àdúrà yẹn dáadáa, nítorí pé ẹgbàágbèje èèyàn káàkiri ayé ló mọ̀ ọ́n tàbí kí wọ́n ti gbọ́ ọ rí. Àmọ́, ǹjẹ́ o tiẹ̀ ti ronú jinlẹ̀jinlẹ̀ rí nípa ohun tí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn túmọ̀ sí? Ṣàkíyèsí pé Ìjọba náà ní í ṣe pẹ̀lú mímú kí ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé. Nígbà náà, kí ni Ìjọba Ọlọ́run gan-an? Kí sì ni ìfẹ́ Ọlọ́run fún ilẹ̀ ayé wa?
Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Jẹ́
Ìjọba Ọlọ́run ni ètò tí Jèhófà Ọlọ́run máa lò láti fi ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ àgbáyé hàn. Ó jẹ́ ìjọba kan tí Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi jẹ́ olórí fún. Lọ́nà tó rọrùn láti lóye, Sáàmù 37:10, 11 sọ ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ilẹ̀ ayé wa, ó sọ pé: “Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́; dájúdájú, ìwọ yóò sì fiyè sí ipò rẹ̀, òun kì yóò sì sí. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”
Nítorí náà, bí gbogbo nǹkan bá tojú sú ọ nítorí bí àwọn ìlànà ayé yìí ṣe ń dìdàkudà, má bọkàn jẹ́. Bíbélì ṣèlérí pé láìpẹ́, ìyípadà tó ga lọ́lá máa dé bá ipò àwọn nǹkan nínú ayé àtàwọn ìlànà táráyé ń tẹ̀ lé. Ìlérí náà pé láìpẹ́ jọjọ Ìjọba Ọlọ́run yóò bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lórí ilẹ̀ ayé kí á lè máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run jẹ́ ìrètí tó dájú.
Mímọ bá a ṣe lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ìlérí Ìjọba Ọlọ́run lè túbọ̀ fi wá lọ́kàn balẹ̀ sí i. Ronú ná lórí àwọn ìlànà tí Ìjọba yẹn máa lò: “Ẹ wá wo àwọn ìgbòkègbodò Jèhófà, bí ó ti gbé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ayanilẹ́nu kalẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Ó mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 46:8, 9) Ìlèrí tó ń múnú ẹni dùn nípa àlááfíà àti ààbò lèyí mà jẹ́ o!
Nínú àsọtẹ́lẹ̀ kan tó dá lórí Jésù Kristi tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run yìí, Sáàmù 72:12-14 sọ pé: “Yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Òun yóò káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì, yóò sì gba ọkàn àwọn òtòṣì là. Yóò tún ọkàn wọn rà padà lọ́wọ́ ìnilára àti lọ́wọ́ ìwà ipá, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò sì ṣe iyebíye ní ojú rẹ̀.”
Àwọn Ìlànà Bíbélì
Gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára àwọn ìlànà tí Bíbélì rọ̀ wá láti mú lò: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Mátíù 5:3) Òmíràn ni pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.”—Òwe 3:5, 6.
Bíbélì tún kọ́ wa pé gbogbo wa pátá la máa jíhìn fún àwọn ìlànà tá a bá yàn láti máa tẹ̀ lé. Ronú lórí ohun tí Oníwàásù 11:9 sọ pé: “Máa yọ̀, ọ̀dọ́kùnrin, ní ìgbà èwe rẹ, sì jẹ́ kí ọkàn-àyà rẹ ṣe ọ́ ní ire ní àwọn ọjọ́ ìgbà ọ̀dọ́kùnrin rẹ, kí o sì máa rìn ní àwọn ọ̀nà ọkàn-àyà rẹ àti nínú àwọn ohun tí ojú rẹ bá rí. Ṣùgbọ́n mọ̀ pé ní tìtorí gbogbo ìwọ̀nyí ni Ọlọ́run tòótọ́ yóò ṣe mú ọ wá sínú ìdájọ́.” Láti fi hàn pé a óò jíhìn fún ohun tá a bá ṣe, Òwe 2:21, 22 sọ ọ́ ní ṣàkó pé: “Àwọn adúróṣánṣán ni àwọn tí yóò máa gbé ilẹ̀ ayé, àwọn aláìlẹ́bi sì ni àwọn tí a óò jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù sórí rẹ̀. Ní ti àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an; àti ní ti àwọn aládàkàdekè, a ó fà wọ́n tu kúrò lórí rẹ̀.”
Pẹ̀lú ìrètí tí ń fúnni níṣìírí yìí pé ìjọba òdodo kan ń bọ̀, ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ló máa jẹ́ tiwa tá a bá lè ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run! Bíbá àwọn mìíràn táwọn náà nífẹ̀ẹ́ láti wà lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run kẹ́gbẹ́ yóò ràn wá lọwọ́ láti máa gbé lọ́nà tí yóò mú ká lè jàǹfààní ìṣàkoso Ìjọba ológo rẹ̀ náà. Bákan náà, yóò tún jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti rí àwọn nǹkan tí yóò jẹ́ àbájáde àwọn ìlànà rere tí Ìjọba náà yóò mú lò.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò “ni ilẹ̀ ayé” wọn yóò sì “rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—SÁÀMÙ 37:11