Omi Ohun Iyebíye Tó Ń Mú Ká Wà Láàyè
Omi Ohun Iyebíye Tó Ń Mú Ká Wà Láàyè
JÉSÙ sọ fún obìnrin ará Samáríà kan tó ń fa omi nínú kànga nípa ìsun omi kan tó ń tú yàà láti fúnni ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòhánù 4:14) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé omi ìṣàpẹẹrẹ ni Jésù ń tọ́ka sí, síbẹ̀ omi tí à ń mu ṣe pàtàkì gan-an fún ìwàláàyè wa, torí pé lẹ́yìn afẹ́fẹ́, òun ló tún kàn. Èèyàn lè wà láàyè fún bí ọ̀sẹ̀ mélòó kan láìjẹun, àmọ́ èèyàn ò lè gbé ju ọjọ́ márùn-ún lọ bí kò bá mu omi!
Omi ló pọ̀ jù nínú bí ara wa ṣe tẹ̀wọ̀n sí. Bí àpẹẹrẹ, ìdá márùndínlọ́gọ́rin sí márùnlélọ́gọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún ọpọlọ wa ló jẹ́ omi nígbà tí omi ko ìdá àádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn iṣu ẹran ara wa. Láfikún sí àwọn àǹfààní mìíràn tí omi ń ṣe fún ara, ó tún ń jẹ́ kí oúnjẹ dà nínú wa kí ara sì ṣàmúlò wọn, nípa gbígbé àwọn èròjà aṣaralóore lọ sínú àwọn ohun tíntìntín inú ẹ̀jẹ̀. Ó máa ń mú àwọn nǹkan tó jẹ́ májèlé àtàwọn nǹkan tí ara ò nílò mọ́ kúrò nínú ara, ó ń jẹ́ kí àwọn oríkèé ara àti ìfun wà nípò tó yẹ, bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í jẹ́ kí ara gbóná kọjá ààlà. Àmọ́, ǹjẹ́ o mọ̀ pé mímu omi dáadáa tún wà lára ohun tó ń dín sísanra kù?
Mu Omi Kó O Lè Dín Sísanra Kù
Lákọ̀ọ́kọ́ ná, omi kò ní èròjà kálórì afáralókun, kò ní ọ̀rá, bẹ́ẹ̀ ni èròjà sodium inú rẹ̀ kò tó nǹkan. Èkejì, kì í jẹ́ kébi tètè pani. Ẹ̀kẹta, omi máa ń jẹ́ kí ara lè lo ọ̀rá tó ti fi pa mọ́. Lọ́nà wo? Bí omi tó wà nínú kíndìnrín kò bá tó, kò ní lè ṣiṣẹ́ dáadáa. Ẹ̀dọ̀ á ràn án lọ́wọ́, àmọ́ èyí kò ní jẹ́ kí ẹ̀dọ̀ lè lo ọ̀rá tó wà nínú ara bó ṣe yẹ. Ni ọ̀rá á bá jókòó sínú ara níbẹ̀, onítọ̀hún á sì máa sanra sí i. Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí Dókítà Donald Robertson, tó wà ní Southwest Bariatric Nutrition Center
ní ìlú Scottsdale ní Ìpínlẹ̀ Arizona, ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ti sọ, “mímu omi tó pọ̀ jẹ́ ọ̀nà pàtàkì láti dín sísanra kù. Bí àwọn èèyàn tó fẹ́ dín sísanra kù kì í bá mu omi tó pọ̀ tó, ara ò ní lè lo ọ̀rá bó ṣe yẹ.”Lóòótọ́, kí omi máa dúró sára ló sábà máa ń fa sísanra jọ̀kọ̀tọ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn tí omi máa ń dúró sára wọn máa ń rò pé dídín omi tí àwọ́n ń mu kù ni ojútùú ìṣòro náà. Àmọ́ èyí kì í ṣòótọ́ rárá. Bí ara kò bá rí omi tó tó, gbogbo omi tó bá ń wọnú ara ló máa fẹ́ gbà dúró nípa fífi wọ́n pa mọ́ sí àwọn ibì kan nínú ara, irú bí ẹsẹ̀ àti ọwọ́. Nítorí náà, àwọn onímọ̀ nípa àwọn ohun aṣaralóore dábàá pé ká máa fún ara ní ohun tó nílò—ìyẹn ni omi tó tó. Sì tún rántí o, bí iyọ̀ tó ò ń jẹ bá ṣe pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni omi tí ara rẹ á máa gbà dúró láti fi là á ṣe máa pọ̀ tó.
Máa Fún Ara Rẹ Lómi
Lójúmọ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, ní ìpíndọ́gba, nǹkan bíi lítà omi méjì ló ń jáde lára wa látinú awọ ara, ẹ̀dọ̀fóró, ìfun àti kíndìnrín. Nípa mímí síta nìkan, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì lítà omi tí à ń pàdánù lójoojúmọ́. Bí a ò bá dá omi yìí padà, ńṣe ni omi ara wa máa gbẹ. Díẹ̀ lára àwọn àmì tó ń fi hàn pé omi ara wa ti gbẹ ni ẹ̀fọ́rí, àárẹ̀ ara, kí ara máa kanni gógó, kí ìtọ̀ ẹni máa pọ́n, àìlè gba ooru mọ́ra, àti kí ẹnu àti ojú gbẹ táútáú.
Nítorí náà, báwo ló ṣe yẹ kí omi tá à ń mu ṣe pọ̀ tó? Dókítà Howard Flaks, tó jẹ́ ògbóǹkangí nínú béèyàn ṣe lè dènà sísanra jọ̀kọ̀tọ̀ sọ pé: “Ó kéré tán, ẹni tí ara rẹ̀ le gbọ́dọ̀ máa mu omi tọ́ńbìlà mẹ́jọ sí mẹ́wàá lójúmọ́. Wàá nílò jù bẹ́ẹ̀ lọ bó o bá ń ṣe eré ìmárale gan-an tàbí bó bá jẹ́ ilẹ̀ olóoru lò ń gbé. Àwọn èèyàn tó sì sanra gan-an ní láti máa mu jù bẹ́ẹ̀ lọ.” Àmọ́, àwọn èèyàn kan ti ń sọ pé mímu omi kìkì nígbà tí òùngbẹ bá ń gbẹni ti tó. Síbẹ̀, nígbà tí òùngbẹ bá fi bẹ̀rẹ̀ sí í gbẹ ọ́ gan-an, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ara rẹ ti gbẹ nìyẹn.
Ṣé èèyàn lè mu àwọn nǹkan dídùn dípò omi? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan olómi ọsàn náà máa ń fún ara lómi, síbẹ̀ wọ́n ṣì ní èròjà kálórì afáralókun nínú. Bákan náà, àwọn nǹkan olómi tí ṣúgà àti mílíìkì pọ̀ nínú wọn máa ń mú kí ara túbọ̀ nílò omi, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé omi náà ni wọ́n máa nílò láti mú kí wọ́n dà nínú. Bẹ́ẹ̀ sì ni ọtí àtàwọn nǹkan mímu bíi kọfí àti tíì máa ń jẹ́ kéèyàn tọ̀ gan-an, tí èyí á sì mú kó pọn dandan láti túbọ̀ mu omi láti dí èyí téèyàn ń tọ̀ jáde. Ó dájú pé kò sí nǹkan tó lè rọ́pò ohun iyebíye tó ń mú ká wà láàyè yìí, ìyẹn omi. Nítorí náà, kí ló dé tó ò lọ mu ife omi kan báyìí?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Àwọn Àbá Tó Lè Jẹ́ Kó O Túbọ̀ Máa Mu Omi Sí I
● Máa gbé omi lọ́wọ́.
● Máa mu omi ife kan nígbà tó o bá ń jẹun.
● Mu omi kó o tó lọ ṣe eré ìmárale, nígbà tó o bá ń ṣe é lọ́wọ́, àti nígbà tó o bá ṣe tán.
● Máa mu omi dípò kọfí lẹnu iṣẹ́.
● Kí omi má bàa lọ́ lẹ́nu, fi omi ọsàn wẹ́wẹ́ díẹ̀ sí i tàbí kó o fi asẹ́ sẹ́ ẹ.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 23]
Fọ́tò: www.comstock.com